Obasanjo ṣàlàyé irúfẹ́ àìsàn tó ti ń bá a fínra fún bí ogójì ọdún àti ọ̀nà tó fi ń tọ́jú ara rẹ̀

Oloye Olusegun Obasanjo wọ aṣọ buba dudu ati fila

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo, ti ṣalaye irufẹ aisan kan to ti n ba a finra fun bi ogoji ọdun.

Oloye Obasanjo ti wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa ṣe ere idaraya, ki wọn si maa ṣọ ounjẹ jẹ lai gbagbe lilọ sile iwosan loorekoore fun ayẹwo ara wọn.

Obasanjo sọ pe awọn nnkan yii ti ṣeranwọ fun oun papaa julọ pẹlu bi arun itọ ṣuga ti ṣe boun finra fun bi ogoji ọdun bayii.

Aarẹ ana orilẹede Naijiria to ti pe ẹni ọdun mọkandinlaadọrun un bayii fidi ọrọ naa mulẹ ninu ifọrọwanilẹwo kan to ṣe niluu Abeokuta lopin ọsẹ to kọja.

Baba Iyabo ni bi eeyan ba ṣe n dagba si ni ere idaraya ṣe maa n wulo si fun agọ ara eeyan.

Obasanjo ni ṣiṣe awọn nnkan yii le jẹ ki ẹmi eeyan gun laye.

''Ohun kan to yẹ ki ẹ mọ ni pe ere idaraya dara fun ọmọde ati agbalagba.

O ṣe pataki gan an papaa julọ ti eeyan ba ti di agbalagba.

Lagbara Ọlọrun, mo ti pe ọdun mọkandinlaadọrun un, ara mi si le koko bi ọta bo tilẹ jẹ pe mo ti ni arun itọ ṣuga fun bi ogoji ọdun bayii.

Ọpọ eeyan lo maa n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ ilera ara wọn,'' Obasanjo ṣalaye.

Baba Iyabo ṣalaye ilana to n tẹle lori ọrọ ilera rẹ, eyi to pe orukọ rẹ ni ''DREAM + C''

Obasanjo ni lẹta D duro fun iru ounjẹ ti eeyan n jẹ, nigba ti R duro fun isinmi.

Lẹta E lede oyinbo ni Obasanjo sọ pe o duro fun ṣiṣe ere idaraya nigba gbogbo.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri sọ pe lẹta M wa fun lilọ sile iwosan fun ayẹwo ara.

Lẹta S ni Obasanjo ṣalaye pe o wa fun ibaṣepọ pẹlu awọn eeyan.

Lakotan, Obasanjo sọ pe lẹta C duro fun itẹlọrun tori itẹlọrun ni baba iwa.

Obasanjọ sọ pe inu oun maa n dun lati kopa ninu ere idaraya ni gbogbo igba.

Idi si niyii ti o fi kopa ninu ere idaraya ''Golf'' gbigba eyi to waye niluu Abeokuta lopin ọsẹ to kọja.