"Àwọn tó yọ mí nípò ni yóò ṣì ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀" - Ọba ìlú Eselu sọ̀rọ̀

Oba Akintunde ti ijọba ipinlẹ Ogun jawe gbeleẹ fun ree pẹlu ilẹkẹ oye lọrun ati ọwọ, o mu foonu dani
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Eselu tiluu Eselu nijọba ibilẹ Ariwa Yewa nipinlẹ Ogun, Oba Akintunde Akinyemi ti sọ pe otitọ ni ijọba ipinlẹ Ogun jawe gbeleẹ foun lori ẹsun ṣiṣe oṣelu ẹlẹya kan ti wọn fi kan oun.

Ọba Akinyemi lo fidi iroyin naa mulẹ lasiko to n ba BBC sọrọ l'Ọjọru, to si jẹ ko di mimọ pe ijọba lo le ṣalaye ohun ti wọn ri nipa ẹsun naa.

Nigba to n sọrọ, Kabiyesi sọ pe lotitọ loun ti gba iwe ti ijọba fi ranṣẹ soun, gẹgẹ bi jijawe gbeleẹ foun, ṣugbọn to loun ko ni ohunkohun lati sọ lori rẹ.

Kabiyesi naa sọ pe ijọba to fi iwe gbeleẹ ranṣẹ soun naa ni wọn le sọ pato, nipa ohun ti wọn ri, to fi di pe wọn gbe igbesẹ naa.

"Otitọ ni, mo ti gba lẹta naa, awọn si ni wọn le ṣalaye nipa rẹ. Ijọba lo le ṣalaye pe nnkan bayii ni mo ṣe, mi o fẹ sọ nnkankan lasiko yii," Ọba Akinyemi sọ bẹẹ fun BBC.

"Awọn ni ki wọn sọ iru oṣelu ti mo n ṣe, ko ma jẹ pe emi ni mo n ṣaaju ẹlẹẹdẹpẹẹdẹ, nitori pe ẹni to ba fẹsun kan ni, naa ni yoo fidi rẹ mulẹ.

"Emi o le sọ nnkankan nipa rẹ, ki emi to le sọ ohunkohun, ijọba ni yoo sọ pe nnkan ti mo ṣe ree, boya ki ẹ lọ beere lọwọ wọn, ẹ ṣeun."

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni ijọba ipinlẹ kede pe ohun ti jawe gbele ẹ fun Ọba Akinyunde Akinyemi, Eselu tiluu Iselu nijọba ibilẹ Ariwa Yewa lori ẹsun ṣiṣe oṣelu.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, Ganiyu Hamzat buwọ lu, lo ti sọ pe ijọba koro oju si ki awọn ori ade maa kopa ninu ọrọ oṣelu, paapaa nipinlẹ Ogun.

Lẹta naa ti ijọba tun fi ranṣẹ si akọwe ijọba ibilẹ Ariwa Yewa ati ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ni wọn ti sọ pe awọn tẹle abala kejilelaadọta (ipin kinni) ninu iwe ofin oye jijẹ ti ọdun 2021, titi digba ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun to tako ọba naa.

Ijọba sọ pe ṣiṣe oṣelu ẹlẹya kan tako iwe ofin to de awọn ọba alaye, pẹlu ikilọ pe iwa naa le da epo si aala ipo ori ade.

Bakan naa ni ijọba tun jẹ ko di mimọ pe bi awọn ọba ba n ṣe oṣelu ẹlẹya kan, o le da omi alaafia ilu ti wọn n ṣakoso ru, nipa oniruuru ibi ti onikaluku to si nidi oṣelu.

Ijọba sọ pe lati le gba alaafia ati eto laaye nipinlẹ naa, paapaa niluu Iselu lohun ṣe gbe igbesẹ naa, lati le ṣe agbeyẹwo ohun to jẹ otitọ.

Siwaju sii ni ijọba tun paṣẹ pe ki Ọba Eselu fi aafin rẹ loju ẹsẹ, ko si dẹkun lati maa fi ara rẹ han gẹgẹ bi ọba, ati pe ko gbọdọ lo ohunkohun to le fi han gẹgẹ bi ọba nita gbangba, nipa lilo awọn nnkan bi ilẹkẹ, irukẹrẹ ati ade.

Bakan naa ni ijọba paṣẹ pe igbakugba ti ohun b anilo ọba naa fun ibeere tabi ohunkohun, o gbọdọ fi ara rẹ han, lati le wẹ ara mọ ni gbogbo asiko ti yoo fi gbe ile rẹ.