Ooni Ile Ife kéde orúkọ ọmọbìrin rẹ̀ tuntun

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja ll
Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja Keji, ti kede orukọ ọmọbinrin tuntun ti Eledua ṣẹṣẹ fi ta a lọrẹ.
Eyii lo waye nibi eto isọmọlorukọ ọmọ naa to waye ni gbagede Emese, to wa ninu aafin Ooni, niluu Ile Ife, nipinlẹ Osun.
Ọjọ kẹjọ lẹyin ti Olori Oluwatosin Ogunwusi bi ọmọbinrin tuntun naa ni ayẹyẹ isọmọlorukọ ọhun waye.
Ọpọ awọn ori ade, oloye laafin Ooni atawọn to di aṣa Yoruba mu lo peju sibi ayẹyẹ isọmọlorukọ na, bẹẹ ni wọn ṣadura ti wọn si tun ṣe gbogbo ohun to yẹ fun ọmọ tuntun jojolo ọhun.
Ki ni orukọ ọmọ naa?
Orukọ ọmọ tuntun naa ni Adelewa, Adeyele, Adeshikemi, Ayoade, Ọmọ Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja keji.
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe Lowa Adimulat ti Ile Ife to kede awọn orukọ naa ṣadura pe ki Eledumare fun ọmọ ọhun ni ọgbọn, ilera pipe, okun, ore ọfẹ ati ẹmi gigun.
Lowa Adimula tun gbadura pe ki ọmọọba naa di irun ko si di igba ti yoo ṣoju ile Oodua nibi giga lagbaye.
Lara awọn nnkan ti wọn fi ṣeto isọmọlorukọ naa gẹgẹ bii aṣa ilẹ Yoruba ni ireke, aadun, oyin, ẹja gbigbẹ, owo, kalamu, obi, orogbo, ataare, igbin, ọti schnapps, omi, epo pupa ati ẹyele.
Gẹgẹ bii wọn ṣe sọ, awọn ohun elo naa ni wọn fi ṣadura fun ọmọ ọba fun adun, itẹsiwaju, ọgbọn, ọjọ gigun, alaafia, oye, aabo latọrunwa ati igbeaye to niyi.
Lowa Adimula fi ẹmi imoore han si Olodumare fun ibi ọmọ naa, o si juwe rẹ gẹgẹ bii igba ọtun fun aafin Ooni.
O tun dupẹ lọwọ Ooni ati Olori Oluwatosin, o gbadura fun ọmọ ọba tuntun pe asiko to waye yoo san idile Ooni, yoo si mu alaafia, irẹpọ ati ilọsiwaju ba ijọba Ooni.
Nigba to n sọrọ, Ooni dupẹ lọwọ Olodumare fun ẹbun nla to fi jinki idile Oduduwa.
O fi akoko naa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to peju sibẹ ati gbogbo oriade to duro tii.




























