Makinde ṣàgbédìde òfin tó de àwọn fijilanté àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò abẹ́nú míì

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti buwọlu ofin lati mu atunṣe ba bi awọn ẹṣọ aabo abẹnu to fi mọ awọn lẹgbẹlẹgbẹ ṣe n ṣiṣẹ ni ipinlẹ naa ti wọn pe ni Executive Order 001 ti ọdun 2026.

Makinde gbe igbesẹ naa n waye lati ri daju pe gbogbo awọn ẹgbẹ to ni i ṣe pẹlu eto aabo ni ipinlẹ naa bii awọn fijilante, atawọn mii n ṣiṣẹ labẹ ilana ofin to fi aaye gba alaafia, ṣiṣe iṣẹ letoleto ati titẹle ofin ipinlẹ naa.

Nigba to n buwọlu ofin naa ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, Makinde ni ofin naa pọn dandan pẹlu bi ipenija aabo to n koju awọn ilu ati ileto ni ipinlẹ ọhun ṣe n peleke ni ojoojumọ ati bi awọn eeyan ṣe n kora wọn jọ da egbẹ silẹ lati koju ipenija naa lai si akoso to peye.

Bo ṣe woye pee ọrọ aabo jẹ ojuṣe ijọba atawọn araalu, o ṣalaye pe ofin naa jẹ agbekalẹ lati ri daju pe gbogbo awọn lẹgbelẹgbẹ to ba maa da si ọrọ aabo fi orukọ silẹ pẹlu ijọba, ki ijọba si maa mojuto ojuṣe wọn.

Bakan naa lo tẹmpelemọ pe awọn eeyan gbọdọ jina si awọn iwa tabi ohun to le mu iwa ẹlẹyamẹya wa, ti wọn si gbọdọ yago fun awọn ohun to le mu ki wọn maa nawọ aleebu tabi koju oro sawọn ẹya kan ni pato lai si ẹri to daju.

O ni ijọba ko ni fi aaye iwa ọdaran tabi iwa jagidijagan labẹ fifi eto aabo boju.

Nigba to n sọrọ lori awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni awọn ile ẹkọ meji ni ijọba ibilẹ Oriire ni ipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun, gomina sọ aridaju rẹ fawọn eeyan pe ijọba pẹlu ajọṣepọ awọn ẹṣọ aabo n ṣiṣẹ takuntakun lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ naa.

Gomina Makinde tun gboriyin fawọn ẹṣọ aabo atawọn araalu fun suuru wọn ati bi wọn ṣe n ko ara wọn ni ijanu ni asiko yi, to si jẹjẹẹ lati tun mu eto aabogbopọn si kaakiri ipinlẹ Oyo.

O wa rọ awọn eeyan lati maa fi gbogbo awọn iwa ko tọ ti wọn ba kẹfin ni agbegbe wọn to ijọba leti dipo gbigbe igbesẹ lọwọ ara wọn ati ṣiṣe awọn ohun to lodi si ofin.

Ṣaaju ni Kọmiṣanna fun eto idajọ ipinlẹ Oyo, Abiodun Aikomo ti ṣalaye pe gbogbo awọn ẹgbẹ to ba fẹ maa pese aabo fun ilu ti wọn si ni ju eeyan marun-un lọ gbọdọ fi to ijọba leti, ki wọn si lọ forukọ silẹ lati ọfiisi olubadamọran gomina lori eto aabo.

Aikomo fi kun pe awọn ẹgbẹ to ti wa tẹlẹ naa gbọdọ lọ forukọsilẹ pẹlu ọfiisi olubadamọran gomina lori eto aabo, o pẹ ju, ọjọ mẹta lẹyin ti gomina ti buwọlu ofin tuntun yii, ki wọn si gba iwe ẹri wọn dani.

O ni eyi maa ṣe iranwọ fun ijọba lati mọ awọn eeyan to n gbe ohun ija dani ati pe o maa jẹ ki ijọba le ṣe amojuto awọn to n wọṣọ ẹṣọ aabo kaakiri ipinlẹ naa.

O ṣekilọ pe awọn to ba kọ lati ṣe ohun ti wọn sọ yii ni wọn maa gba pe o tẹ ofin loju mọlẹ, ti wọn si maa lugbadi ofin.

O fi kun pe ijọba ti fun awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo ara ẹni laabo ilu, NSCDC laṣẹ lati ri pe gbogbo eeyan lo tẹle ofin tuntun yii ni kete ti gomina ti buwọlu u.