Olorì Naomi Silekunola sọ̀rọ̀ nípa ìgbé ayé rẹ̀ bíi aya ọba, akẹ́kọ̀ọ́ àti òjíṣẹ́ Olúwa

Àkọlé fídíò, Olorì Naomi Silekunola sọ̀rọ̀ nípa ìgbé ayé rẹ̀ bíi aya ọba, akẹ́kọ̀ọ́ àti òjíṣẹ́ Olúwa
Olorì Naomi Silekunola sọ̀rọ̀ nípa ìgbé ayé rẹ̀ bíi aya ọba, akẹ́kọ̀ọ́ àti òjíṣẹ́ Olúwa
Published

Olori Naomi Silekunola ti ṣalaye fun BBC News Yoruba wi pe ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin rẹ ati Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwunsi, Ojaja Kẹta,bo tilẹ jẹ pe o ti kuro laafin.

Olori Naomi sọ pe ''baba ni Ooni jẹ fun mi ati ọmọ mi Tadenikawo.

Eeyan maa n gbade Olori wa lati ọrun ni, irinajo bi mo ṣe pade Ooni ko ṣe e ṣalaye tori iṣẹ Oluwa ni mo n ṣe.

Olori le kuro laafin amọ aafin kii fi olori silẹ, bi eeyan ba jẹ olori, ko le yi pada.

Ẹmi ni olori, akaimoye ẹni ti ko fẹ ọba ri, ti a si n pe wọn ni iya.''