You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa nǹkan mẹ́fà tí kò tí ì lójútùú fáwọn olóṣèlú Nàìjíríà bí ìbò ọdún 2027 ṣe ń súnmọ́lé
Bi ojumọ ṣe n mọ ni idibo apapọ ilẹ Naijiria n sunmọle, ti ipo aarẹ yoo si waye loṣu Kin-in-ni ọdun 2027.
Amọ awọn nnkan mẹfa kan wa to n fẹ abojuto ṣugbọn ti awọn oloṣelu ko ti i ri ojutuu rẹ lẹka oṣelu nilẹ yii.
Bi awon ẹgbẹ oṣelu to laami-laaka ṣe n koju wahala tiwọn ni awọn ẹgbẹ alatako naa n koju rogbodiyan abẹle to n da wọn laamu.
Bakan naa ni ajọ eleto idibo ilẹ wa ta a mọ si INEC naa ko ti i yanju awọn ẹjọ to wa ni kootu.
Wọnyi ni awọn nnkan mẹfa ti wọn ko ti i ri ojutuu si i.
Ọjọ iwaju ẹgbẹ oṣelu ADC
Ẹgbẹ oṣelu ADC ti n koju rogbodiyan ni tiẹ o tojo mẹta, eyi si n jẹ ki ohun ti yoo ṣẹlẹ si i ninu idibo to ku dẹdẹ yii maa kọ awọn awoye ọrọ lominu.
Bi ẹgbẹ naa ṣe paara kootu lori awọn olori wọn, bẹẹ ni awọn ti wọn fa kalẹ lati dije naa tun ni ohun ti wọn n koju.
ADC ti fa Atiku Abubakar kalẹ bii ẹni ti yoo dupo aarẹ bayii, nitori oun naa ni eekan oloṣelu to ṣẹku sibẹ, Rotimi Amaechi ni yoo si ṣe Igbakeji rẹ.
Laipẹ yii ni ile ẹjọ giga kan tun paṣẹ pe ADC ko gbọdọ dije ninu ibo ọdun to n bọ, ki ile ẹjọ Kotẹmilọrun too yi idajọ naa pada.
Awọn onimọ nipa oṣelu ti woye pe gbogbo ohun to n koju ADC pata ni wọn gbọdọ ti yanju rẹ ki idibo ọdun to n bọ too de.
Ai ri ojutuu si wahala abẹnu wọn le mu ki omi ti ẹyin wọ igbin wọn lẹnu bi wọn ṣe sọ.
Awọn ẹjọ INEC
Awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn n jẹjọ ni kootu pẹlu ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC ko ti I yanju rẹ.
Bi wọn ko ba pari ẹjọ naa ki ọjọ idibo too pe, o le ṣe idiwọ fun idibo naa bawọn onimọ nipa oṣelu ṣe sọ.
Nigba ti INEC kede bi idibo yoo ṣe lọ ni 2027, wọn ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ṣe iforukọsilẹ awọn oludije wọn titi ọjọ kẹwaa oṣu Karun-un ọdun 2026, ki wọn si pari idibo abẹnu wọn titi ọgbọnjọ oṣu Karun-un ọdun 2026.
Amọ ẹgbẹ oṣelu Youth Party (YP), gbe INEC lọ sile ẹjọ nitori eyi, wọn ni ko ba ofin mu.
Wọn ni ki kootu paṣẹ ki akoko naa wọ oṣu Kẹsan-an fun iforukọsilẹ.
Ile ẹjọ gba eyi wọle, amọ INEC yi i pada nigba ti wọn de ile ẹjọ Kotẹmilọrun.
Fifi orukọ awọn oludije lede
Ẹgbẹ oṣelu APC wa lara awọn ti wọn n fa sẹyin ninu fifi orukọ oludije wọn lede.
Awọn kan tiẹ sọ ninu awọn to yege ibo abẹle, pe awọn kan lo wa nidii ai tete fun awọn ni iwe ẹri mo yege.
Wọn n fapajanu pe latigba ti idibo abẹnu naa ti waye, wọn ko ti I fi orukọ awọn oludije tootọ sita, wọn ko si fun wọn niwe ẹri mo yege.
Bakan naa ni awọn ẹgbẹ alatako kan naa ṣi wa nidii ai ti i ri orukọ wọn, wọn ni wọn n tẹ ẹtọ awọn loju mọlẹ ni.
Fun apẹẹrẹ, ẹgbẹ oṣelu NDC ti Rabiu Kwankwaso ati Peter Obi wa naa n koju iṣoro kan naa lẹka oludije ipo gomina .
Amọ APC ninu awijare wọn, sọ fun BBC pe eto naa n pẹ́ kawọn le ṣe otitọ pẹlu kaluku ni.
Bala Ibrahim, Adari ikede apapọ fun APC, ṣalaye pe gbogbo aroye to wa niwaju ẹgbẹ naa lo yẹ kawọn wadii ẹ yekeyeke.
Idarapọ awọn alatako
Bi ẹgbẹ oṣelu alatako kọọkan ṣe n ba iṣoro kan tabi ikeji yii, o ṣee ṣe kawọn kan parapọ di ẹgbẹ kan ṣoṣo ṣaaju idibo 2027, bi wọn ba fẹ ṣẹgun APC to n ṣejọba lọwọ.
Ọpọ igba ni awọn ẹgbẹ yii ti fẹsun kan APC pe oun lo n da aarin awọn ru labẹnu,
Wọn ni APC n ṣe bẹẹ ko ma baa koju atako to le.
Amọ ọpọ igba ni APC naa ti sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.
Iwoye awọn onimọ oṣelu ni pe ti ọrọ ba doju ẹ tan, ti awọn ẹgbẹ alatako si fi igbanu kan ṣoṣo ṣe ọja, o ṣee ṣe ki won di ẹgbẹ kan ṣoṣo ti yoo koju Aarẹ Bola Tinubu ni 2027.
Jonathan to fẹẹ dupo aarẹ
Ẹgbẹ alatako, PDP, igun ti Tanimu Turaki n lewaju fun lo kede Goodluck Jonathan, aarẹ tẹlẹ bii ẹni ti yoo dupo aarẹ ni 2027 ninu ẹgbẹ naa .
Eyi n waye lasiko ti PDP ti pin si igun meji, nitori igun Nyesom Wike ti i ṣe minisita ilu Abuja naa ti fa oludije kalẹ.
Sandy Onor ni awọn fa kalẹ ni tiwọn.
Ko ti i ye eeyan boya INEC yoo gba awọn ohun ti igun Turaki ko kalẹ, bi orukọ Abdulrahman Muhammad ṣi ṣe wa loju opo INEC bii ẹni ti yoo dupo aarẹ.
Eyi n jẹ ki iyemeji maa wa lori Jonathan ti wọn tun fa kalẹ yii.
Awọn kan ti kọkọ pe ẹjọ, pe ki kootu paṣẹ pe Jonathan ko le dije, ṣugbọn ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria sọ pe Jonathan lẹtọọ ati dije lẹẹkan si I ni Naijiria.
Amọ Jonathan funra rẹ ko wi nnkan kan mọ, o si n jọ pe pe oun gan-an ko ti i mọ boya yoo dije tabi bẹẹ kọ.
Ọjọ iwaju NDC
Iforukọsilẹ ẹgbẹ NDC ti Peter Obi ati Rabiu Kwankwaso n ṣe n koju atako, lẹyin ti ifisun de kootu pe ki wọn tu ẹgbẹ naa ka.
Ọmọwe Umar Ardo, oludije fun ipo gomina nipinlẹ Adamawa nigba kan to tun jẹ olori ninu ẹgbẹ ADC, to si tun gbiyanju lati da ẹgbẹ ADA silẹ lo pe NDC ati INEC lẹjọ.
Alaye Ardo ni pe NDC ko kunju oṣunwọn labẹ ofin Naijiria.
Ohun ti yoo ṣelẹ si NDC bi idibo ṣe n sunmọle ko ti i ye ọpọ eeyan bayii.
Ohun ti ile ẹjọ ba sọ lori rẹ ni yoo si sọ ibi ti ọrọ ẹgbẹ naa yoo ja si.