Báwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe wà nínú ìbẹ̀rù àti ìpayà ní South Africa, ìṣí kejì wọn padà délé láàrin gbèkéde ìparí oṣù tí wọn fún wọn

Awọn ọmọ Naijiria lọkunrin ati lobinrin pẹlu ọmọde n sọkalẹ latinu ọkọ baalu to gbe wọn wa sile

Oríṣun àwòrán, Pius Utomi Ekpei/AFP Via Getty

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Isi keji awọn ọmọ Naijiria to n bọ lati orilẹede South Africa ti gunlẹ si orilẹede yii.

Papakọ ofurufu Muritala Mohammed ni wọn de si lẹyin ti wọn ti ni idaduro fun ọpọ ọjọ, ki baalu to wa gbe wọn.

Jinni-jinni si ti bo awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa bayii bi iwọde ẹ le awọn alejo lọ, to gbalẹ kan nibẹ.

O le ni ọtalerugba awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko wa sile ni ọsẹ meji sẹyin, wọn si wa lara ogunlọgọ ọmọ Naijiria to wa ni South Africa to fẹ wa sile.

Ni ana ọjọru, ọgọta awọn ọmọ Naijiria ni baalu ko pada sile lati South Africa gẹgẹ bii ara igbesẹ ijọba apapọ lati seto iranwọ fun wọn laarin iwde ẹ pada silu yin to n waye nilẹ South Africa.

Awọn eeyan naa lo jẹ ọkunrin ati obinrin, ọmọde ati agba, ti ijọba si ni igbesẹ kiko awọn ọmọ Naijiria wa sile ko ni dawọ duro titi ti awọn yoo fi ko gbogbo ọmọ Naijiria to ba fẹ lati pada sile lati South Africa.

Awọn ọkunrin to pọ ti wọn mu igi dani

Oríṣun àwòrán, Darren Stewart/Gallo Images via Getty Images

Ìbẹ̀rù àti ìpayà báwọn ọmọ Nàìjíríà báwọn ọmọ South Africa ṣe ní kí wọn padà sílùú wọn títí ìparí oṣù

Oniṣowo ọmọ Naijiria kan, Wilson Oghodero ti ni inu ibẹru ati ifoya ni awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa fi n gbe bayii pẹlu gbedeke ọgbọnjọ oṣu Kẹfa ti wọn fun awọn ajoji ti ko ni iwe lati fi kuro ni orilẹ ede naa.

Wilson sọ fun BBC pe awọn ẹgbẹ naa sọ pe awọn maa lọ lati ojule sojule lati ṣe ayẹwo iwe igbeluu awọn ajoji ti gbedeke ti wọn fun wọn ba ti wa sopin.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni eyi ti mu alekun ba inu fu aya fu ba awọn ọmọ Naijiria to w ani South Africa to ti forukọ silẹ lati pada wale.

Ẹgbẹ to n ri ọrọ awọn ajoji ni South Africa n pe fun afikun ofin ki eeyan to le wọ orilẹ ede naa, ti wọn si kede ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa gẹge bi gbedeke fun awọn ajoji ti ko b ani iwe igbeluu lati fi orilẹ ede wọn silẹ.

Wilson ṣalaye pe lati igba ti kede gbedeke naa, ti ijọba Naijiria naa si ti fifẹ han lati lati ko awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa pada sile ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti fi ile ti wọn n gbe silẹ, ti wọn si ti ko si itosi ibi ti ileeṣẹ Naijiria wa ni Pretoria, ti wọn n reti ọkọ ofurufu to maa gbe wọn pada sile.

Ṣaaju ninu oṣu yii ni ijọba Naijiria ko awọn eeyan 268 pada sile lati Johannesburg. Ijọba ni eeyan to to ẹgbẹrun kan ni wọn forukọ silẹ lati kuro ni South Africa.

"Awọn eeyan lati ọna jinjin, wọn ti ta awọn dukia wọn, wọn o le pada si ibi ti wọn n gbe tẹle, ileeṣẹ Naijiria ni wọn n sun.

"Emi bayii, baagi mi nikan lo ku, mo ti ta gbogbo dukia mi, ipe wọn nikan ni mo n duro de.

"Mi o mọ ohun ti ma a ṣe ti oṣu ba ti pari bayii, mo ti sọ fun onile mi pe mi o gbele mọ."

Wilson sọ pe awọn alaṣẹ Naijiria ni awọn n duro de lati mọ igba ti awọn maa kuro ni orilẹ ede naa amọ ti ijọba ko fun awọn lọjọ kan pato ti awọn maa kuro.

Ṣaaju ni ijọba Naijiria sọ pe ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹfa ni awọn maa ko awọn eeyan mii kuro ni South Africa amọ ti ko ri bẹẹ. Ijọba ko sọ ohun to fa idiwọ tabi igba ti wọn maa pada ko awọn eeyan to ku to ṣi w ani South Africa.

BBC kan si awọn alaṣẹ Naijiria lati beere ohun to ṣẹlẹ amọ ti wọn ni awọn maa fi atẹjade sita.

Awọn ọmọ Naijiria mii to wa ni South Africa naa sọ pe awọn kan w ani ileeṣẹ Naijiria ti awọn n duro de ijọba Naijiria lati wa awọn pada sile ṣaaju gbedeke ọgbọn ọjọ ti wọn fun awọn.

Lara awọn fidio to wa lori ayelujara ṣafihan bi awọn eeyan naa ṣe n kọminu lori bi wọn ko ṣe ri ounjẹ jẹ ni ibi ti wọn wa.

Naijiria bii Ghana, Malawi, Zimbabwe ati Mozambique ti n ko awọn eeyan kuro ni South Africa lẹyin ti ifẹhonuhan tako awọn ajoji waye ni South Africa.

Awọn to n ṣe iwọde tako awọn ajoji ti ko ni iwe igbeluu n fẹsun kan pe awọn eeyan naa ko jẹ ki awọn ohun amayedẹrun ti ijọba n pese to iṣamulo, ti wọn si n beere fun ofin to tun lagbara tako awọn ajoji.

Ijọba South Africa ni awọn n ṣiṣẹ lati gbogunti awọn to n fi orilẹ ede naa ṣe ibugbe lọna aitọ, ti wọn si n rọ awọn araalu lati ma gbogun tako awọn ajoji.

Wilson sọ pe awọn ẹgbẹ to n ṣe iwọde tako awọn ajoji kii ṣe oṣiṣẹ ijọba, awọn araalu to n le awọn ajoji ni wọn.

"Ọpọ eeyan lo n ṣe aarẹ"

Ọmọ Naijiria mii, Christian Onyenweaku to ba ileeṣẹ iroyin News Central sọrọ sọ pe ọpọ awọn to n su sile iṣẹ ijọba Naijiria lo ti n ṣe aarẹ bayii.

O ni iṣoro nla ni awọn n koju nibẹ ti ijọba ko sit ii mu ileri wọn ṣẹ lati ko gbogbo awọn kuro.

O ni awọn ile ijọsin atawọn ajọ kan to n ṣe iranwọ fun awọn lo jẹ ki awọn ṣi maa ri ounjẹ jẹ.

"A ti ri ounjẹ ti di iṣoro, ti kii ba ṣe awọn pasitọ Naijiria atawọn ajọ kan lo jẹ ka maa ri ounjẹ jẹ bayii."

A o ni gba ki ẹnikẹni lo ohun ija lasiko iwọde - Ileeṣẹ ọlọpaa

Ileeṣe ọlọpaa South Africa ti ni awọn ko ni fi aaye gba ẹnikẹni lati gbe ohun ija dani tabi lo ohun ija kankan lasiko iwọde tawọn araalu fẹ ṣe ni ọgbọn ọjọ, osu Kẹfa.

Ọlọpaa ni awọn oṣiṣẹ awọn ti wa ni sẹpẹ ni gbogbo ẹkun mẹjọ ti iwọde naa ti maa waye ati pe awọn ẹṣọ aabo ti maa w ani gbogbo agbegbe ṣaaju iwọde naa.

Kọmiṣanna fun ẹkun Eastern Cape, Ọgagun Vuyisile Ncata sọ pe awọn ko ni aaye gba wahala tabi laasigbo nibi iwọde naa.

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn gba pe ẹtọ awọn eeyan ni labẹ ofin lati ṣe iwọde, o ni awọn ko ni fi aaye gba titẹ ofin loju mọlẹ, iwa odaran tabi maa tabuku ẹtọ awọn eeyan lasiko iwọde.

Bakan naa lo ke si awọn to n ṣe agbatẹru iwọde ọhun lati ba awọn eeyan wọn sọrọ ki wọn ma da wahala silẹ lasiko iwọde ọhun.