Ogun Ukraine ló sọ mí di ẹni tó ń bá èèyàn gbé oyún

- Author, Sofia Bettiza
- Role, World Service Global Health Reporter
- Reporting from, Kyiv
- Author, BBC News Ukrainian
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Karina ti wa ninu oyun oṣu mẹfa, amọ kii ṣe oun lo ni ọmọ to wa ninu rẹ.
Ẹni ọdun mejilogun naa lati guusu Ukraine jẹ ẹni to maa n ba awọn eeyan gbe oyun, oyun tọkọtaya kan ti wọn jẹ ọmọ orilẹede China lo si wa ninu rẹ lasiko yii.
Lasiko to wa lọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ado oloro wo ile rẹ niluu Bakhmut lẹyin ti ogun Russia ati Ukarine bẹrẹ.
Lẹyin eyii ni oun ati ọrẹkunrin rẹ lọ siluu Kyiv lati wa iṣẹ amọ ko rọrun lati ri iṣẹ ọhun.
O bi ọmọ kan, lasiko ti ọmọ naa wa lọmọ ọdun kan abọ ti ko si ri owo tọju rẹ lo pinnu lati maa ba awọn eeyan gbe oyun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ogun to waye ni Ukarine lo sọ ọ di ẹni to n ṣe irufẹ iṣẹ bẹẹ.
Iye owo ti yoo gba fun gbigbe oyun naa ni 12,500 ($17,000) bo tilẹ jẹ pe ko ni gba pupọ ninu owo ọhun titi di igba to ba bimọ tan.
O ti sọ pe oun yoo gbe ọpọlọpọ oyun bayii titi ti ara oun ko ni gbe oyun kankan mọ, oun yoo si fi owo naa ra ile.
Amọ ṣa, o ṣeeṣe ki erongba rẹ yii ma le wa si imuṣẹ o.

Oríṣun àwòrán, BioTexCom
Ṣaaju ogun naa, Ukraine ni awọn eeyan ti maa n ba ẹlomiran gbe oyun julọ lagbaye lẹyin ilẹ Amẹrika.
Awọn onimọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe ogun Russia ti ṣakoba fun iṣẹ ọhun, awọn eeyan tun ti bẹrẹ si n ba awọn eeyan gbe oyun bayii nibẹ.
Wayi o, ile igbimọ aṣofin Ukraine ti n daba lori ofin kan ti yoo maa ṣokoso biba eeyan gbe oyun ati lati fofin de awọn ọmọ ilẹ okeere ti awọn eeyan n ba gbe oyun.
A gbọ pe awọn ọmọ ilẹ okere naa ni ida 95% awọn eeyan ti wọn n ba gbe oyun.
Ọpọ awọn aṣofin ilẹ naa ni wọn sọ pe abadofin naa tẹ awọn lọrun.
Wọn fẹsun kan awọn to n ṣiṣẹ naa pe wọn ti sọ ọrọ ọmọ bibi di karakata.
Bẹẹ lawọn mii ninu awọn aṣofin naa sọ pe ko tọ ki awọn ọmọ ilẹ Ukraine maa ba awọn atọhunrinwa gbe oyun nigba ti awọn onilu funra wọn nilo ọpọlọpọ ọmọ latari awọn to padanu ẹmi wọn sinu ogun Russia.
Ajafẹtọọ awọn obinrin, Maria Dmytrieva, sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn gbẹsẹle iṣẹ ọhun patapata.
Gẹgẹ bii oye rẹ, awọn ile iwosan ti wọn ti n ṣe iṣẹ ọhun n mọọmọ lo awọn obirin ti ko ri jajẹ lati ba awọn ọlọrọ gbe oyun, eyii to ja si pe wọn n lo awọn to n gbe oyun naa ni ilokulo.
Awọn ọmọ to ti padanu awọn obi wọn

Awọn ọmọ kan tun wa ti awọn obi wọn maa n kọ silẹ lẹyin ti wọn ba bi wọn tan.
Ni Ukraine, ẹni ti wọn ba ti ba gbe ọmọ lo gbọdọ tọju ọmọ naa, kosi gbọdọ kọ ọmọ ọhun silẹ labẹ bo ti wu ko ri.
Wei, to jẹ ọmọ ọdun marun un bayii ni ijamba ọpọlọ lẹyin ti wọn bi ki oṣu rẹ ko pe lọdun 2021. Ileeṣẹ BioTexCom lo wa ẹni to gbe oyun rẹ.
Ile awọn ọmọ abarapa kan to wa ni Kyiv lo n gbe bayii.
Lẹyin ti awọn obi rẹ lati Asia gbọ pe abarapa ni yoo ya, wọn kọ lati gba a lọwọ ẹni to ba wọn gbe oyun rẹ.
Obirin to gbe oyun rẹ naa sọ pe oun ko fẹ ọmọ ọhun, ofin ko si le kan an nipa fun lati gba ọmọ naa labẹ ofin Ukraine.
Ọkan lara awọn to n fẹ ki ijọba Ukraine ṣe atunṣe si ofin oyun gbigbe, Valeria Soruchan sọ pe ọpọ awọn obi ti wọn ba gbe oyun lo maa n kọ awọn ọmọ naa silẹ ti ko ba tẹ wọn lọrun.
Bo tilẹ jẹ pe ko lodi si biba eeyan gbe oyun, o koro oju si ofin rẹ ti ko mulẹ daadaa, o si n fẹ ki ijọba fofin de awọn atọhunrinwa ti wọn n ba gbe ọmọ nibẹ.
Ọga agba ileeṣẹ BioTexCom, Tochilovsky sọ pe ti awọn obi ba kọ ọmọ wọn silẹ ojuṣe awọn ni lati tọju awọn ọmọ naa.
Ṣugbọn ọpọ ọmọ bii Wei ni kii ri alagbatọ ti yoo gba wọn tọ.





















