Èèyàn 32 ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú tó já lulẹ̀ n'Igbokoda-Festus Keyamo, Mínísítà ìrìnàjò òfurufù

Festus Keyamo (SAN) lapa osi, ọkọ ofurufu to ni ijamba lapa ọtun.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Minisita fun irinajo ofurufu lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo, (SAN), ti fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mejilelọgbọn (32) lo wa ninu ọkọ ofurufu awọn ologun to jabọ n'Igbokoda, ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.

Ninu atẹjade ti Keyamo fi sita lọjọ Aje oni lo ti ṣalaye, pe ọkọ ofurufu naa poora lasiko irinajo lati Benin lọ si Eko, ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja iṣẹju mẹtala aarọ.

Nọmba baaluu ọhun bi Keyamo ṣe wi ni "NGR 931."

"Gbogbo igbiyanju lati gbe ọkọ naa dide lo ja si pabo, iwadii pada fi ye wa pe ọkọ naa ti ja lulẹ lagbegbe ibudo awọn ọmọ ogun oju omi to wa ni Igbokoda"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ ni Keyamo sọ eyi.

O ni, "A ti ri ajaku rẹ, bẹẹ ni wiwa awọn eeyan ati idoola ti n lọ lọwọ.

"Iwadii fi han pe ero mẹẹẹdọgbọn (25) atawọn oṣiṣẹ ọkọ meje lo wa ninu ọkọ ofurufu yii."

Minisita naa lo ṣalaye bẹẹ.

O ni oun ti ba ọga agba ologun oju ofurufu, Sunday Kelvin Aneke sọrọ lori iṣẹlẹ yii, o si ti ṣeleri ifọwọsowọpọ rẹ lori ijamba naa.

Bo ba ṣe n lọ, Minisita irinajo ofurufu ni oun yoo maa fi to araalu leti.

Bàálù ẹlikópítà já lulẹ̀ nílùú Igbokoda l'Ondo, ohun tí a mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún rèé

Pangolo baalu agberapa to ja lulẹ

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Ondo ti sọ pe baalu agberapa ẹlikopita kan ti ja lulẹ lonii niluu Igbokoda ni ijọba ibilẹ Ilaje nipinlẹ Ondo.

A ko le sọ bayii iye eeyan to ku tabi farapa ninu ijamba ọkọ ofurufu ọhun lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Baalu to ja naa ti da ibẹru-bojo silẹ lagbegbe ọhun, pẹlu bi awọn ẹṣo eleto aabo to n doola ẹmi lasiko pajawiri ṣe duro wamu wamu nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ẹnikan to n gbe ni agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Olorunlola Oluwafemi, sọ fun BBC pe ojo n rọ lọwọ ni awọn gbọ ariwo nla kan bi ara.

Oluwafẹmi sọ pe nigba tawọn ri i wi pe kii ṣe ara lawọn jade ti awọn si ri i wi pe baalu lo ja lulẹ.

O ni eefin n ru soke nibi ti baalu naa ti ja lulẹ.

Oluwafemi sọ pe ibi ti baalu naa ja si ko jinna si igbo kan to wa lẹgbẹẹ ibudo awọn ọmogun ori omi Naijiria ti wọn n pe ni Forward Operating Base niluu Igbokoda.

Ẹwẹ, awọn ọmogun oju omi atawọn ẹṣọ eleto aabo mii ti lọ sibi iṣẹlẹ ọhun lati doola awọn to wa niluu baalu naa.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.