Ṣé lóòótọ́ ni Gómìnà Adeleke kò lágbára láti dá iṣẹ́ ẹgbẹ́ NURTW dúró l'Osun gẹ́gẹ́ bí MC Oluomo ṣe sọ? Ohun tí òfin sọ rèé

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X/NURTW/Facebook
Agbẹjọro agba to ti fi ilu Eko ṣe ibugbe, Ọmọwe Monday Ubani, (SAN), ti sọ pe Gomina Ademola Adeleke lagbara lati da iṣẹ ẹgbẹ awakọ NURTW nipinlẹ Osun duro ti nnkan ti wọn ba n ṣe ba ti n ṣakoba fun eto aabo ilu.
Ọmọwe Ubani ṣalaye lori foonu fun BBC Yoruba wi pe Gomina ipinlẹ Osun ni aṣẹ lati sọ pe ki ẹgbẹ awakọ da iṣẹ wọn duro gẹgẹ bi olori awọn ẹṣọ eleto aabo ipinlẹ naa niwọn igba ti iṣẹ ẹgbẹ NURTW ba ti n pa eto aabo ati alaafia ilu lara.
L'Ọjọbọ ọsẹ ti kọja ni Gomina Adeleke paṣẹ pe ki gbogbo ẹgbẹ awakọ ati gbogbo awọn to ni i ṣe pẹlu tikẹẹti jija nipinlẹ Osun lọ rọkun nile.
Gomina Adeleke sọ pe ẹgbẹ kankan to ni i ṣe pẹlu jija tikẹẹti f'awọn onimọto, ọlọkada ati awọn miran kaakiri gbogbo garaaji to wa nipinlẹ Osun ni ki wọn da iṣẹ duro.
Gomina Adeleke gbe aṣẹ naa kalẹ, lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn olori eleto aabo nipinlẹ naa lọsẹ to kọja.
Gomina Adeleke ko laṣẹ lati da iṣẹ ẹgbẹ awakọ NURTW duro – MC Oluomo
Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ NURTW ni Naijiria, Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti sọ pe gomina ipinlẹ Osun ko laṣẹ labẹ ofin lati da iṣẹ ẹgbẹ awakọ duro ni ipinlẹ naa.
Nigba to n sọrọ le aṣẹ ti Gomina Adeleke pa l'Ọjọbọ to kọja nipa idaduro iṣẹ ẹgbẹ awakọ l'Osun, Akinsanya sọ pe ko si ẹni to lagbara lati da iṣẹ ẹgbẹ NURTW duro labẹ bo ṣe wu ko ri.
MC Oluomo ti igbakeji rẹ, Aliyu Ore, ṣoju fun sọ pe ṣalaye pe ofin lo wa nidii idasilẹ ẹgbẹ NURTW, ati pe ẹgbẹ naa ti bori awọn ijọba ipinlẹ to ti gbe wọn lọ sile ẹjọ lori iru ọrọ bayii ṣaaju akoko yii.
''A gbọ wi pe gomina ipinlẹ Osun ti paṣẹ idaduro ẹgbẹ wa nipinlẹ Osun, amọ, ijọba ko lagbara lati ṣe eleyii.
Ko si gomina to lagbara lati da iṣẹ ẹgbẹ wa duro tori a o si labẹ ipinlẹ kankan.
Ofin lo wa ni idi idasilẹ ẹgbẹ NURTW,'' Akinsanya lo sọ bẹẹ.
''Gomina lagbara lati da iṣẹ ẹgbẹ awakọ NURTW, amọ…''
Agbẹjọro agba Monday Ubani (SAN) ti sọ pe gomina ipinlẹ Osun lagbara labẹ abala karun un iwe ofin Naijiria lati da iṣẹ ẹgbẹ awakọ NURTW duro ti nnkan ti wọn ba n ṣe ba ti n ṣakoba fun alaafia ilu.
''O tun wa ninu ofin ipinlẹ wi pe gomina gbọdọ gbe igbesẹ lori ẹnikẹni tabi nnkan to ba le ṣakoba fun eto aabo ipinlẹ rẹ.
Gomina ni olori awọn ẹṣọ eleto aabo ni ipinlẹ, ko si gbọdọ duro ni nnkan bajẹ tan ki o to gbe igbesẹ.
Ti gbogbo nnkan ba daru tan, gomina ni gbogbo eeyan maa bu, idi niyii ti o fi gbọdọ gbe igbesẹ to yẹ.
Ile ẹjọ yoo gba iru igbesẹ bẹẹ wọle papaa julọ to ba ti jẹ pe o wa fun idaabo bo awọn araalu ati dukia wọn,'' Ọmọwe Ubani lo sọ bẹẹ.
Agbẹjọro Ubani ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe gomina ko laṣẹ lati dasi ọro bi wọn ṣe n ṣe ẹgbẹ wọn.
O ni ko si nnkan to kan gomina nipa ẹni ti ẹgbẹ awakọ NURTW fẹ yan gẹgẹ bi olori tabi alaga wọn.
Ọmọwe Ubani sọ pe nigba ti nnkan ti ẹgbẹ naa n ṣe ba bẹrẹ si ni ṣakoba fun alaafia ati eto aabo ilu ni gomina le gbe igbesẹ lori wọn.
Agbẹjọro Ubani fikun ọrọ rẹ pe nnkan to ba wu ẹgbẹ awakọ ni wọn le ṣe ninu ẹgbẹ wọn, niwọn igba ti ko ba ti ṣakoba fun alaafia ilu tabi eto aabo ipinlẹ.
"Agbekalẹ ofin yii lo wa lati da alaafia pada si gbogbo awọn garaaji ọkọ ati fifi opin si jija tikẹẹti"
Ṣaaju ninu atẹjade ti kọmiṣanna ipinlẹ Osun feto iroyin ati ilanilọyẹ araalu, Kolapo Alimi fi ssita lẹyin ipade ọhun, gomina paṣẹ fun awọn eleto aabo lati fi kele ofin gbe ẹnikẹni to ba tapa si aṣẹ to ni ki gbogbo ẹgbẹ awakọ ati gbogbo awọn to nii ṣe pẹlu tikẹẹti jija lọ rọkunnile.
Gomina tun sọ pe kawọn agbofinro gbe ẹnikẹni to pe ara rẹ ni olori tabi ọmọ ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Osun.
O ni agbekalẹ yii ni lati da alaafia pada si gbogbo awọn garaaji ọkọ ati fifi poin si jija tikẹẹti.
"Gomina ti paṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ileeṣẹ eleto aabo to ku lati fi opin si gbogbo iṣẹ ẹgbẹ awakọ NURTW kaakiri awọn garaaji to wa nipinlẹ yii. Aṣẹ yii ni lati fi opin si gbogbo gbigba oniruuru owo lawọn garaaji," atẹjade naa sọ bẹẹ.
"Mo n fi asiko yii pa a laṣẹ fun awọn ọlọpaa ati awọn ileeṣẹ eleto aabo ni aṣẹ dawọ gbogbo iṣẹ ẹgbẹ awọn awakọ duro kaakiri garaaji. Nko sọ pe ki ẹ tilẹkun awọn agraaji pa o, ṣugbọn ẹ ko gbọdọ gba ẹnikẹni laaye lati ṣiṣẹ lorukọ ẹgbẹ awakọ.
"Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o tapa si aṣẹ yii ni ki wọn fọwọ ṣikun ofin gbe lori ẹsun dida alaafia ilu laamu," gomina sọ bẹẹ.



























