Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ wọ́gilé ìpàdé àpérò tí igun kan lẹ́gbẹ́ PDP ṣe ní Ibadan, yọ Tanimu Turaki nípò alága

Oríṣun àwòrán, @KABIRUTURAKISAN
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti wọgile apero apapọ ti igun kan ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ṣe ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo ni ọjọ Kẹẹdogun ati Kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.
Nibi idajọ ile ẹjọ naa gbe kalẹ lọjọbọ, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ni awọn adajọ mẹta ninu awọn adajọ marun-un to gbọ ẹjọ naa fẹnuko pe ẹjọ Kotẹmilọrun ti igun tanimu Turaki pe ko lẹsẹ nilẹ.
Adajọ Stephen Adah to ka idajọ naa sita sọ pe awọn to ṣe ẹjọ naa ti lodi si idajọ ile ẹjọ giga eyi to ni wọn ko gbọdọ tẹsiwaju pelu apero naa ṣugbọn wọn kọ eti ikun si aṣẹ ile ẹjọ.
Ile ẹjọ to ga julọ naa ti wa fidi rẹ mulẹ pe ṣiṣe apero naa lodi si idajọ ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun tig be kalẹ.
Ẹ o ranti pe ṣaaju ki apero naa to waye ni oniruuru ifanfa to fi mọ igbejọ ile ẹjọ ti n waye lori rẹ ti ile ẹjọ giga ijọba apapọ kan ti ni wọn ko gbọdọ tẹsiwaju lori rẹ nitori wọn ko tẹlẹ ofin ẹgbẹ ati pe wọn ko tẹle ilana to yẹ.
Ile ẹjọ naa tun sọrọ lori awọn awuyewuye to waye nibi awọn ipade apero to waye lawọn ipinlẹ kọọkan ṣaaju ki apero apapọ naa to waye.
Pẹlu idajọ ile ẹjọ to ga julọ yii lori apero apapọ ẹgbẹ naa, o ti foju han pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ ti wọn dibo yan nibi apero ẹgbẹ PDP ti igun Minisita fọrọ ilu Abuja, Nyesom Wike ṣe ni ojulowo awọn alaṣẹ ẹgbẹ bayii.
Idajọ yii ni igbagbọ wa pe o maa ṣe atunto ẹgbẹ naa bi wọn ṣe n gbaradi fun eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Níbo ni igi ọ̀rọ̀ yóò wó sí bí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yóò ṣe dájọ́ ìjà àgbà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ADC àti PDP?

Oríṣun àwòrán, Supreme Court
Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe oni Ọjọbọ, ọgbọnjọ oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni idajọ yoo waye nile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, lori ẹjọ ija agba to n waye ninu ẹgbẹ African Democratic Congress (ADC) ati ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ti wọn jẹ ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi lorilẹede yii.
Tẹ o ba gbagbe, o ti ṣe diẹ ti rogbodiyan lori ta ni yoo ṣaaju awọn ẹgbẹ yii ti n waye, ti ile ẹjọ si ti sun idajọ siwaju fun awọn asiko kan.
Lonii ni Adajọ Mohammed Lawal Garba yoo lewaju ikọ adajọ ẹlẹni marun-un ti yoo gbe idajọ naa kalẹ, lẹyin ti won ti gbọ awijare igun mejeeji lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin odun 2026.
Ẹhonu ADC
Igun to n tẹlẹ David Mark ninu ADC lo gbe ẹjọ lọ sile ẹjọ to ga julọ.
Wọn ni awọn ko faramọ idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun to paṣẹ iyọkuro orukọ David Mark nipo olori.
Ẹ o ranti pe lori ọrọ yii ni INEC ti i ṣe ajọ eleto idibo ilẹ wa fi yọ orukọ Mark to jẹ olori ADC ati ati Aregbesola to wa nipo Akọwe ẹgbẹ naa lapapọ kuro.
Amọ awọn ti idajọ Kotẹmilọrun naa kan sọ pe awọn ko gba, ni wọn fi mori le ile ẹjọ to ga julọ.
David Mark sọ pe ọrọ abẹle inu ADC ni rogbodiyan nipa ẹni ti yoo di ipo olori mu.
O ni bi ofin Naijiria ṣe sọ, ki i ṣe kootu ni yoo da a.
Dugbẹdugbẹ ọrọ naa ti wa ni kootu to ga ju, o ṣee ṣe ko ja lonii Ọjọbọ!
PDP ati rogbodiyan tiẹ
Ni ti PDP, igun Kabiru Turaki to jẹ alaga fun awọn kan ninu ẹgbẹ naa ni wọn yan an sipo lasiko ipade apapọ ẹgbẹ wọn loṣu Kọkanla ọdun to kọja.
Ṣugbọn ile ẹjọ giga ati ile ẹjọ Kotẹmilọrun paṣẹ pe ipade apapọ ti wọn ti yan Turaki ko lẹṣẹ nilẹ, tabi ba ofin mu. Wọn ko gba a wọle.
Igun Minisita fun ilu Abuja, Nyesom Wike, ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun gba wọle bii ojulowo olori ati adari ẹgbẹ PDP.
Araalu n reti abajade idajọ kootu
Ọpọ eeyan lorilẹede Naijiria lo n foju sọna lati gbọ ibi ti ẹjọ awọn ẹgbẹ mejeeji yii yoo fi si lonii Ọjọbọ, paaaa julọ, ti ADC to ti di olori ẹgbẹ alatako gboogi bayii.
ADC n lewaju latari bi awọn oloṣelu nla ṣe n parapọ lati fa ẹnikan kalẹ ti yoo gba agbara lọwọ APC lẹka ipo aarẹ.
Awọn oloṣelu to gbajumọ bii Atiku Abubakar, Peter Obi, Rabiu Musa Kwankwaso, Rotimi Amaechi, Nasir El-Rufai, Rauf Aregbesola, Liyel Imoke, Aminu Tambuwal ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti di ọmọ ẹgbẹ ADC bayiii.
Pataki idajọ ile ẹjọ to ga julọ si idibo 2027
Gẹgẹ bi awọn amoye to n wo bi nnkan ṣe n lọ lagbo oṣelu Naijiria ṣe n sọ, ipa kekere kọ ni idajọ to ba ti kootu to ga julọ wa lonii yii yoo ni lara idibo apapọ ti yoo waye loṣu Kin-in-ni ọdun 2027.
Ki kootu too dajọ rara ni igun ti David Mark n dari ninu ADC ti kọwe si Adajọ agba ilẹ Naijiria.
Wọn fi han pe idaamu ọkan wa fawọn lori igbesẹ ti ajọ eleto idibo le gbe.
Wọn ni ko maa lọ jẹ pe wọn yoo yọ orukọ ADC kuro ninu iwe idibo bi idajọ yii ba pẹ ju ko too jade.
Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni ile ẹjọ giga apapọ to wa l'Abuja naa gbe ikede jade l'Ọjọru, pe INEC ko gbọdọ kopa tabi gba ipade apapọ ti awọn alabojuto ẹgbẹ ADC kankan ba patẹ rẹ wọle.
Bakan naa ni kootu tun paṣẹ fun awọn apaṣẹ ẹgbẹ naa lapapọ lati ma ṣe da si iṣakoso awọn to ti wa nipo adari lawọn ipinle kiri.
Ile ẹjọ sọ pe awọn alaṣẹ ipinlẹ kọọkan lo letọọ lati ṣeto ipade to ba yẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Adajọ Joyce Abdulmalik lo gbe idajọ naa kalẹ, lẹyin ti awọn alaṣẹ ADC ipinlẹ gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ pe ki wọn ba awọn wo ohun ti awọn afunnṣọ ẹgbẹ n ṣe.
Ṣaa, bi kootu ba da awọn ẹjọ naa loni tabi bẹẹ kọ, BBC News Yoruba yoo mu bo ba ṣe lọ wa fu yin.


























