Ṣé lóòótọ́ ni Teniola àti Tiwa Savage yóò wàákò nínú ẹ̀ṣẹ́ kíkàn láti gba ₦1.5bn? Ohun tí a mọ̀ rèé

Tiwa Savage wọ aṣọ olomi buluu, Teniola wọ agbekọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olorin Afro n ni, Tiwalola Savage tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Tiwa Savage ti sọ pe oun gba lati ba akẹgbẹ rẹ, Teniola Atinuke Apata wọya ija ninu ẹṣẹ kikan.

Tiwa Savage sọ pe ko si ẹru kankan to fẹẹ bao un lati ba Teni to jẹ olorin takasufee nni ja ija awọn gbajumọ.

Teni lo pe Tiwa Savage sita wi pe oun ṣetan lati ba a wọya ija awọn gbajumọ lori papa, ati pe to ba to bẹẹ, ko dide lati dahun.

Ọjọ Ẹti, ọjọ keji, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni Teniola daba wi pe yoo wu oun lati ja ija ti owo rẹ yoo to biliọnu kan aabọ naira.

Teni sọ pe ẹni to wu oun lati ba ja ija naa ni Tiwa Savage.

Ṣugbọn loju ẹsẹ ni Tiwa ti da a lohun pẹlu ọrọ mẹta pere to fi sọ pe "Mu ọjọ kan."

Lasiko to n kede ija naa sita, Teni sọrọ nipa bi awọn gbajumọ lẹka amuludun ṣe n ri owo nla, ti wọn si n ra ọkọ bọginni.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe oun ko nii wo oju ọmọ Tiwa, iyẹn Jamal lẹẹmeji rara, ni kete ti wọn ba fun feere, lati da ẹṣẹ bo mama rẹ.

"Jẹ ka jọ ja, Tiwa Savage ati emi. Mọmi, maa lu ẹ titi ti o maa fi mu ori wọnu igbo. Emi ti mo n binu, nko tiẹ ni wo oju Jamal rara.

"Maa ge oju mi. Biliọnu kọọkan. Eel oni wọn n ta awọn ọkọ bọginni yii? Bi wọn ba fun wa ni Biliọnu kan aabọ naira, ṣe maa le ra Bugatti? Ka tiẹ kọkọ bẹrẹ nibẹ yẹn naa.

"Mama, ẹ jẹ ka ja. Tiwa, maa lu ẹ, maa si kọrin 'My Darling' fun ẹ," Teni sọ bẹẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Erémọdé lásán ni

Bi ere, bi awada ni Teni fi fọnran to gbe sita naa ṣe, ṣugbọn idahun Tiwa toun naa dahun pẹlu awada lo jẹ ki ere ọhun di otitọ laaarin awọn mejeeji.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn ololufẹ wọn ni wọn ti n ronu bi ọjọ naa yoo ṣe ri, ṣugbọn awọn miran n sọ pe wọn ko ni erongba naa lọkan, bi ko ṣe pe ọna lati tun mu inu awọn ololufẹ wọn dun sii ni.

Wọn ni ko si ija kankan to fẹẹ waye, nitori pe ko si awọn ti yoo ṣagbatẹru ija ọhun, ko si iwe adehun ti wọn tọwọ bọ, bẹẹ si ni ko tii si ọjọ kankan ti wọn mu, bi ko ṣe pe ere ni awọn mejeeji jọ n ṣe.

Àwọn irúfẹ́ ìjà tó ti wáyé

Lati bi oṣu meloo sẹyin ni oniruuru ija awọn amuludun ti waye nilẹ Naijiria, to si jẹ pe eyi ti wọn n sọ lọwọ bayii ni ti ija to waye laaarin Phyna ati Nkechi Blessing lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.

Phyna to gbegba oroke nibi idije Big Brother Naija lọdun diẹ sẹyin lu Nkechi Blesing lalubami, lati fi gba bẹliiti.

Ṣaaju asiko yii ni gbajumọ ori ayelujara, Charles Okocha ati Portable ti ja ija yii

Bẹẹ naa ni Speed Darlington ati Carter Efe ti gbena woju ara wọn.

Carter Efe naa tun lu Portable.

Ṣugbọn ṣaaju awọn ija yii ni Portable ti lu Okocha ati Darlington.