Ọ̀nà wo ni iléeṣẹ́ ológun gbà pa àgùnbánirọ̀ kan ní Abuja, tí ẹbí rẹ̀ fi fọnmú?

Oríṣun àwòrán, Ebi Samad
- Author, Adebola Ajayi
- Role, Journalist
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Awọn ẹbi agunbanirọ, Abdulsamad Jamiu ti jiyan iroyin ti ileeṣẹ Ologun Naijiria fi lede lori iku ọmọkunrin naa.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Jamiu nigba to padanu ẹmi rẹ sọwọ ibọn awọn ologun.
Awọn ẹbi ọmọkunrin naa sọ pe ile awọn, to wa ni Shagari Quarter, agbegbe Dei-dei ilu Abuja, ni awọn ọmọ ogun pa ọmọkunrin naa si, lodi si nnkan ti ileeṣẹ Ologun sọ.
Ṣaaju ni agbẹnusọ ileeṣẹ Ologun Abuja, Olawuyi Odunola gbe iroyin jade lọjọ Aiku, ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 pe awọn gba iroyin pe awọn kan n jale ni agbegbe Shagari Quarters, Dei-Dei, Abuja ti awọn si sare lọ sibẹ.
Odunola ninu atẹjade naa sọ pe, bi awọn ọmọ ogun ṣe debẹ ni awọn adigunjale naa bẹrẹ si ni ṣina ibọn bolẹ fun awọn.
O ni awọn naa si n da pada fun wọn ko to di pe awọn adigunjale naa salọ.
"Awọn ologun lo yinbọn mọ ori ọmọ wa to n sun ni yara"
Ileeṣẹ Ologun ni asiko ti ibọn n ro lakọlakọ naa ni Samad ti fara gbọta ibọn to si jade laye, bi o tilẹ jẹ pe awọn gbiyanju lati ri daju pe ẹnikẹni ko ṣeṣe lasiko ikọlu naa.
Amọ awọn ẹbi Abdulsamad sọ pe bi ọrọ ṣe ri kọ ni ileeṣẹ Ologun ṣe gbe kale ati pe niṣe ni wọn pa ọmọ awọn mọ ile, ti wọn si ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye fun BBC.
Awọn ẹbi rẹ sọ pe nibi ti Abdulsamad sun si ninu yara rẹ ni awọn Ologun ti yinbọn fun-un lori, to si gbabẹ ku lẹsẹkẹsẹ.
Awọn aworan ati fidio ti wọn fi han BBC ṣafihan bi gbogbo inu yara naa ṣe daru, ti oju ọta ibọn si wa lara ogiri ati ilẹkun inu yara naa.
Asiko ti Samad n sun lọwọ ni awọn ologun yinbọn pa - Fareedah Jamiu
Ẹgbọn Samad, Fareedah Jamiu sọ fun BBC pe irọ patapata gbaa ni pe Samad ku lasiko tawọn Ologun atawọn adigunjale n ṣina ibọn bolẹ funra wọn.
O ni nnkan bii aago meji oru ni oun bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn ninu yara oun ti oun sun si, ti oun sis are jade lati lọ ti ilẹkun ile awọn.
O sọ pe bi oun ṣe fẹ lọ tilẹkun naa ni oun pade awọn ọmọ ogun ni ẹnu ọna ile awọn ti oun si beere Samad lọwọ wọn.
Fareedah ni nigba ti oun ko gbọ ijẹ Samad ni oun sare lọ si yara rẹ to sun si amọ oku rẹ ni oun ba nigba ti oun debẹ.
"Oke ni yara mi wa nigba ti yara Samad wa ni isalẹ, nigba ti mo gbọ iro ibọn, mo dide lati lọ sare ti ilẹkun.
"Mo lọ si yara rẹ lati lọ duro ti Samad, nibẹ ni mo ti ri awọn ọmọ ogun, mo sare kunlẹ fun wọn pe ki wọn ma pa mi.
"Wọn beere pe ta ni mi mo si sọ fun wọn pe olugbe ile naa ni mi, mo sọ fun wọn pe ki wọn ma yinbọn t imo ba ti sọkalẹ amọ bi mo ṣe n sọkalẹ ni mo n gbọ oorun ibọn t imo si beere pe aburo mi da."
Fareedah fi kun pe iro ibọn ti oun gbọ tumọ si pe aburo oun ni wọn pa sinu yara ti oun si bẹrẹ si ni pariwo amọ tawọn Ologun naa jagbe mọ oun pe ki oun dakẹ ki oun ma jii awọn ara adugbo silẹ.
"Ibọn tawọn Ologun yin, lo gba ara ilẹkun Samad wọ inu yara rẹ, to si lọ ba a lori nibi to sun si"
Fareedah tẹsiwaju pe lẹyin naa ni awọn ologun naa pe awọn ọlọpaa atawọn fijilante ti wọn gbe oku Samad le wọn lọwọ ti wọn si ni kawọn fijilante nu gbogbo ẹjẹ to wa nilẹ.
Lati kin ọrọ Fareedah lẹyin, awọn ẹbi Jamiu fi atẹjade sita lọjọ Aje pe awọn n beere fun idajọ ododo lori iku ọmọ wọn.
Wọn sọ ninu atẹjade naa pe irọ ni ileeṣẹ pa pẹlu bi wọn ṣe sọ pe Samad jade laye nigba ti awọn ọmọ ogun atawọn adigunjale n koju ibọn sira wọn.
Wọn fẹsun kan pe ibọn tawọn Ologun yin, lo gba ara ilẹkun Samad wọ inu yara rẹ, to si lọ ba a lori nibi to sun si.
Awọn ẹbi naa n beere fun iwadii to loorin lori iku ọmọ wọn lai si idasi ileeṣẹ Ologun ati pe awọn fẹ ki ileeṣẹ Ologun ṣafihan awọn ọmọ ogun to yinbọn pa Samad, ki wọn si ni ki wọn lọ rọkun nile titi ti iwadii fi maa pari lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni wọn ni ki ileeṣẹ Ologun tun tọrọ aforiji lọwọ awọn ẹbi ni gbangba, ki wọn ko atẹjade ti wọn kọkọ fi lede jẹ, ki wọn si sọ ohun to ṣẹlẹ gangan.
Ileeṣẹ paṣẹ ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa
Atẹjade ti olu ileeṣẹ fi lede lọjọ Aiku sọ pe awọn ti ni ki iwadii to gbopọn bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa ki wọn si ṣawari ohun to fa iku ọmọkunrin naa.
Wọn ni awọn maa fi abọ iwadii naa lede, ti awọn si maa ṣe aridaju rẹ pe awọn ko fi ohunkohun pamọ lori iwadii naa.
Ileeṣẹ Ologun ni awọn ti gbe oku Samad fun awọn alaṣẹ to yẹ ti wọn si tig be si ile iwosan gbogbogbo ti Kubwa.
Wọn ni awọn ni ifarajin si dida aabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu paapaa ni Abuja, ti awọn si ṣe atungbeyẹwo ilana ti wọn n gba ṣiṣẹ lati ri daju pe awọn da aabo to peye bo awọn araalu pẹlu bi wọn ṣe n koju awọn ọdaran.
Wọn wa rọ awọn araalu lati farabalẹ, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo bi wọn ṣe n ṣiṣẹ lati mu alaafia jọba laaarin ilu.























