MTN ṣàlàyé ìdí tí Data àwọn ọmọ Naijiria fi ń tètè tán

Ọwọ to mu foonu dani
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fun gbogbo ẹni to ba n lo foonu nla ta a mọ si Smartphone, dandan ni Data. Idi ni pe bi ko ba ti si data lori foonu, bii ẹni gbe apola igi lasan dani ni.

Amọ lọpọ igba, data ọhun ki I pẹẹ tan, bii pe kinni kan wa to n fa a mu loju opo ayelujara ni.

Aroye ti ọpọ ọmọ Naijiria maa n ṣe nipa data to n tete tan yin, ati bi wọn ṣe n fi oju adani-nigbese wo awọn ileeṣẹ to n ta data, lo mu MTN, ọkan lara ileeṣẹ eleto ibaraẹnisọrọ, ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ si data awọn eeyan gan-an.

Ki ni MTN wi?

Nibi ipade kan ti wọn gbe kalẹ l'Abuja lọjọ Aje ọsẹ yii, eyi ti wọn pe akori rẹ ni " Data on trial" ni Adari ẹka to n ri si nẹtiwọọki ni Naijiria nileeṣẹ MTN, Mike Ndukwe, ti sọ pe ohun ti awọn to n lo data n lo o fun lo n jẹ ko tete tan.

Lara awọn nnkan ti MTN sọ pe o n jẹ ki data tete tan ni :

  • Sisọ fidio to wuwo kalẹ (downloading).
  • Ki eeyan maa ka fidio ti yoo jẹ data pupọ silẹ bi eto kan ṣe n lọ lọwọ.
  • Ki awọn nnkan maa sọkalẹ sori foonu funra rẹ latari ohun ti ẹni to ni foonu naa ti tẹ (Automatic downloads).
  • Awọn oju opo kan to wa labẹnu lai foju han.
  • Isọdọtun awọn apa ibi ti eeyan n ko ohun to wa lori foonu si (Cloud backups) ati ọpọ nnkan ti eeyan n ṣe lori ayelujara to n pọ si i.

Ndukwe tẹsiwaju pe:

"A ki ji data yin. Amọ bo ṣe n ri lara, paapaa lasiko yii ti ko si kekere owo.

"Amọ otitọ to wa nibẹ ni pe data ki i tan lai ṣe pe awọn nnkan kan ti waye, boya latọwọ ẹni to n lo foonu tabi foonu funra rẹ"

Bẹẹ ni Ndukwe ṣalaye.

Ndukwe tun sọ pe bi awọn nnkankan ṣe ṣe n iṣẹ lorii foonu, jẹ idi miran ti data awọn eeyan fi le maa sare tan.

Adari nẹtiwọọki ni Naijiria naa sọ pe awọn oju opo bii TikTok, YouTube, Instagram ati WhatsApp ko lo iye data kan naa, o ni wọn n jẹ data jura wọn lọ.

O fi kun un pe bi fidio ba ṣe wuwo si, bo ṣe n pada funra rẹ ti eeyan n tun un wo (auto replay) ati bi eeyan ṣe n gba fidio si maa n jẹ data.

Gẹgẹ bo ṣe wi, fidio iṣẹju mẹẹẹdogun lori TikTok le jẹ to mẹgabytes meji si ogun (2-20).

Atẹjiṣẹ lori WhatsApp ni tiẹ ki I jẹ data pupọ bi Ndukwe ṣe ṣalaye.

Amọ eyi ti a mọ si status updates, awọn, atẹjiṣẹ ọlọpọ eeyan ati bẹẹ bẹẹ lọ le mu data gbẹ ju bi eeyan ṣe ro lọ.

"Bi o ba fi WhatsApp rẹ si ilana ti nnkan yoo maa sọkalẹ sibẹ lai tẹ ẹ rara, (autodownload), ori data rẹ lo n lọ lẹsẹkẹsẹ.

"O le tun un ṣe lapa ibi ti a mọ si settings."

Bi o ba fẹ ki data rẹ maa pẹ ko too tan, eyi lawọn ohun ti wọn gba ọ nimọran lati maa ṣe

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

*Mu gbogbo apa ibi ti nnkan ti n sọkalẹ (automatic download) funra rẹ lorii foonu rẹ kuro.

*Yi I pada si pe ko ma ṣe bẹẹ mọ.

*Din awọn fidio to wuwo to o n gba sori foonu rẹ ku.

*Jẹ ki abala ti wọn kọ data-saving si loju foonu rẹ wa ni titan silẹ.

*Ma a yẹ bi o ṣe n lo data rẹ si wo loju opo MyMTN.

Bakan naa ni ọga to n ri ri imọ ẹrọ ni MTN Nigeria, David Ogunsola, ṣalaye pe ipele oju opo ti eeyan n lo naa tun maa n sọ bi data yoo ṣe tete tan si.

"Iru oju opo ti o wa, boya 3G tabi 4G, maa n sọ bi wa a ṣe lo data si, amọ bi yoo ṣe ya ọ si lati ṣe ohun ti o fẹ ṣe lori ayelujara naa yoo yatọ sira wọn.

Nnkan miran ti MTN tun sọ ni pe iṣoro ina ọba ni Naijria n jẹ kawọn maa fi owo awọn pese ina ati nnkan irinsẹ si gbogbo ẹka ileeṣẹ MTN.

Eyi n mu wọn nawo pupọ bi wọn ṣe wi, lojuna ati ṣaa ri I pe awọn ọmọ Naijiria ni nẹtiwọọki to daa lo gẹgẹ bii eyi ti wọn n lo lawọn ilẹ okeere bii Europe ati America, amọ owo nla ni eyi n jẹ.

Ori data naa ni yoo si fabọ si.