Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Temi Nkem tó jáwé olúborí nínú ètò Big Brother Naija Season 11 pẹ̀lú ẹ̀bùn kàbìtì

Oríṣun àwòrán, teminators_official_fanpage/Instagram
Temi Nkem lo jawe olubori ninu eto Big Brother Naijiria Season 11 ti o si gba ẹbun ₦160m.
Temitope Chigbue ti apetan orukọ rẹ n jẹ Temi, ẹni ọdun mọkanlelogun, fakọyọ ninu eto naa ti wọn pe ni ''Show Ya Sef.''
Lati igba ti eto naa ti gberasọ ni Temi ti bẹrẹ ti fakọyọ ti o si jẹwọ ara rẹ titi ti eto naa fi pari.
Wọnyi ni nnkan mẹwaa ti o yẹ ki o mọ nipa Temi Nkem to jawe olubori ninu eto Big Brother Naija Season 11
Temitope Chigbue ni apetan orukọ ọdọbinrin to jawe olubori ninu eto Big Brother Naija ti ọdun yii.
Amọ, Temi Nkem ni o n jẹ lati igba ti eto naa ti bẹrẹ ti o si fi pari lọjọ Aiku ọjọ kẹrin oṣu Kẹwaa ọdun yii.
Temi jẹ akẹkọọ nigba ti o darapọ mọ eto Big Brother Naija Season 11.
Temitope ṣapejuwe ara rẹ bi ẹni to ni igboya ti ọrọ si da muṣe muṣe lẹnu oun.
Temi ni ko si ẹni to maa ri oun ti ko ni wo oun ni ẹẹmeji, o ni oun gan an ni ẹni to yẹ ko wa lori eto Big Brother Naija.
Temi gbadun ki o maa kopa ninu ere idaraya golf, ati ko maa jẹun pẹlu ki o maa rin.
O tun ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to maa n feti silẹ lati gbọ nnkan ti ẹnikẹni ba n sọ.
Temi ni oun lẹbun ki oun maa fawọn eeyan ni imọran ti oun ba ti gbọ nnkan ti wọn fẹ sọ tan.
O ni fifun awọn eeyan ni imọran jẹ ọkan lara ẹbun ti Eledua fun oun.
Temitope tun sọ nipa ara rẹ wi pe ọpọ eeyan lo maa n ri oun bi ẹni to ni igberaga nigba mii, tori oun kii gba jọgẹ fun ẹnikẹni.
Nkem wa lara awọn oludije mẹsan an to wọ ipele aṣekagba ni Big Brother Naija pẹlu Aikou, Barry, Bluethopia, Flora, Oyin, Ricky, Sheba ati Tram ninu awọn mẹrinlelogun ti wọn jọ bẹrẹ eto ọhun.
Temi ni o tẹle Imisi bayii ninu awọn to ti jawe olubori ninu eto Big Brother Naija.
Nkem ni oun yoo maa ṣe fidio lori ayelujara, bakan naa lo ni oun yoo tun maa gbe iroyin jade lori itakun ayelujara ni bayii ti eto Big Brother Naija ti pari.




























