Wo àwọn àsìkò tí ìwa ipá ti ṣẹlẹ̀ káàkiri Nàíjíríà látìgbà tí ọ̀rọ̀ ètò ìdìbò 2027 ti bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Latigba ti eto idibo apapọ ile Naijiria fun ọdun 2027 ti bẹrẹ, ni oniruuru iwa ipa bii ikọlu lasiko ipolongo ati awọn miran ti n lọ.
Bawọn ọmọ ẹgbẹ alatako ṣe n kọlu ara wọn, naa lawọn oludije sipo oṣelu n sọrọ kugbakugbe sira wọn, ko da ti awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu ko dẹkun lati maa sọrọ abuku sawọn alatako.
Ninu oṣu kẹjọ, ọdun yii ni ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ranṣẹ pe gbogbo awọn oludije, to fi mọ awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu kọọkan, lati tọwọ bọwe adehun wi pe wọn yoo gba alaafia laaye ni gbogbo asiko ipolongo ibo ati ọjọ idibo.
Bi awọn ọmọ egbe oṣelu APC ṣe n ṣe ikọlu sawọn alatako, bẹẹ naa lawọn alatako n ṣe ikọlu sira wọn ati bẹẹbẹẹlọ.
Eyi lo si tapa si iwe ofin tuntun ti idibo,, ti ọdun 2026, to fi mọ iwe adehun alaafia ti awọn oludije ati awọn alakoso egbe kọọkan.
Ki lo sẹlẹ ṣaaju
Yatọ si awọn ikọlu to ti waye ṣaaju, ni nnkan bi ọjọ meloo sẹyin ni ikọlu miran tun waye nipinlẹ Delta, nibi ti eeyan mefa ti ku, ti awọn miran si tun farapa.
Nibi ipolongo ibo fun Sẹnetọ Ovie Omo-Agege n'ilu Uduere, ni ija oṣelu ti bẹ silẹ. Omo-Agege n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) for di fun idibowadii ti awọn kọkọ ṣe, fihan pe eeyan mẹfa lo ku, ti ọpọlọpọ si farapa.
Omo-Agege n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) for di fun idibo ọdun 2027.
Bakan naa, l'Ọjọru to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo tun fidi rẹ mulẹ pe ikọlu oṣelu miran tun waye nipinlẹ naa.
Ọlọpaa sọ pe awọn agbebọn mẹta ni wọn ṣe ikọlu si awọn ọmọ egbe oṣelu NDC, lasiko ti wọn n ṣe ipolongo niluu Benin.
Oniruuru ikọlu lo ti mu ọpọ ẹmi lọ lọdun 2026, lori eto idibo ọdun 2027 to n bọ lọna.
Awọn ikọlu to ti kọkọ waye
End of podcast promotion
Rogbodiyan to waye laipẹ yii niluu Eko ni ọpọ alẹnulọrọ koro oju si.
Bi African Democratic Congress ṣe koju ikọlu tiẹ naa lo ṣe kan PDP nibi awọn ipolongo ibo to waye lawọn ilu bii Enugu, Benue Eko.
Niṣe ni ọpọ eeyan to wa sibi eto naa bẹrẹ si sa asala fun ẹmi wọn.
Wọn fọ igo silẹ kaakiri ibudo ti eto naa ti waye, awọn afurasi ọmọ ita to wa nibẹ si ba ọpọ mọto to jẹ tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NDC to wa nibẹ jẹ.
Ni ipinlẹ Gombe, lọjọ kọkanla oṣu Kọkanla yii ni awọn afurasi janduku da ina taya soju ọna, wọn si fọ awon gilasi ọkọ Isa Pantami to n dije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa.
Eyi waye lasiko ti oloṣelu naa wa siluu rẹ fun ipolongo ibo.
Ni Katsina, awọn afurasi janduku kọlu ẹgbẹ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC, lasiko ti wọn n lọ so ibi ipolongo ibo fun Gomina Dikko Radda.
Awọn ọlọpaa sọ pe niṣe ni awọn ero di oju ọna pa ni Yankara, wọn si bẹrẹ si I ju okuta, bẹẹ ni wọn n dana sun awọn iwe alẹsode ipolongo ibo lẹyin ti Gomina Dikko Radda kọja loju ọna ọhun lọ si ibi ipolongo APC ni Faskari.
Awọn eeyan farapa lẹyin tawọn janduku dana sun awọn ọkọ.
Bi African Democratic Congress ṣe koju ikọlu tiẹ naa lo ṣe kan PDP nibi awọn ipolongo ibo to waye lawọn ilu bii Enugu, Benue, Delta, Edo ati Sokoto.
Eto idibo nilẹ Naijiria
O fẹẹ je ko tii si eto idibo kan to waye nilẹ Naijiria, ti ko si eyi to ni iwa ipa ninu, iyẹn latigba ti orileede naa ti gba ominira. Lọdun 1960.
Eto idibo akọkọ to waye lọdun 1964 si 1965 ni akọsilẹ awọn to ba iwa ipa lasiko naa lọ.
Awọn eeyan to le ni igba ni padanu ẹmi wọn nigba naa, paapaa lekun Guusu Iwọ-Oorun, gẹgẹ bi ajọ HRW ṣe sọ ninu akọsilẹ wọn.
Bẹẹ naa lọrọ tun ri lẹyin eto idibo to waye lọdun 1983, nibi ti ọpọ ẹmi ati dukia ti ṣofo danu.
Fun awọn to ba tun ranti daadaa wi pe lasiko eto idibo Aarẹ ti ọdun 1993, eyi ti ọpọ nigbagbọ wi pe oun lo je eto idibo to lọ daadaa julọ ninu itan Naijiria, ko si akọsilẹ wi pe iwa ipa ko ṣẹlẹ.
Bi Ọgagun ile Naijiria nigba naa, Ibrahim Babangida ṣe wọgile eto idibo ọhun, ni wahala ti bẹ silẹ pẹlu ifẹhonuhan.
Ẹgbẹ olupolongo kan ti wọn pe ni 'Campaign for Democracy (CD)', eyi ti Beko Ransom-Kuti jẹ olori rẹ sọ pe awọn eeyan to le ni ọgọrun kan, ti wọn n lọ pelu alaafia ni awon eleto aabo yinbọn pa danu, lojuna lati dẹwọ wahala nibi ifẹhonuhan to waye ninu oṣu Keje.
Eto iṣejọba awa-ara-wa
Ṣugbọn ṣa sibẹ, ko sohun to yatọ ninu fifa wahala lasiko ati lẹyin eto idibo, latigba ti Naijiria ti bẹrẹ ijọba awa-ara-wa lọdun 1999.
Kete ti ajọ eleto idibo kede Olusegun Obasanjo gẹgẹ bi oludije to jawe olubori lasiko eto idibo ọdun 1999, ni wahala miran tun bẹ silẹ.
Iwadii fidi rẹ mulẹ pe awọn ọgọrin ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ lasiko wahala naa.
Bẹẹ naa lawọn eeyan ti ko din ni ọgọrun kan padanu ẹmi wọn kaakiri ipinlẹ to wa ni Naijiria lori eto idibo apapọ ọdun 2003 to gbe Obasanjo wọle fun saa keji.
Awọn araalu to le lọọdunrun ni wọn pade iku ojiji lasiko eto idibo ọdun 2007, koda ti awọn to le laadọrin naa tun ku ṣaaju asiko ọhun.
Lọdun 2011, lẹyin eto idibo to gbe Goodluck Jonathan depo Aarẹ, awọn araalu ti ko din ni ẹgbẹrin ni wọn ku laaarin ọjọ meta ti wahala fi bẹ silẹ lawọn ipinlẹ mejila to wa lẹkun Ariwa Naijiria.
Iṣẹlẹ yii lo si buru julọ ninu itan oṣelu nilẹ Naijiria.
Ko tan sibẹ, ṣaaju ati lẹyin eto idibo apapọ ọdun 2015, awọn to le ni ọgọrun kan ni wọn padanu ẹmi wọn , gẹgẹ bi ajọ agbaye ti ICG ṣe sọ.
Bẹẹ naa ni ajọ European Union Election Observation Mission fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan to to aadoje ni wọn ku lasiko eto idibo ọdun 2015 ati 2019.
Sugbọn ṣa, laaarin oṣu Kẹrin, ọdun 2014 si osu Karun-un, ọdun 2022 iwadii fidi rẹ mulẹ pe awọn ti ko din ni ọtalelọọdunrun ni wọn padanu wọn lasiko eto idibo apapọ to waye kaakiri Naijiria.
Bẹẹ ni wọn tun ji awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo mọkanlelaadọta gbe lawọn asiko eto idibo ọhun.
Ki lo n fa awọn wahala oṣelu yii?
Ninu iwadii, a gbọ pe oniruuru awọn nnkan lo ṣẹlẹ to fi di pe wahala bẹ silẹ, ti awọn eeyan si n padanu ẹmi ati dukia wọn.
Lara awọn ohun to ṣẹlẹ ni; lilu eeyan pa, igbanipa, jija apoti ibo gba, dida eto idibo ru, ijinigbe, sisọrọ to le da wahala silẹ, yinyin ibọn, iwa janduku ati bẹẹbẹẹlọ.
Yatọ si awọn araalu ti wọn ku, awọn oṣiṣẹ eleto aabo naa pade iku ojiji lenu iṣẹ wọn lasiko eto idibo.



























