Agbébọn pa olùkọ́, jí ọ̀gá àgbà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ l'Ogbomoso

Awon agbebọn to gbe ibọn dani, bo oju wọn duro siwaju ọkọ ninu igbo, ẹnikan wa ninu ọkọ naa ninu wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko ti i le fi iye wọn mulẹ lọ nibi ikọlu naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti naa, o ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ yii ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ.

Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de bo ṣe wi.

Bi wọn ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.

Ninu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn fun olukọ kan, ẹni ti iroyin sọ pe o ti jade laye, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.

"Awọn agbebọn ti wọ agbegbe Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo. Wọn gbe ọga ile ẹkọ ati awọn akẹkọọ ti a ko mọ iye won lọ"

"Ẹni to fi to wa leti sọ pe wọn yinbọn mọ olukọ kan lasiko ikọlu naa."

Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.

Ajọ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Oyo paṣẹ titi awọn ile ekọ pa lawọn ijọba ibilẹ kan, fi idi iku olukọ mulẹ

Latari iṣẹlẹ yii, Ajọ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Oyo, 'Oyo State Universal Basic Education Board (OYOSUBEB), ti paṣẹ pe ki awọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ to wa lagbegbe naa ati ayika rẹ wa ni titipa.

Alaga ajọ naa, Ọmọwe Nureni Aderemi Adeniran, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Awọn ijoba ibilẹ bii Surulere, Ila-Oorun Oyo, Oriire ati Olorunsogo ni ile ẹkọ titipa naa kan.

Ajọ OYOSUBEB ṣalaye bi iṣẹlẹ yii ṣe ba wọn lọkan jẹ to, wọn ba awon ẹbi ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun.

Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe wi, wọn ko le sọ pato iye akẹkọọ ti awọn agbebọn gbe lọ.

OYOSUBEB sọ pe awọn ẹṣọ alaabo ti bẹrẹ si I wa awọn ti won gbe lọ naa kiri awọn igbo to wa lagbegbe yii.

Awọn alaṣẹ n ṣiṣẹ tọ ipadabọ awọn ti wọn ji gbe

Ọmọwe Adeniran fi idaniloju rẹ han, pe ijọba atawọn agbofinro yoo ṣiṣẹ tọ ipadabọ awon ti won ji gbe naa.

O fi kun un pe wọn ti gbe ikọ ọtelẹmuyẹ kan dide lati ri si eyi, labẹ idari Kọmiṣanna ọlọpaa.

Bakan naa ni awọn alaṣẹ pe fun alaafia laaarin awon eeyan agbegbe naa, wọn rọ wọn lati ma ṣe gbe iroyin ohun ti ko ṣẹlẹ jade, eyi to le mu aibalẹ ọkan wa lagbegeb naa.

OYOSUBEB daro olukọ to ba iṣẹlẹ naa lọ, wọn fidi iku rẹ mulẹ.

Bakan naa ni wọn ṣapejuwe rẹ bii olukọ to jara mọṣẹ, ti ipinlẹ Oyo ko si ni I gbagbe rẹ.