Wo ipa tí mímú àlékún bá iye owó lílẹ pátákó ìpolongo ìbò máa ní lórí ètò ìdìbò 2027

Atẹ ipolongo ibo Tinubu ati Shettima ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun 2023

Oríṣun àwòrán, AFP

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n mojuto eto lilẹ atẹ ipolowo ati ipolongo ni ipinlẹ Kwara iyẹn Kwara State Signage and Advertisement Agency (KWASAA) ti mu alekun ba iye ti wọn n gba fun lilẹ atẹ ipolongo ibo fawọn oludije sipo oṣelu ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.

Nibi eto kan ti wọn ti pe awọn alẹnulọrọ ni ọga agba ajọ KWASAA, Toba Adeyeye kede pe alekun ti ba owo naa, ti owo naa si ti wa laaarin miliọnu meji naira ati ọgọrun-un miliọnu naira.

Adeyeye nigba to n sọrọ nibi eto naa ṣalaye pe awọn oludije sipo aarẹ maa san ọgọrun-un miliọnu naira, nigba ti awọn oludije sipo gomina maa san aadọta miliọnu naira.

Awọn oludije sipo sẹnetọ maa san ọgbọn miliọnu naira, awọn oludije sile igbimọ aṣojuṣofin maa san miliọnu mẹwaa naira, ti awọn oludije sile aṣofin ipinlẹ maa san miliọnu meji naira ti wọn ba fẹ lẹ atẹ ipolongo ibo wọn ni ipinlẹ Kwara.

O fi kun pe owo naa maa gba awọn oludije naa laaye lati lẹ posita ipolongo ibo wọn, ṣe ipolongo ni ita gbangba, lo awọn ọkọ ti wọn tẹ awọn orukọ oludije si, gbe bana sita ni gbogbo awọn aaye ti ijọba ba ti faaye gba wọn.

O sọ pe ti ko ba si amojuto to peye fawọn ẹgbẹ oṣelu lori bi w.ọn ṣe n ṣe ipolongo, o ṣeeṣe ko ni ipa lori aabo awọn araalu.

O woye pe gbogbo awọn araalu lo ni ẹtọ lati le polongo ibo, ki wọn si ṣafihan ipolongo wọn fun araye amọ ọna ti ọpọ maa n gba lati ṣe bẹẹ lo maa n jẹ ikọnilominu, idi niyi ti awọn ṣe ni lati mojuto, to si fa idi ti wọn pe ipade awọn alenulọrọ.

Adeyeye ni ajọ naa ko ni jẹ lilo lati ọwọ oloṣelu kankan tabi ẹgbe oṣelu kankan lẹnu iṣẹ wọn, ti wọn si rọ gbogbo ẹgbe oṣelu lati kan si wọn fun iṣẹ wọn, to si jẹ pe gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu ni wọn ni anfaani lati kan si awọn.

PDP, APC bu ẹnu atẹ KWASAA, ni igbesẹ naa ko ba ofin mu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣugbọn awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ajọ naa pe niṣe ni ijọba n lo wọn lati tẹ awọn ẹgbẹ alatako ri pẹlu owo gegege ti wọn gbe jade fawọn oludije lati san fun lilẹ atẹ ipolongo lasan.

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ati ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC sọ pe awọn ko gba iye owo tuntun ti ajọ naa gbe jade, ti wọn si ni wọn ko fẹ kawọn ẹgbe oṣelu alatako kopa ninu eto idibo 2027.

Atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Kwara, Olusegun Adewara fi sita sọ pe awọn oludije awọn ko nis an owo kankan ti ko ba ofin tabi ti iwe ẹri wa lati fi gbe e lẹsẹ.

O fi kun pe awọn gba ojuṣe KWASAA gẹgẹ bi ajọ to n mojuto atẹ ipolongo ibo to fi mọ ojuṣe ṣiṣe amojuto awọn ohun elo ipolongo ni ita gbangba.

Bakan naa ni ẹgbe oṣelu ADC, ninu atẹjade ti agbẹnusọ wọn ni ipinlẹ Kwara, Kabir Basambo fi lede sọ pe gbigbe aduru bayii sita fun lilẹ atẹ ipolongo dabi gbigba owo ori lori eto ijọba awaarawa ni.

Basambo ni owo naa ko ba ofin mu ati pe ajọ KWASAA ko i tii sọ idi kan pato ti wọn fi gbe alekun to pọ bẹẹ jade.

O fi kun pe igbesẹ yii lo ṣokunfa ko jẹ pe awọn oludije to lowo tabua nikan ni wọn maa ni anfaani lati le ṣe ipolongo bi wọn ṣe fẹ leyii to lodi si ofin.

Ki nipa ti alekun owo yii maa ni lori eto idibo 2027?

Ẹwẹ nigba ti BBC News Yoruba kan si onimọ nipa ero awujọ, Nicholas Uwerunonye ni kii ṣe ipinlẹ Kwara nikan ni alekun bayii ti waye bi awọn ipinlẹ mii bii Ekiti, Oyo, Ogun, Abia ati olu ilu Naijiria ti mu alekun ba owo ipolongo wọn.

Uwerunonye woye pe awọn ajọ yii, labẹ ofin ni anfaani lati mu alekun ba iye owo lati lẹ atẹ ipolongo ibo ni tootọ lati le mojuto bi awọn eeyan ṣe kan maa n gbe atẹ ipolowo ati ipolongo wọn sita.

O ni sibẹ, gẹgẹ bi ofin ti ajọ to n mojuto eto idibo ni Naijiria, INEC gbe kalẹ lati fi aaye gba gbogbo awọn oludije lati ṣeto ipolongo wọn pẹlu asiko ati aaye kan naa lai si idiwọ fun, o maa ṣoro fun awọn ẹgbẹ alatako lati ko owo tabua bayii sita fun awọn ajọ KWASAA.

O sọ pe labẹ ijọba awaarawa ti Naijiria n lo, o ni kii ṣe ohun to bojumu fun ijọba lati maa lo awọn ajọ rẹ lati fi maa ni awọn ẹgbẹ alatako lara.

O tẹsiwaju pe gbigbe owo gegege bayii kalẹ fawọn oludije n mu alekun ba owo ti awọn oludije n na lori eto idibo to si le mu kawọn oludije naa ṣi iwa wu nigba ti wọn ba depo nipasẹ ọgbọn lati fi kọkọ ri owo ti wọn n lori ipolongo ibo.

Onimọ naa tun sọ pe ti a ba ṣe agbeyẹwo ofin ti INEC gbe kalẹ pe o ni gbedeke iye ti oludije kọọkan le na lori eto idibo ti iye ti wọn ba na sori ipolongo ibo le mu wọn lugbadi ofin.

Bakan naa lo rọ awọn ajọ ijọba lati maa fi awọn oludije lẹgbẹ alatako si erongba ki wọn to maa gbe ofin jade lojuna ati le faaye gba awọn oludije mii lati le kopa ninu ipolongo ibo bo ṣe yẹ.

Uwerunonye wa rọ ajọ INEC lati maa fun awọn ajọ bayii ni gbedeke iye ti wọn le maa gba lọwọ oludije kọọkan ki wọn ba a le ri ṣaridaju rẹ pe awọn oludije naa ko ṣẹ sofin.