Èèyàn 300 ṣe ìgbéyàwó ní Gaza láàárín ogun tó ń wáyé níbẹ̀

Awọn kan lara awọn to n ṣe igbeyawo naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ araalu lo korajọ sibi ayẹyẹ ti ọọdunrun eeyan ti ṣe igbeyawo lẹẹkan ṣoṣo ni Gaza.

A gbọ pe igbeyawo ọlọgọrọ eeyan yii ni igba akọkọ ti ọọdunrun eeyan yoo ṣe igbeyawo lẹẹkan ṣoṣo nibẹ ninu itan.

Ayẹyẹ ọhun to waye ni Deir al-Balah ni iroyin sọ pe wọn ti mu awọn tọkọtaya ọhun laarin eeyan ti iye wọn to ẹgbẹrun meji.

Ajọ ti kii ṣe ti ijọba kan, Khalifa bin Zayed Al Nahyan lo ṣagbatẹru ayẹyẹ naa gẹgẹ bii ọkan lara eto rẹ to pe ni United Arab Emirate's Operation Gallant Knight 3.

Eto United Arab Emirate's Operation Gallant Knight 3 ọhun ni wọn gbe kalẹ lati ṣatilẹyin fun awọn ọmọ Palestine to n gbe ni Gaza.

Ọkan lara awọn iyawo aṣẹṣẹgbe naa, Thekra al-Masri, sọ fun BBC pe ayẹyẹ igbeyawo ọhun mu ireti ọtun ba awọn eeyan ti ogun n ba finra ni Gaza.

Bi ogun ṣe bẹrẹ ni Gaza

Ti ẹ ko ba gbagbe, ogun Gaza bẹrẹ lẹyin ti Hamas kọlu Israel ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 to si ṣekupa eeyan bii 1,200, to tun ji eeyan 251 mii gbe lọ.

Ikọlu naa lo mu ki Israel bẹrẹ ogun si Hamas ni Gaza, ninu eyii ti eeyan ti iye wọn to 72,560 ti gbẹmi mi bayii gẹgẹ bii atẹjade ileeṣẹ eto ilera Gaza ti Hamas n dari.

Lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin ti a wa yii, ko din ni ọmọ Palestine mẹjọ, ninu eyii ti ọmọde mẹta wa, ti wọn ku ni Gaza Strip lẹyin ti Israel ju ado oloro sibẹ.

Nigba ti Israel n sọrọ lori ikọlu naa, o ni agbesunmọmi kan to n sunmọ ibi ti awọn ologun oun wa loun doju ado oloro naa kọ, eyii to lewu fun awọn ologun oun.

Amọ ṣa, agbẹnusọ Hamas kan tib u ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun, to si juwe ibi ti ado oloro naa balẹ si bii eyii ti ko ṣe e foju ri.

O tun fẹsun kan Israel pe ko jẹ ki igbiyanju awọn lati fẹnuko lori adehun jogunomi ko ṣeeṣe.