Ọba Adeyemi Adediran, Owamiran ti ìlú Esa-oke wàjà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

‎Gomina Ademola Adeleke ti ba awọn ẹbi, iluu Esa-oke ati gbogbo ọmọ Ijeṣa lapapọ kẹdun ipapoda Ọba Adeyemi Adediran to waja.

‎Ninu atẹjade ti Rasheed Olawale, ẹni to jẹ agbẹnusọ fun gomina Ademola Adeleke lede lo ti fidi rẹ mulẹ pe Ọba Adeyemi Adediran, Owamiran ti iluu Esa-oke ti waja.

‎Ana ni a gbọ pe, igbakeji si ọba Adeyemi Adediran ti iluu Esa-oke, Ogboni ti iluu Esa-oke, Oloye Paul Olamiju kede konilekogbele fun wakati mẹrinlelogun lati fi ṣe awọn etutu pataki fun Ọba Adeyemi Adediran to wa ni ori aarẹ.

‎Ṣugbọn ikede konilekogbele naa lo mu ipaya ba awọn olugbe iluu Esa-oke latari bi wọn ṣe mọ pe, Ọba Adeyemi n ṣe aarẹ bii ọsẹ diẹ sẹyin.

‎Ninu atẹjade ti Rasheed Olawale fi lede lo ti sọ bi ipapoda Ọba Adeyemi ṣe dun gomina Ademola Adeleke to.

‎Oni, gomina Ademola Adeleke ṣe apejuwe Ọba Adeyemi gẹgẹ bii ẹni to fẹran iluu rẹ ati ẹni to ko eeyan mọra to si jẹ ẹni to tun fẹran alaafia gidigidi.

‎Gomina Adeleke, tun tẹsiwaju pe oun ba ẹbi, ara, ati gbogbo ọmọ bibi iluu Esa-oke ati paapaa julọ gbogbo ọmọ Ijeṣa kẹdun ipapoda Ọba naa.

Gomina Ademola Adeleke ki wọn pe ku ara fẹẹ ra ku ti ọba ọhun.

‎Gẹgẹ bi oun ti o wa ni akọsilẹ. Ọba Adeyemi Adediran, gori itẹ awọn baba-nla rẹ ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ọdun 2004, to si papoda ni ọjọ kẹfa, osu Karùn-ún, ọdun 2026.

Ọba Adeyemi Adediran lo ọdun mejilelogun lori itẹ ki ọlọjọ to de.