Ọ̀pọ̀ èèyàn farapa lẹ́yìn táwọn jàndùkú ṣíná ìbọn bolẹ̀ níbí ipolongo ìbò APC l'Osun

Oríṣun àwòrán, Bola Oyebamiji/Facebook
Iroyin to tẹ wa lọwọ ti sọ pe ọpọ eeyan farapa lẹyin tawọn janduku agbebọn ṣina ibọn bolẹ nibi ti ẹgbẹ oṣelu APC ti n ṣe ipolongo ibo niluu Ilesa lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Osun to n bọ.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC n ṣe ipolongo ibo nibi ti wọn ti n rin lati agbegbe Oke-Omiru lọ si Isokun niluu Ilesa lọwọ ni nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye.
Ọmọ ẹgbẹ APC kan to n jẹ Segun sọ fawọn akọroyin wi pe ''laaarọ kutu ti a n pada si olu ileeṣẹ ẹgbẹ wa lawọn janduku kan ti ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Olawale Akerele, dari wọn ṣekọlu si wa.
Awọn janduku naa yinbọn soke lati dẹru ba wa, amọ, ọpọ ninu wa si duro sibẹ.
Bayii ni awa naa pakuru mọ wọn ti wọn si yinbọn si aarin wa nibi ti a ti n ṣe ipolongo ibo.
Ọpọ eeyan lo fara ṣeṣe ninu wa lẹyin ti wọn yinbọn si aarin wa.
Lẹyin naa ni a tun ko ara jọ pada lati fi ẹhonu han, ṣugbọn Họnarebu Akerele tun ko awọn janduku wa lati da wa ru.
Wọn ṣe ikọlu si wa, ọpọ ọmọ ẹgbẹ APC lo si farapa.''
Ọgbẹni Segun fikun ọrọ rẹ wi pe awọn ti gbe awọn ọmọ ẹgbẹ to farapa lọ si ile iwosan.
O ni ibọn ba awakọ akẹru kan ati awọn eeyan ti wọn n kọja lọ.
Segun sọ pe ''ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ wa torukọ rẹ n jẹ Tobi n gbatọju lọwọ bayii nileewosan Wesley Guild Teaching Hospital.''
Bakan naa ni adari eto iroyin fun igbimọ olupolongo ibo fun APC, Oluremi Omowaiye, fidi rẹ mulẹ pe aṣofin ipinlẹ Osun Akerele to jẹ ọmọ ẹgbẹ Accord lo wa nidii iṣẹlẹ naa.
Ikọlu yii lo jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ APC niluu Ilesa ṣe iwọde lati ke pe awọn agbofinro wi pe ki wọn fọwọ ofin mu Họnarebu Akerele.
''Awọn APC lo kọkọ yinbọn soke, kawọn Amotekun to wa pẹlu mi naa to yinbọn soke''
Ẹwẹ, Họnarebu Akerele ti ṣalaye pe oun n wa ọkọ lọ lagbegbe Isokun nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ APC to n ṣe ipolongo ti ba oun nibẹ.
''Bayii ni wọn bẹrẹ sii yinbọn soke, awọn ẹṣọ Amotekun naa si wa pẹlu mi ninu ọkọ.
Awọn ẹṣọ Amotekun naa yinbọn soke lati dẹru ba wọn, lẹyin naa ni a kuro nibẹ.
Nigba to ya ni ọga ọlọpaa DPO pe mi wi pe awọn eeyan kan fẹsun kan mi pe mo yinbọn sawọn ọmọ ẹgbẹ APC kan.
Bayii ni mo sare lọ si agọ ọlọpaa lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.





























