Kí ni ká ti pe èyí? Àṣòfin tẹ́lẹ̀, 'Radical' fi èpè bọnu níwájú ààfin Olubadan lẹ́yín tó pàdánù tíkẹ́ẹ̀tì

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Niṣe ni awọn eeyan n sọ pe ere ni awada ni, to si dabi ẹni pe awọn eeyan ba n wo ere agbelewo ni igboro ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.

Eyi waye bi oludije si ile igbimọ aṣofin to fẹ ṣoju Ibadan North Constituency II, Olusegun Olaleye, ti ọpọ mọ si Radical Brother ṣe fidi rẹmi nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Lẹyin to fidi rẹmi naa lo gbe agogo, to si bẹrẹ si ni pariwo kaakiri gbogbo ilu Ibadan.

Ninu fidio to gba ori ayelujara ṣafihan bi Olusegun Olaleye ṣe gbe agogo sọwọ, to si yọri sita ninu ọkọ to n gbe kiri.

Fidio naa, pẹlu ọrọ ti Olusegun n sọ fi han iwaju aafin Olubadan ilẹ Ibadan lo wa to si n sọ awọn alufanṣa si ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije sipo gomina, Sharafadeen Alli.

Iroyin ni olu ile ẹgbẹ APC ni Olusegun Olaleye ti kọkọ bẹrẹ awọn ọrọ alufanṣa rẹ ko to di pe o lọ si iwaju aafin Olubadan.

"Mo fi aṣẹ ọrun sọrọ, gẹgẹ bi ẹri ninu eto idibo yii, opin de si Sharafa, ninu irinajo gomina rẹ, opin de, Tunde Alabi, opin de si gbogbo yin.

"Ninu irinajo eto idibo yii, Sharafa, o o tun moke, to ba mu irọ lo mu, aṣẹ gun un nitori o fẹ yan ọmọ alaini jẹ.

"Idibo emi Olusegun Olaleye, o fẹ yan mi jẹ, o yan ọpọlọpọ eeyan jẹ. Niwaju aafin ni mo ti kede rẹ bayii, Kabiyesi, wọn fẹ yan emi ọmọ yin jẹ, mo wa pa a laṣẹ, Sharafa Alli, opin de."

Eyi ni awọn ọrọ alufanṣa ti Olaleye bo ṣe n lu agogo kaakiri ilu Ibadan, to si ni oun fẹ wo ọna to maa gbegba to maa fi jawe olubori nibi eto idibo.

Ibeere to gbẹnu ọpọ eeyan bayii ni pe ki ohun to waye laaarin Olaleye ati Sharafadeen Alli to fi n sọ gbogbo awọn ọrọ to n sọ yii.

Olusegun Olaleye, lo ti fi igba kan ri jẹ aṣofin ile igbimọ ipinlẹ Oyo fun ọdun mejọ labẹ iṣejọba gomina Abiola Ajimobi.

O tun fẹ dije lọ sile aṣofin nibi eto idibo ọdun 2027 to n bọ lọna labẹ ẹgbẹ oṣelu APC amọ to fi fidi rẹmi nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ naa to waye lọjọ ru.