Àìsàn 'sickle cell' bá mi fínra tó bẹ́ẹ̀, mo bẹ Ọlọrun kó gba ẹ̀mí mi - Adekunle Gold

Adekunle Gold pẹlu ẹgba ọrun

Oríṣun àwòrán, Mata/AdekunleGold

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja olorin takasufe, Adekunle Gold, ti sọrọ lori idojukọ rẹ pẹlu aisan sickle cell.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu gbajumọ ori ayelujra, Yanke Yee, Adekunle Gold sọ pe aisan naa ba oun finra to bẹẹ lẹyin ti oun le lẹni ogun ọdun ti oun fi gbadura fun iku.

Adekunle Gold, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Adekunle Kosoko sọ pe "Nigba ti mo pe lẹni ogun ọdun ni nnkan nira julọ fun mi julọ. Mo gba dura ki Ọlọrun gba ẹmi mi."

Gbajumọ olorin naa sọ pe asiko naa le to bẹẹ ti iya oun ti ko fẹran ki eeyan maa sọrọ odi ko ri nnkankan sọ mọ lasiko ti oun gbadura fun iku naa.

Nigba to n sọrọ lori aisan sickle cell, Adekunle bu ẹni atẹ lu bi awọn eeyan ṣe maa n kaanu awọn to n ba aisan naa finra ti wọn si maa n ro pe wọn ti gba ọjọ iku wọn.

O ni awọn eeyan maa n wo oun bi ẹni ti ọjọ iku rẹ ko pe mọ ni kete ti wọn ba ti gbọ pe oun ni aisan naa.

Adekunle sọ pe "Wọn maa n wo mi bii pe mi o ni pẹ ku mọ.

Lẹyin naa lo ni ko tọ ki awọn eeyan maa fi oju iku wo ẹnikẹni to ba n ba aisan sicke cell gbe.

Ọrọ yii lo n jẹyọ lasiko ti olorin takasufe naa n gbe eeyan kan lọ sile ẹjọ lori ọrọ kobakungbe to ni wọn n sọ nipa oun lori ayelujara.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹnu lọlọ yii ni Adekunle gbe ọkunrin kan lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe ọkunrin naa sọ iroyin ẹlẹjẹ nipa mọlẹbi oun pe arun gbẹmi ọmọbinrin oun.

A gbọ pe ile ẹjọ ti sọ ẹni to gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa olorin ọhun si ẹwọn ọdun meji, eyii ti ọpọ eeyan lori ayelujara ni o tọ lati dena gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri lori ayelujara nipa ẹlomiran.

Wayi o, bo tilẹ jẹ pe Adekunle n ba aisan sickle cell gbe, ṣaṣa ni ẹni to le ko iyan rẹ kere lagbo awọn olorin ni Naijiria.