A fẹ́ ya ìpáǹle nígbà kan àmọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn òbí wa fi ń bọ́ wa, ló pè wá padà – Damilola Mike-Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Damilola Mike Bamiloye/Facebook
Gbajugbaja oṣere tiata Kristẹẹni nni, Damilola Mike-Bamiloye ti sọ pe nigba ti oun pẹlu awọn ọmọ obi oun n dagba, awọn fẹẹ ya ipanle ọmọ, ṣugbọn ọrọ Bibeli ti wọn n gbọ lo yi aye wọn pada.
Damilola Mike-Bamiloye to jẹ ọkan lara awọn ọmọ agba oṣere Kristẹẹni nni, Mike Bamiloye lo sọrọ naa, lasiko n ba BBC sọrọ laipẹ yii.
Oṣere naa, to tun jẹ adari ere sọ fun BBC nipa boun pẹlu awọn aburo rẹ ṣe dagba, pẹlu awọn iriri rẹ bo ṣe n dagba.
Nigba to n sọrọ, ọkunrin naa sọ pe iyalẹnu lo maa n jẹ foun nigba toun ba n pe orukọ oun nile-ẹkọ, ti ẹnu si maa n ya awọn lẹnu.
O ni asiko toun ba sọ orukọ oun ni ile-ẹkọ ni kekere, awọn eeyan yoo maa sọ pe ọmọ Baba Iṣawuru ree, to si loun maa n wo o pe ki ni wọn n sọ.
"Ile-Ife la ti dagba, iriri akọkọ ti mo ranti ni Agbara Nla ti a ṣe ni 1993, mo ṣakiyesi wi pe nigba ti mo wa nile-ẹkọ, ti a ba n darukọ ara wa, to ba kan asiko t'emi, ti mo ba sọ pe Damilola-Mike Bamiloye lorukọ mi, ti awọn olukọ ba gbọ orukọ yẹn, inu wọn maa dun pe ọmọ Baba Iṣawuru leleyi," O sọ fun BBC bẹẹ.
"Emi kan maa n wo pe taani Baba Iṣawuru, ṣe ẹ mọ pe mo ṣi kere nigba yẹn, ko fi bẹẹ ye mi to, nipa agbegbe iṣẹ tiata ti mo wa.
"Ṣugbọn nigba to ya, mo ṣẹṣẹ wa n mọ pe nnkan wa ninu iṣẹ tiata yii. Igba ti mo n dagba ni mo ṣẹṣẹ mọ pe baba mi gbajumọ.
"Gbogbo nǹkan tí àwọn èèyàn ń là kọjá ni àwa náà ń là kọjá"
Siwaju sii lo sọ pe ko si iyatọ laaarin awọn pẹlu ẹda ti Ọlọrun da, nitori pe gbogbo nnkan ti ọdọ n la kọja ni awọn naa n la kọja gẹgẹ bi eeyan.
"Igba ti a n dagba, gbogbo nnkan ti awọn ọdọ n la kọja ni awa naa n la kọja. Awa naa ni adanwo ti wa, a si maa n la awọn iṣoro kọja," o ṣalaye bẹẹ.
"Igba kan wa ti mama mi pe wi pe iranṣẹ Ọlọrun lo jẹ, o ko gbọdọ ṣiṣe. Ṣugbọn ju iyẹn lọ, mo ṣakiyesi wi pe awọn eeyan n wo wa gan an.
"Ọrọ Ọlọrun ti a tun n gbọ laraarọ tun ṣe iranlọwọ fun wa nipa titọ wa sọna.
"Ọ̀rọ Ọlọ́run lọ jẹ́ ká la àdánwò kọjá"
O ni nnkan ko ye oun nigba toun n dagba, nitori pe oun fẹẹ dabi ọmọ lile tẹlẹ ni, ṣugbọn iwaasu ọrọ Ọlọrun ti awọn obi oun fi n bọ awọn lo pada yi igbe aye wọn pada si rere.
"Awa naa fẹẹ dabi awọn ọdọ lile nigba yẹn, ṣugbọn lẹyin-o-rẹyin, awọn ọrọ Ọlọrun yẹn lo jẹ ka la awọn adanwo naa kọja.
"Gbogbo igba ni mo maa n gbọ ọrọ wi pe mama mi rẹwa. Anfaani lo jẹ fun mi lati ni iru mama ti mo ni. Bi wọn ṣe rẹwa sinu naa ni wọn ṣe rẹwa sita.
"Ọdọ awọn obi mi ni mo kọ nipa ifẹ otitọ, ti mo ri bi baba mi ṣe fẹran mama mi, ti mo si ri apẹẹrẹ ti wọn gbe kalẹ.
"Mo n sọ nibikan wi pe igba miran wa ti baba mi maa se ounjẹ fun mama mi, wọn maa wa bu ounjẹ naa pe ka gbe e lọ fun mama mi. Awọn nnkan wọnyi jẹ iwuri fun wa gidi.
"O tun jẹ iwuri fun mi paapaa la ti jẹ ki n mọ pe ifẹ ni lati farada nnkan.
"Màmá mi ṣòro láti darí nínú fíìmù"
Nigba to n sọrọ nipa didari ere tita, Damilola sọ pe o maa n rọrun foun lati dari baba oun, ṣugbọn ti mama oun maa n fi oju miran wo oun.
"Ti mo ba n dari baba mi ninu ere, wọn maa n tẹle aṣẹ mi, ṣugbọn ti mo ba n dari mama mi, wọn maa n wo pe 'iwọ ọmọ yii, ma da mi laamu jare, nnkan ti mo fẹẹ ṣe ni maa ṣe'.
"Ti eeyan ba wa si agboole tiata onigbagbọ nitori owo, o le ba ijakulẹ pade, eeyan to ba wa, gbọdọ ni erongba wi pe oun fẹẹ fi iṣẹ naa bukun fun awọn eeyan ni.
"Owo ṣe pataki pupọ, ṣugbọn Ọlọrun mọ bo ṣe n pese, o si maa n lo awọn eeyan lati gbọ iṣoro wa."


























