Bíjọba Tinubu kò ṣe rẹ́yìn ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ tó ń pa Krísítẹ́ní, a ti gé ìrànwọ́ wa sí Naijiria dé ìdajì - Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Tinubu
Ile igbimọ aṣofin ilẹ Amẹrika ti n ṣiṣẹ lori abadofin kan ti yoo dẹwọ iranwọ ijọba ilẹ naa fun ijọba Naijiria to jẹ ijiya fun bi awọn agbebọn ṣe n gbẹmi awọn ọmọlẹyin Kristi.
Aṣofin kan ninu ẹgbẹ oṣelu Republican, Riley Moore ti kan sara si abadofin naa loju opo X rẹ.
More sọ pe lootọ ni awọn agbebọn n ṣekupa awọn Kristẹni ni Najiria ti ijọba Naijiria ko si ṣe nnkankan nipa rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Moore ni ijọba Tinubu ti kuna lati ṣe awọn nnkan to yẹ ko ṣe gẹgẹ bii alakalẹ ti ijọba ilẹ Amẹrika la kalẹ lati tẹsiwaju iranwọn rẹ fun Naijiria.
Ofin tuntun yii, ti BBC ti ri ke si ijọba Amẹrika gbẹsẹle ida 50% owo iranwọ to yẹ ko fi ranṣẹ si ijọba Naijiria.
Ṣaaju ni Amẹrika ti sọ fun ijọba Naijiria pe ko wa ojutu si eto aabo to mẹhẹ, paapaa bi awọn alakatakiti ẹsin ṣe n ṣekupa awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria.
Ijọba Amẹrika n reti ki ijọba Naijiria gbe igbesẹ lati fopin si iṣekupani naa ati lati fi oju gbogbo awọn to wa nidi awọn ikọlu ọhun lede ki wọn si jiya to tọ labẹ ofin.
Wọn n reti ki Naijiria tun pese ilegbe tuntun ati eto abọ lọtun fun awọn ti ogun ẹsin naa sọ di alainilelori.
Moore fi kun pe "Ijọba Amẹrika ko ni la oju rẹ silẹ ki wọn maa gbogun ti awọn eeyan ninu Kristi."
Moore wa lara awọn to maa n funrere ọrọ Aarẹ Donald Trumo pe lootọ lawọn alakakiti ẹsin n ṣekupa awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria.
Amọ ṣa, ni gbogbo igba ti ọrọ naa ba n jẹyọ ni ijọba Naijiria maa n sọ pe ko si ohun to jọ iṣekupani awọn Kristẹni ni Naijiria.
Wọn ni kii ṣe awọn ọmọlẹyin Kristi nikan ni awọn agbebọn n kọju ija si Naijiria nitori bi wọn ṣe n pa Kristẹni naa ni wọn n pa awọn Musulumi.
Ninu oṣu Kejila ọdun kọja, ijọba Amẹrika fi ado oloro ranṣẹ si Naijiria lati pa awọn agbesunmọ ni Sokoto.
Ijọba Naijiria sọ pe ijọba Amẹrika ko da ikọlu naa ṣe laaye ara rẹ, ati pe ajọṣepọ awọn mejeji ni.




























