Kókó tó wà nínú lẹ́tà tí Davido fi ránṣẹ́ sí Donald Trump lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ l'Osun ṣáájú ìbò Gómìnà tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, EPA/Shutterstock/Davido/X
Gbajugbaja akọrin takasufee n ni, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido, ti kọ lẹta si Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika lori nnkan to n ṣẹlẹ ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Osun ti yoo waye lọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii.
Davido ṣalaye ninu ọrọ to fi ranṣẹ si Trump loju opo X rẹ pe ''ibẹru-bojo ti gbalẹ bayii, o si ṣee ṣe ki rogbodiyan bẹ silẹ lasiko ibo gomina ọjọ Satide to n bọ.
O ṣee ṣe ki idunkoko-mọni tun ṣẹlẹ lasiko idibo gomina ipinlẹ Osun.
Eleyii to tun da bii rẹ ni pe awọn kan tun le da eto idibo naa ru.''
Davido ni awọn eeyan ipinlẹ Osun ni ẹtọ lati dibo fun ẹnikẹni to ba wu wọn ni alaafia lai si ibẹru rara.
Akọrin takasufee naa wa kepe Trump atawọn lajọ-lajọ lagbaaye lati foju si eto idibo gomina opin ọsẹ yii nipinlẹ Osun.
O tun rọ Aarẹ Trump lati sọ fun gbogbo awọn tọrọ kan lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ ki awọn araalu si dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Davido ni ''a o fẹ itajẹsilẹ, a o fẹ idunkoko-moni, alaafia ni a fẹ.
Bakan naa ni a tun fẹ ki eto idibo gomina ipinlẹ Osun lọ ni irọwọ rọsẹ.''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























