Ìjọba Nàíjíríà bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n fáwọn tó fẹ́ẹ́ gbẹ̀mí ara wọn

Aarẹ Bola Tinubu
Àkọlé àwòrán, The bill has been proposed by Nigeria's president
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ fun ile igbimọ aṣofin lati ṣagbeyẹwo ofin to pese idajọ ẹwọn fun ẹnikẹni to ba gbiyanju lati doola ẹmi rẹ nilẹ Naijiria.

Tinubu sọ pe ki ile igbimọ aṣofin pese iranlọwọ eto ilera pipefun ẹni to ba pinnu lati gbẹmi ara rẹ, dipo ko jẹ ijiya nipa idajọ ẹwọn

Aarẹ fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti ori ba ko yọ lasiko ti wọn n gbiyanju lati gbẹmi ara wọn nilo itọju nipa eto ilera, ati ọna idanilẹkọọ ti yoo jẹ ki wọn tun ero ọkan wọn pa.

Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka eto ilera fi n pe fun ayipada yii. Ati pe abadofin lati yọ ẹsun ọdaran kuro lori igbiyanju lati gbẹmi ara ẹni ti gba kika keji kọja nile igbimọ aṣofin agba.

Labẹ ofin Naijiria, iwa ọdaran ni ẹnikẹni to ba gbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ, ati pe iru ẹni bẹẹ yoo lo to ọdun kan lọgba ẹwọn, tabi ko san owo itanran - iru ẹni bẹẹ si le ṣẹwọn, ko si tun san owo itanran papọ.

Kii ṣe pe ile igbimọ aṣofin agba yoo yọ idajọ naa kuro, wọn yoo rọpo idajọ ẹwọn ati faini sisan pada si eto itọju ilera, idanilẹkọọ ati iranlọwọ to ba yẹ.

Sẹnetọ Asuquo Ekpenyong, to gbe aba naa dide sọ pe bi atunṣe ba wa ninu agbeyẹwo ofin naa, yoo ṣe iranlọwọ to yẹ fun awọn to ba n gbero lati gbẹmi ara wọn.

Ekpenyong jẹ ko di mimọ pe idajọ nipa ofin naa tun le ko ẹru sọkan awọn mọlẹbi, nipasẹ ohun ti wọn n la kọja.

"Ẹnikẹni to ba gbero lati gbẹmi ara rẹ ni lati rii pe oun ṣaṣeyọri, lati le ma jẹ ko foju winna ofin, iyẹn to ba kuna lati gbẹmi ara rẹ," o sọ bẹẹ.

O sọ siwaju pe aba naa kii ṣe lati fun awọn to n gbero lati gbẹmi ara wọn ni iwuri tabi koriya, bi ko ṣe lati daabo bo awọn to ba la ipenija naa kọja ni aabo ati iranlọwọ to ba yẹ.

Ilé ìgbìmọ aṣòfin tẹ́wọ́ gbàá

Kete ti Aarẹ Tinubu ti fi aba naa ranṣẹ ni Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ti tẹwọ gbaa, ẹni to ti figba kan tẹlẹ sọ pe ki wọn maa ran iru awọn eeyan bẹẹ lọ sẹwọn.

"A n sọ pe iwa ọdaran ni gbigba ẹmi ara ẹni bayii. Fun idi eyi, bi ẹ ba gbero rẹ, o dara lati ṣe aṣeyọri. Bi ẹ ko ba ṣe aṣeyọri rẹ, a maa ran yin lọ sẹwọn," Akpabio sọ bẹẹ nigba naa.

Ṣugbọn ṣa, lẹyin to tẹwọ gba aba naa lọwọ Aarẹ, o sọ pe igbesẹ naa ko si fawọn to ba n la ipenija tabi iṣoro to nii ṣe pẹlu ailera ilera ọpọlọ.

"Nko mẹnuba awọn to n la iporuru ọkan kọja, nitori pe ara wọn ko da pe fun ilera to nii ṣe pẹlu ọpọlọ, nitori pe wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe lasiko naa" Akpabio fidi eyi mulẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe fifi iya jẹ awọn to n la ipenija to nii ṣe pẹlu iporuru ọkan kọja, jẹ eyi to gba agbeyẹwo gidi.

Kí ló bí ìgbésẹ̀ yìí?

Igbesẹ yii lo waye, lẹyin ti awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka eto ilera rọ Aarẹ lati ṣagbeyẹwo ofin yii.

Nibi apero kan to waye ninu oṣu Karun-un, ọdun 2024, Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣegun lẹka eto ilera ọpọlọ, APN, Ọjọgbọn Taiwo Obindo rọ awọn aṣofin lati yọ iwa ọdaran kuro ninu ẹsun gbigbẹmi ara ẹni.

"Ki lo de, awa gẹgẹ bi orileede, fiya jẹ awọn to n ṣaisan, ti wọn si nilo iranlọwọ."

Nigba to n sọrọ nipa awọn iriri rẹ gẹgẹ bi dokita lẹka eto ilera ọpọlọ, Obindo sọ pe ọpọ awọn eeyan lo n ku nipasẹ ailera ọpọlọ.

Akpabio ti wa fi aba naa lati ọdọ aarẹ ranṣẹ si igbimọ ti yoo ṣagbeyẹwo rẹ.

Naijiria wa lara ọpọ orileede ilẹ Afrika nibi ti igbiyanju lati gba ẹmi ara ẹni ti jẹ iwa ọdaran.

Ọdun 2023 ni orileede Ghana wọgile ofin naa, nigba ti ile ile-ẹjọ giga Kenya ninu oṣu Kinni, ọdun 2025 sọ pe igbesẹ naa ko ba ofin mu.