''Ọlọ́pàá lu kóndó mọ́ ọlọ́kadà lórí'' ní Iseyin; ọlọ́kadà kú, aráàlú fẹ̀hónúhàn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Rogbodiyan bẹ silẹ niluu Iseyin laarọ ọjọ Abamẹta lẹyin ti ọlọpaa kan la kondo ọwọ rẹ mọ ọkunrin kan lori ti ọkunrin naa si jade laye.

A gbọ pe agbegbe ibi ti awọn ọlọpaa ti maa n yẹ awọn alupupu ati ọkọ wo loju ọna ilu Iseyin siluu Oyo ni iṣelẹ naa ti waye.

Iroyin ni iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin ti ọkan lara awọn ọlọpaa ọhun gbiyanju lati da oloogbe naa duro lori alupupu rẹ amọ to kọ jalẹ.

Inu bi ọlọpaa latari bi ọkunrin naa ṣe gbena woju rẹ, o si la kondo ọwọ rẹ mọ ọn lori.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn akọroyin pe "Hausa ni ọkunrin to n wa ọkada yẹn, ṣugbọn nitori ko fun wọn lowo ti wọn maa n gba nibẹ, ọkan ninu wọn la kondo mọ ọn lori, o si ku lẹsẹkẹsẹ."

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ogunlọgọ awọn ọlọkada ti wọn jẹ Hausa atawọn araalu mii ya bo agbegbe ọhun, ti wọn si ko igi di ọna to lọ si agọ ọlọpaa Okutapemo ni ifẹhonuhan.

Ijamba lo gbẹmi ọlọkada naa amọ a ti mu awọn ọlọpaa ti ọrọ kan, iwadii ti bẹrẹ – Ileeṣẹ ọlọpaa

Ayanlade Olayinka to n gbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti fidi ilṣẹlẹ naa mulẹ.

Ayanlade sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ kulẹ kulẹ ohun to ṣẹlẹ ni pato.

O kọkọ sọ pe itakurọsọ waye laarin oloogbe naa atawọn ọlọpaa ti oloogbe si kọ lati ju ọwọ silẹ fun awọn ọlọpaa.

Asiko ti eyii n lọ lọwọ ni ọlọpaa lu ọkunrin naa to si ṣubu lati ori alupupu rẹ.

Lẹyin wakati diẹ to sọ eyii fun awọn akọroyin ni Ayanlade tun pada kọ atẹjade mii nibi to si sọ pe ijamba lo gbẹmi ọkunrin ọhun, kii ṣe pe ọlọpaa lo lu u ni kondo.

Ayanlade ṣalaye pe nnkan bii aago marun un abọ afẹmọju ni Umar Yahúza, to jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn ni ijamba lori alupupu rẹ lẹbaa ibi ti awọn ọlọpaa ti n yẹ ọkọ wo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Kete lẹyin naa ni wọn gbe e lọ sile iwosan Fadok fun itọju.

"Amọ o ṣeni laanu pe ni nnkan bii aago meje abọ aarọ ni a gbọ pe o ti fi aye silẹ lẹyin bo ṣe farapa latari ijamba ọhun.

"Lẹyin eyii ni awọn ọlọkada kan lọ ṣe ifẹhonuhan niwaju ile iwosan Fadok ti wọn si fẹsun kan awọn ọlọpaa to wa nibi ti wọn ti n yẹ ọkọ wo pe awọn lo jẹ ki oloogbe ni ijamba ọhun."

Ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan ti wa ni ahamọ bayiii fun iwadii, wọn si ti jọwọ oku oloogbe naa fun awọn mọlẹbi rẹ lati sin ni ilana ẹsin Musulumi.