Ọ̀fọ̀ míì tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, àgbà òṣèré jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Solomon Akiyesi /Facebook
Ẹgbẹ oṣere tiata ilẹ Naijiria ti a mọ si Actors Guild Of Nigeria (AGN) ti kede iku ọkan lara awon agba oṣere nilẹ yii, Solomon Akiyesi.
Ọjọ Aje ni Aarẹ ẹgbẹ naa, Abubakar Yakubu kede pe Solomon Akiyesi to maa n dari ere yatọ si pe o jẹ oṣere, ti jade laye.
Aarẹ AGN fi kun un pe Oloogbe naa sun lalẹ ọjọ Aiku ni, ko si ji saye mọ lọjọ keji.
Ẹni ọdun mejidinlọgọta (58) ni Oloogbe Solomon Akiyesi ko too jade laye.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Gẹgẹ bi ohun ti ọmọ Oloogbe Akiyesi sọ, o ni ṣaaju ọjọ Aje naa ni Akiyesi sọ pe àyà n dun oun, awon si gbe e lọ sile iwosan.
Lẹyin ayẹwo lo ni awon dokita sọ pe ọgbẹ inu lo n da a laamu.
Ọmọ naa tẹsiwaju pe wọn fun un ni oogun ti yoo lo, awon si pada sile.
Oorun alẹ ọjọ Aiku mọjumọ ọjọ Aje naa ni Solomon sun ti ko si ji saye mọ bo ṣe sọ.
Nnkan bii aago mẹrin idaji ti iyawo rẹ gbiyanju lati ji i lo ri i pe agba oṣere to maa n sabaa ṣe ere oloyinbo naa ti dagbere faye.
Wọn ti gbe oku rẹ sile igbokuusi kan niluu Abuja to fi ṣe ibugbe.
Ta a ni Solomon Akiyesi?

Oríṣun àwòrán, Solomon Akiyesi/ Facebook
Ọmọ bibi ilu, Ososo, nijọba ibilẹ Akoko-Edo, nipinlẹ Edo ni Oloogbe Solomon Akiyesi.
Nnkan bii ọdun 1990 sisalẹ lo ti bẹrẹ si i ṣe ere ori itage ati sinima.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ere oloyinbo lo n sabaa ṣe ju to si maa n dari, Oloogbe Akiyesi kopa ninu fiimu to to ọgọrun-un nigba aye rẹ.
Lara awọn ere to ti ṣe ni Marry Who You Love, Kiss My Pain, Joy of Nakasha, Heart of a Saint, Deadly Affair, Gen Z Wife ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọmọ orilẹede Naijiria ni Oloogbe Solomon Akiyesi, ṣugbọn wọn mọ riri rẹ nilẹẹ Kenya naa pẹlu awon iṣẹ rẹ to debẹ.
Awọn ololufẹ rẹ lati Kenya ti n kọ orọ ibanikẹdun ranṣẹ, gẹgẹ bi ọpọ ibanikẹdun ṣe ti n jade lati Naijiria naa.


























