You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébọn tún yabo ilé ẹ̀kọ́ méjì ní Borno, jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ
Lọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn tun yabo ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ati ti girama; Central Primary School, Mussa ati Government Secondary School toun naa wa ni Mussa, nijọba ibilẹ Askira-Uba, ipinlẹ Borno.
Ọpọ akẹkọọ ni iroyin sọ pe wọn ti di awati lẹyin ti awọn agbebọn yabo awọn ile ẹkọ naa lapa Ariwa Ila Oorun Borno.
Laarọ ọjọ yii kan naa ti awọn agbebọn kan ṣọṣẹ niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo, ti wọn pa olukọ, ji ọga agba atawọn akẹkọọ gbe ni wọn tun ṣoro nile ẹkọ ni Borno.
Ajinigbe lo gbe awon akẹkọọ to di awati lọ ni tabi awọn ọmọ naa lo sa wọgbo funra wọn?
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Borno, Nahum Daso, ṣalaye fun BBC pe awon ajinigbe naa yade ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ.
"Wọn yabo ile ẹkọ naa lati ji awon akẹkọọ gbe lọ.
"A ko le fidi ẹ mulẹ pe wọn ji awon akẹkọọ gbe, amọ ohun ti a le fidi rẹ mulẹ ni pe ọpọ awọn akẹkọọ sa wọ igbo lọ lasiko ti awọn ajinigbe naa de."
Bẹẹ ni Alukoro ọlọpaa Borno ṣalaye.
O ni ọpọ akẹkọọ ni wọn ko ti I pada wale titi di irọlẹ ọjọ Ẹti naa.
Daso ṣalaye pe awon ti n ṣe onka awọn ọmọ naa lati mọ awon to ti de atawọn ti wọn ko ti I jẹ riri.
"Lọwọlọwọ, a n ṣe onka ati akọsilẹ awọn ọmọ naa, awọn kan ti pade de."
"Irọ ni pe awọn akẹkọọ lo sa wọgbo funra wọn, agbebọn lo ko wọn lọ, o to ọmọ 43 ti wọn fi ọkada rẹpẹtẹ gbe lọ" Bukar Buba, araalu
Olugbe agbegbe Mussa kan, Buka Buba, ẹni to ni ọmọ oun obinrin wa lara awọn ọmọ to sọnu, ṣalaye fun BBC nirọlẹ ọjọ Ẹti naa, pe oun ti ọlọpaa sọ ko ri bẹẹ.
Buba sọ pe irọ gbuu ni pe awon akẹkọọ lo funra wọn sa wọgbo lọ.
" Ọpọ ọmọ ni awọn agbebọn to dihamọra ogun naa ko lọ, ọkada ni won fi ko wọn lọ.
"Koda gan-an, ọmọ temi naa wa lara awon ti won gbe lọ, ọmọbinrin ni.
"Ko pẹ ti ikọ ọlọpaa to n yi agbegbe naa po kuro nibẹ ti iṣẹlẹ yii fi waye.
"Bi awọn ọlọpaa ṣe lọ bayii, ko to ọgbọn iṣẹju ti awọn to ṣekọlu naa fi wọ ilu wa.
"Akẹkọọ ti wọn ko lo fẹẹ to mẹtalelogoji (43), pupọ wọn si wa laaarin ọmọ ọdun mẹta si mẹfa."
Bẹẹ ni Bukar ṣalaye.
O fi kun un pe awon akẹkọọ mi-in ti ọjọ ori won ti wọ mẹẹẹdogun naa wa lara awon ti won ji lọ.
"Niṣoju araalu ni ajinigbe ti ko wọn lọmọ lọ"
Buba ṣalaye pe niṣoju awon araalu bayii ni awọn agbebọn naa ṣe n ko awon akẹkọọ wọnyi lọ.
O ni awon olugbe Mussa n wo wọn kedere lati ori apata kan ti wọn farapamọ si, lasiko ti awọn agbebọn n fi ọkada ko awọn ọmọ naa lọ.
"Ọkada ti wọn gbe wa pọ, a o le ka a tan."
Awọn ẹka iroyin lagbegbe Borno paapaa kin ọrọ ijinigbe yii lẹyin, ohun ti wọn n sọ ni pe awọn ajinigbe lo gbe awon ọmọ to di awati lọ.
Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ko ti I si ẹgbẹ agbesunmọmi kankan to jade sọrọ bi wọn ṣe maa n ṣe nigba mi-in, ti wọn yoo ni awon lawon wa nidii ikọlu kan.
Ṣugbọn ṣaa, akiyesi ti awọn alaṣẹ sẹ bi wọn ṣe wi, ni pe awọn ikọ Boko Haram tabi akẹgbẹ wọn ti I ṣe Islamic State West Africa Province (ISWAP) lo ṣe ikọlu naa.
Eyi kọ ni igba akọkọ, ikeji tabi ikẹta ti ajinigbe yoo ya wọ ile ẹkọ lorilẹede yii, paapaa ni apa Ariwa, ti wọn yoo gbe awọn akekọọ ati olukọ lọ nigba mi-in.
Ṣugbọn ti ọjọ Ẹti yii tun ko ọpọ ọmọ Naijiria lọkan soke yatọ.
Lọjọ kan naa ati asiko kan naa ti wọn n ṣoro l'Ariwa ni wọn tun n ko girigiri ba awọn eeyan nipinlẹ Oyo.
Bi wọn ṣe n daamu agbegbe Mussa ni Borno ni wọn n ko awọn akẹkọọ wọgbo lọ ni Ahoro -Esinele, l'Ogbomoso. Wọn pa tiṣa, gbe ọga agba ile ẹkọ wọgbo lọ ni Ahoro-Esinele.
Agbébọn pa olùkọ́, jí ọ̀gá àgbà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ l'Ogbomoso
Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko ti i le fi iye wọn mulẹ lọ nibi ikọlu naa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti naa, o ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ yii ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ.
Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de bo ṣe wi.
Bi wọn ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.
Ninu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn fun olukọ kan, ẹni ti iroyin sọ pe o ti jade laye, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.
"Awọn agbebọn ti wọ agbegbe Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo. Wọn gbe ọga ile ẹkọ ati awọn akẹkọọ ti a ko mọ iye won lọ"
"Ẹni to fi to wa leti sọ pe wọn yinbọn mọ olukọ kan lasiko ikọlu naa."
Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.
Ajọ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Oyo paṣẹ titi awọn ile ekọ pa lawọn ijọba ibilẹ kan, fi idi iku olukọ mulẹ
Latari iṣẹlẹ yii, Ajọ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Oyo, 'Oyo State Universal Basic Education Board (OYOSUBEB), ti paṣẹ pe ki awọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ to wa lagbegbe naa ati ayika rẹ wa ni titipa.
Alaga ajọ naa, Ọmọwe Nureni Aderemi Adeniran, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita.
Awọn ijoba ibilẹ bii Surulere, Ila-Oorun Oyo, Oriire ati Olorunsogo ni ile ẹkọ titipa naa kan.
Ajọ OYOSUBEB ṣalaye bi iṣẹlẹ yii ṣe ba wọn lọkan jẹ to, wọn ba awon ẹbi ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun.
Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe wi, wọn ko le sọ pato iye akẹkọọ ti awọn agbebọn gbe lọ.
OYOSUBEB sọ pe awọn ẹṣọ alaabo ti bẹrẹ si I wa awọn ti won gbe lọ naa kiri awọn igbo to wa lagbegbe yii.
Awọn alaṣẹ n ṣiṣẹ tọ ipadabọ awọn ti wọn ji gbe
Ọmọwe Adeniran fi idaniloju rẹ han, pe ijọba atawọn agbofinro yoo ṣiṣẹ tọ ipadabọ awon ti won ji gbe naa.
O fi kun un pe wọn ti gbe ikọ ọtelẹmuyẹ kan dide lati ri si eyi, labẹ idari Kọmiṣanna ọlọpaa.
Bakan naa ni awọn alaṣẹ pe fun alaafia laaarin awon eeyan agbegbe naa, wọn rọ wọn lati ma ṣe gbe iroyin ohun ti ko ṣẹlẹ jade, eyi to le mu aibalẹ ọkan wa lagbegeb naa.
OYOSUBEB daro olukọ to ba iṣẹlẹ naa lọ, wọn fidi iku rẹ mulẹ.
Bakan naa ni wọn ṣapejuwe rẹ bii olukọ to jara mọṣẹ, ti ipinlẹ Oyo ko si ni I gbagbe rẹ.