Pete Edochie, àgbà òṣèré tíàtà, jáde láyé

Aworan Pete Edochie
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agba ọjẹ oṣere tiata, to tun jẹ ilumọka, Pete Edochie ti jade laye ni ọdun mọkandinlọgọta, 79.

Iroyin yii lo tẹ wa lẹti ninu atẹjade kan ti ọmọ rẹ, Leo Edochie, fi sita ni owurọ Ọjọ kẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2026 pe oloogbe naa jade laye nipinlẹ Enugu.

Bakan naa ni atẹjade naa tun fidi rẹ mulẹ pe aisan jẹjẹrẹ ti n ba oloogbe naa finra ko to di pe o jẹ ipe Olọrun

Wọn bi Pete Edochie ni ọjọ keje oṣu kẹta ọdun 1947 nipinlẹ Enugu

Baba rẹ jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ Reluwe Naijiria, to si jẹ iṣẹ baba rẹ lo gbe lọ si ipinlẹ Kaduna, ibi to ti dagba.

Pete Edochie lọ si ile ẹkọ Saint Patrick's and Saint James Primary Schools ni Zaria, ko to tun morile Saint John Secondary School, Kaduna, ni 1960.

Lẹyin ọdun mẹrin, o dara mọ baba rẹ nidi iṣẹ Reluwa ṣugbọn mọlẹbi naa kuro nipinlẹ Kaduna saaju ki ogun abẹle to bẹrẹ

Ni ẹni ogun ọdun, Pete Edochie bẹrẹ iṣẹ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Eastern Nigerian Broadcasting Corporation.

Ni ọdun 1980, Pete Edochie lọ si ile ẹkọ British Broadcasting Corporation fun imọ si, to si pada di ọga agba akọkọ fun ileeṣẹ ijọba Anambra Broadcasting Service 3FM Stereo ni ọdun 1987.