Fídíò tó ṣàfihàn ibùba ajínigbé ní ìpínlẹ̀ Ogun - Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, AFP
Fidio kan ti jade sori ayelujara, to n ṣafihan ibi kan ti wọn pe ni ibuba ajinigbe nipinlẹ Ogun.
Ninu fidio ọhun ni ọkunrin kan ti ni awon eeyan nilo lati ṣọra nipinlẹ Ogun, o ni nitori ipinlẹ Ogun ni ibuba awon ajinigbe ti fidio naa ṣafihan wa.
Ẹni to n sọrọ ninu fidio ọhun kọkọ n sọ ede Igbo, nigba to si ya lo yi i si ede Gẹẹsi.
Fidio naa tun ṣafihan apa kan inu igbo naa, nibi ti ẹnikan to wọṣo bii ti ologun to si gbe ibọn dani ti n gbiyanju lati yinbọn soke.
Apa kan fidio naa tun ṣafihan awon kan ti wọn ni ajinigbe lo gbe won pamọ sinu igbo ọhun.
Eredi fidio naa bi won ṣe ṣalaye ninu rẹ, ni pe ki awon araalu ṣọra pupọ, nitori awon ajinigbe yii ni ibuba kaakiri awon igbo ipinlẹ Naijiria.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ lori fidio naa
Lọjọ Aiku, ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin 2026, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi atẹjade kan sita lati ṣalaye lori fidio naa.
DSP Oluseyi Babaseyi, Alukoro ọlọpaa Ogun to fi atẹjade naa sita lorukọ Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Bode Ojajuni, ṣalaye pe:
"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n fi asiko yii sọ fun yin pe ko sohun to jọ ohun to n ṣẹlẹ ninu fidio to gba ori ayelujara kan .
"Fidio naa jẹ irọ, aṣinilọna, bẹẹ ni ko wa lati ipinlẹ Ogun tabi apa ibi kankan ni Naijiria."
Atẹjade ọlọpaa naa sọ pe iwadii fi han pe orilẹede Kenya ni won ti ya fidio naa, lasiko ti won n mu awon kan to n ji ẹran agbo gbe.
Wọn fi kun un pe ikọ kan, General Service Unit (GSU) lo ya fidio naa pẹlu ẹrọ drone wọn.
Alukoro ọlọpaa sọ pe iwadii tun fi han, pe ọdun 2022 ni fidio naa kọkọ jade sori ayelujara.
O ni latigba naa ni won si ti n gbe e jade nigba to ba wu won pẹlu irọ, lati ko awon eeyan ilu laya soke nipa ipo aabo nipinlẹ Ogun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bode Ojajuni, naa koro oju si ohun to wa ninu fidio naa, o si rọ awọn eeyan lapapọ lati ma ṣe gba a gbọ rara.
Ojajuni fi da awon eeyan ipinlẹ Ogun loju, pe ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ko sinmi nipa ki alaafia ati aabo wa fun ẹmi ati dukia awon olugbe ibẹ.
Kọmandi ọlọpaa Ogun wa rọ awọn eeyan pata lati ma ṣe pin fidio naa kiri lori ayelujara mọ, tabi eyikeyi iru rẹ ti wọn ko le fidi rẹ mulẹ, ki won ma baa lọwọ si dida omi alaafia ilu ru.
Bi wọn ba ri ohun ifura to le koba aabo, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun rọ wọn lati tete fi to agbofinro leti.
Amọ pinpin ohun ti ko ṣẹlẹ kiri tabi gbigbe iroyin atako kiri ni ko si aaye fun bi wọn ṣe sọ.


























