Kí ló tún ń fa awuyewuye lórí ìsìnkú Toluwanisings? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Toluwanisings/Instagram
Lati bi ọjọ meloo sẹyin ni awuyewuye tun ti dide lori ọrọ ibi ti wọn yoo sinku gbajugbaja onkọrin igbagbọ nni, Ọlayemi Bolaji Bayonile tọpọ mọ si Toluwanisings si.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ iku onkọrin naa ṣi n jẹ kayeefi fawọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye.
Ṣugbọn ni bayii, bi wọn ṣe sọ pe iyawo oloogbe naa ṣe n sọ pe oun ko fẹ ki wọn sinku ọkọ oun sinu ile to kọ, bẹẹ ni baba rẹ n sọ pe inu ile naa loun fẹ ki wọn sinku ọmọ oun si.
Fọnran ifọrọwerọ ti baba to bi Toluwanisings, Muniru Adekunle Olayemi ṣe laipẹ yii, to si n ja rainrain lori ayelujara, lo ti ṣalaye irin ajo ọmọ rẹ.
Baba naa sọ pe nnkan to le dun mọ oun ninu ju ni ki sinku Bayonle Olayemi sinu ile rẹ to kọ.
"Inu oṣu Keje, ọdun 1992 ni a bi ọmọ mi, Sodiq Bayonle Olayemi ni mo sọ orukọ rẹ lọjọ ti a sọ ọ lorukọ," baba naa fidi rẹ mulẹ.
"Akọrin ẹmi ni ninu ṣọọsi to n lọ, ibẹ lo si ti bẹrẹ iṣẹ orin. Ibẹ lo ti ri akọrin ẹgbẹ rẹ, to fẹ ni iyawo. Asiko igba to bẹrẹ sii kọrin ẹmi lo fi yi orukọ rẹ pada si Toluwani.
"Igba to di Kristiẹẹni, inu mi dun, nitori pe Kristiẹẹni ati Musulumi lo wa ninu idile wa, kii ṣe pe o n ṣe abọriṣa, Ọlọrun kan naa la n sin," o fidi rẹ mulẹ.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe oloogbe naa lo beere lati mọ awọn aburo rẹ ti obinrin miran bi foun, to si latigba naa ni wọn ti n ṣe wọlewọde.
"Ipo keji ni Toluwanisings wa ninu awọn ọmọ mi. Ọjọ kan lo pe mi pe ṣe oun ko ni aburo ni, mo sọ pe o ni. Loju ẹsẹ lo ti gba ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ti wọn fi bẹrẹ sii sọrọ,"
Bàbá náà sọ ẹ̀dun ọkàn rẹ̀
Ọgbẹni Muniru Olayemi sọ pe nnkan kan ṣoṣo to le dun mọ oun ninu julọ, ni wọn sinku ọmọ oun sinu ile to jiṣẹ-jiya kọ, ko too jade laye.
O ni yoo si maa wa ni iranti awọn mọlẹbi, ni gbogbo igba ti wọn ba n de inu ile naa.
Siwaju sii lo ni gbara toun gbọ nipa iku ọmọ oun, loun ti ṣabẹwo si iyawo rẹ, to si loun sọ nnkan toun fẹ fun un, ṣugbọn to ni iyawo naa sọ pe ko le ṣee ṣe.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe, bi wọn ko ba le sinku ọmọ oun sinu ile to kọ, ki wọn gbe e lọ si ibi ti wọn sinku mama rẹ si lọdun mẹrinlelọgbọn sẹyin.
"Mi o fẹ ki wọn gbe oku ẹ lọ si itẹ tabi ṣọọṣi kan, ki wọn sin in sinu ile ẹ, lo le dun mọ emi ninu ju," Baba Toluwanisings sọ ẹdun ọkan rẹ.
O tẹsiwaju pe, "Nigba to kọ ile, inu ile rẹ ni ki wọn sin in si. Wọn si n fa a, o ni oun ko le maa fi ojoojumọ maa wo saare ọkọ oun. Ṣe ti wọn ba wa gbe e lọ si ṣọọṣi, ṣe ibẹ lo ti fẹ maa lọ gbadura fun un ni?
"To ba ri bẹẹ, ti ẹ ba mọ pe ẹ ko le sin sinu ile to kọ, ẹ gbe wa si Ikirun, ki wọn wa sin sẹgbẹ iya ẹ," Baba naa ṣalaye.


























