You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Afeez Owo ṣàlàyé ohun tó fa ìyapa láàrin òun àti Mide lásìkò kan nínú ìgbéyàwó wọn
Gbajugbaja olootu ere ati oṣere ori itage, Afeez Abiodun tọpọ mọ si Afeez ọwọ ti ṣalaye ohun to fa iyapa laarin oun ati iyawo rẹ, Mide Martins laarin kan ninu igbeyawo wọn.
Afeez Owo ni Ọlọrun nikan lo le ṣe ohun gbogbo laye, ati pe ko si ẹda kan to le da ohun kan ṣe.
Afeez fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan ori ayelujara Africanalist.
O ṣalaye wi pe ''aimọye eeyan ti wọn kii ṣe ilumọọka ti igbeyawo wọn ti tuka, mo ti lọ sibi igbeyawo ti wọn ṣe lọwọ Satide ti igbeyawo naa si tuka lẹyin ọjọ meji.
Ija kan ṣoṣo ti mo ja ri pẹlu iyawo mi lati igba ti a ti ṣe igbeyawo naa ni igba ti a yapa.
Ija naa burẹkẹ gan an, amọ, a pari ọrọ naa, a si tun pada lati maa jọ gbe papọ.
Afeez Owo ni oun ko gbọ agbọye lo jẹ ki inu ṣi oun bi ti ọrọ naa si di ija laarin oun ati Mide.
''Inu kan bi mi ni, mo si da gbogbo rẹ ru, ati pe itakun ayelujara naa dakun ọrọ ọhun.
Nitori nnkan to yẹ ka pari laarin ara wa ni, amọ, ṣe ni wọn gbe ọrọ naa sori ayelujara wi pe mo ti kuro nile fawọn o.
Wọn ni mo da awọn ọmọ silẹ lọ, loootọ si ni mo lọ sile itura fun ọjọ meji nigba ti inu n bimi.
Ọgbẹni Abiodun ni nnkan to ṣẹlẹ ni pe oun gba ile itura lọ nigba ti inu n bi oun.
Amọ, o ni iyawo oun sọ pe oun binu da ọmọ silẹ kuro nile foun.
O ni iyẹn gan an lo jẹ koun pinu lati kuro nile gan an.
Mide jẹ onitiju mi, ko si nnkan to ba ni ki n ṣe ti n ko ni ṣe - Afeez Owo
Gbajumọ oṣere naa sọ pe funra iyawo oun naa lo wa bẹbẹ wi pe koun jeburẹ awo olugbẹbẹ.
Afeez Owo ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe Mide koun jẹ gẹgẹ bi ọkọ ju osẹre lọ tori o mọ pe oun maa n fifẹ han si i.
Ilumọọka olootu ere naa sọ pe ko yẹ ki oun yin ara oun, amọ, oun le fi gbogbo ẹnu sọ pe oun ni Ọlọrun Mide, oun naa si tun ni baba rẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe Mide ni Ọlọrun oun naa, oun naa si ni iya oun.
''Lai si Mide, o ṣee ṣe ko ma si ẹni to n jẹ Afeez Abiodun.
Lai si Afeez Abiodun, o ṣee ṣe ko ma si Mide, iyawo mi nikan ni ẹnikan to le bami sọrọ ti mo si maa gbọ lẹsẹ kẹsẹ.
Mide jẹ onitiju mi, ko si nnkan to ba ni ki n ṣe ti n ko ni ṣe.
Ti Mide ba sọ pe ki n maa bayin ja, mo maa bayin ja lai nidii, ko kan mi.
Ti o ba si ni ki n maa bayin rẹrin-in naa, mo maa rẹrin-in ni o.
Afeez Owo ni lara ẹkọ toun ti kọ ninu igbeyawo oun pẹlu Mide to n lọ si ọdun mejilelogun bayii ni pe ko dara ki ọkunrin da wa lai ni iyawo.
O ni ọpọ anfaani lo maa fo iru ọkunrin bẹẹ ru tori ko ni si alabaro fun un.