You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aṣọ kan ló kù lọ́rùn àwọn òbí mi nítorí ẹ̀kọ́ mi, ètò ẹ̀yáwókàwé NELFUND ló kó mi yọ láti kẹ́kọ̀ọ́ jáde – Oladepo Gbenga akẹ́kọ̀ọ́ tó mókè jùlọ ní fásitì LAUTECH
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ilu Ifẹ Ọdan ni ipinlẹ Ọṣun ni Ọladapọ Caleb Olugbenga ti jade, oun si ni akẹkọọ to pegede julọ ni fasiti imọ ẹrọ LAUTECH ti ṣẹ fa.
Gẹgẹbi o ṣe sọ, o ni ẹbi oun ko ni ina, omi, koda wọn ko ni mohunmaworan pẹlu. O ni abẹla ati atupa loun atawọn ẹbi oun fi n kawe.
O fi kun un pe gbogbo ohun ini awọn obi oun ni wọn gbe ta tan lati ran ẹgbọ̀n oun, oun ati aburo oun lọ si ileẹkọ.
Gbenga wa dupẹ lọwọ ijọba fun anfani eto ẹyawokawe NELFUND ti wọn gbe kalẹ eyi to ni o fun oun ni anfani lati pari ẹkọ fasiti oun.