You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àǹfààní márùn-ún tó wà nínú kí obìnrin sùn láì wọ pátá
Ara ẹlẹgẹ ni ara awọn obinrin tori ọpọ iho to wa lara wọn.
Idi si ree ti wọn se maa n wọ oniruuru awọtẹlẹ bii pata, taiti, sikẹti, kọmu ati bẹẹ bẹẹ lọ, ki wọn le daabo bo awọn ohun ẹlẹgẹ to wa lagọ ara wọn.
Sugbọn bawọn awọtẹlẹ wọnyi ti dara to, o tun ni aleebu tiwọn ti awọn obinrin ko ba ko ara wọn nijanu nidi wiwọ wọn.
Ọkan lara wọn igbesẹ to lewu ni pata wiwọ fawọn obinrin lasiko ti wọn ba fẹ sun lalẹ.
Idi ree ti BBC News Yorùbá fi ṣe àgbéyẹ̀wò àǹfààní márùn-ún tó wà nínú kí obìnrin sùn láà wọ pátá tàbí táítìì lọ́nà àti mú kí ìlerà wọn péye sí i.
Awọn anfaani tó rọ̀ mọ kí obìnrin máa sún làiwọ pátá tàbí taiti lalẹ niyi:
Ǹjẹ́ ìwọ mọ pe sísun ni ogolonto lai wọ pátá a máa ṣara rẹ loore? Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ obinrin ni ko mọ eleyi.
Lara awọn anfaani tó rọ̀ mọ kí obìnrin máa sún làiwọ pátá tàbí taiti lalẹ si niyi:
- Alakọkọ ni pé ojú ara obìnrin nílò afẹ́fẹ́ àlàáfíà lalẹ kí obinrin lè fi sún dáadáa
- Ẹlẹẹkeji ni pé aiwọ pata a máa din àìsàn to n wa lati ara kokoro ailefojuri ti a mọ si Yeast Infection, to máa n jẹ ki ojú ara yun obìnrin, ku.
- Anfaani kẹta ni pé ó máa ń dín ooru abẹ kú fún obìnrin yàtọ̀ sì pe o n jẹ́ ki oòrùn wọra sii
- Ikẹrin ni pé sísun lalẹ láìwọ pátá a máa fòpin sí ìṣòro kí ìtàn máa fìgbà gbogbo kọlu ara wọn, kí ara sì máa tá eeyan.
- Èyí tó gbẹ̀yìn ni wípé ọpọ obìnrin gba pe o jẹ ọna láti pé olólùfẹ́ wọn pé iṣẹ́ yà lai fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀.
Amọ ti òórùn bá ka obinrin mọ ìta ni ibòmíràn tí kìí se ilé ara rẹ níbi tí ààbò rẹ ko tí péye,o san kí ó wọ pátá tàbí taiti sun lalẹ láìṣi abẹ́ rẹ sihoho.