Àwọn sinimá kan wà tí mo ṣe tí àwọn òbí mi kò lè wò nítorí… - Bolaji Ogunmola, òṣèré tíátà

Àkọlé fídíò, Àwọn sinimá kan wà tí mo ṣe tí àwọn òbí mi kò lè wò nítorí… - Bolaji Ogunmola, òṣèré tíátà
Àwọn sinimá kan wà tí mo ṣe tí àwọn òbí mi kò lè wò nítorí… - Bolaji Ogunmola, òṣèré tíátà
Published

Gbajumọ oṣere, Bolaji Ogunmọla ti ṣalaye irinajo rẹ si sinima ṣiṣe ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC News Yoruba.

Gbajumọ oṣere naa to jẹ oju mimọ lagbo sinima ede oyinbo ṣalaye pe kii ṣe pe oun ko le ṣe sinima ede Yoruba, ṣugbọn awọn onisinima ede oyinbo lo ni wọn saba maa n pe oun julọ.

O ṣalaye pe ko rọrun fun oun lati gbe ipinnu oun kalẹ niwaju awọn obi oun pe iṣẹ sinima loun fẹ ṣe jẹun, wọn ko tẹwọ gba a rara.

"Nigba ti mo sọ fun awọn obi mi pe iṣẹ tiata ni mo fẹ ṣe, mama mi kọkọ bu sẹrin pe mi o tii mọ nnkan ti mo fẹ ṣe jẹun."

O ni oun ni lati ṣe ọpọ alaye fun wọn lori idi ti oun fi yan iṣẹ naa laayo ṣugbọn ero wọn ni pe irufẹ awọn eeyan kan lo maa n ṣe iṣẹ ọhun.

Ifẹnukonu ninu sinima

"Nipa ifẹnukoraẹnu ninu sinima, wọn kii kọ ọ sinu iwe itan sinima pe wọn maa fi ẹnukonu ninu ipin kan, iṣẹ atinuda ọwọ awọn oludari ni.

Eyi lọrọ ti Bọlaji Ogunmọla sọ ninu ifọrọwerọ naa nigba ti BBC News Yoruba bii nipa fifi ẹnu ko ẹnu laarin awọn oṣere, eleyi ti ọpọ awọn to n wo sinima maa n kọminu le lori.

O ni fun awọn eeyan lati maa ri eyi nikan sọrọ nipa rẹ, a jẹ wi pe oun 'ko tii ṣe iṣẹ oun bi iṣẹ to niyẹn' nitori pe, gẹgẹbi ọrọ rẹ, apapọ ere sinima naa lo yẹ ki awọn eeyan le maa sọrọ le lori kii ṣe ipa ti o kan ifẹnukonu nikan.