Wo ọ̀nà márùn-ún tí o lé gbà dènà ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀ (Lassa Fever) tó ti ṣekúpa èèyàn 259 báyìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria ti sọ pe iba ọrẹrẹ ti ọpọ mọ si lassa fever ti ṣekupa eeyan 259 lọdun 2026 yii.
NCDC ni eeyan 1,086 lo ti ko arun naa ni ipinlẹ mẹrinlelogun kaakiri orilẹede Naijiria.
Ajọ naa ṣalaye pe eeyan mejila mii lo ṣẹṣẹ lugbadi arun naa bayii ni Naijiria.
NCDC ni awọn ipinlẹ ti akọsilẹ sọ pe awọn eeyan ti ṣẹṣẹ lugbadi arun lassa fever ni ipinlẹ Ondo, Edo ati Kogi.
BBC News Yoruba wa se akojọpọ iroyin nipa arun iba ọrẹrẹ eyi to nii se pẹlu awọn apẹrẹ ti arun naa le mu wa, itọju rẹ ati ipa rẹ lori ilera ẹda.
Ki lo n fa arun Iba Ọ̀rẹ̀rẹ̀?
Iba Lassa jẹ arun kan to maa n waye lati ara kokoro aifojuri ti a mọ si Virus.
Kokoro yii maa n de ara eeyan lati ara ounjẹ tabi nnkan eelo ti ekute to ni kokoro lara naa ba tọ si, tabi to ṣe igbọnsẹ si.
Ajọ eleto ilera agbaye, World Health Organisation (WHO), sọ ọ di mimọ pe iba Lassa pọ ni apa Iwọ Oorun Africa, paapaa ni Naijiria, Liberia, Mali, Togo, Guinea, Ghana, Sierra Leone ati Benin.
Bakan naa, iba Lassa yii tun maa n tàn lati ara ẹnikan si ikeji, nibi ti ko ba ti si idaboobo ati itọju to peye.
Gẹgẹ bi NCDC ṣe wi, arun Lassa n lagbara si i , pẹlu bo ṣe jẹ pe onka awọn to n kọlu n pọ si i.
Nipa iru awọn eeyan ti iba yii saaba maa n kọlu, ajọ naa sọ pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mọkanlelọgbọn (31) si ogoji ọdun (40), takọ-tabo ni wọn ni o si le mu.
Bawo ni o se le mọ pe o ni arun iba ọrẹrẹ?
- Ko maa rẹ eeyan latinu wa
- Ki ọna ọfun maa dun eeyan
- Ki eeyan maa ya igbẹ leralera
- Ki ẹjẹ maa da lati imu, erigi
- Ki ẹjẹ maa wa ninu itọ eeyan tabi loju abẹrẹ
- Ki igba aya maa ro eeyan
- Ki eeyan ni irora lati mi
Ọna marun un lati dèna Lassa Fever
Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan ti ko ni ẹrọ, amọ ti o ni itọju ti ẹni to ba ni aisan naa ba tete lọ si ile iwosan lati fi ara rẹ han.
Ọna ti a le gba dina aisan ti o wa lati ara ẹran igbẹ papa eku inu ile:
Ẹ sọra fun jijẹ eku tabi ẹran igbẹ.
Ẹ ma se sa garri sita gbangba.
Ẹ pa awọn eku to ba wa ni inu ile ati agbegbe yin.
Ẹ pa oko tabi koriko ti o ba wa ni agbeegbe, ki ayika naa le wa ni mimo ni gbogbo igba.
Awọn ohun elo ounjẹ gbọdọ wa ni inu ike ti ẹkutele ko lee de bẹ.
Ẹ sọra lati farakan ẹni ti o ma ni aisan iba ti kosi tete lọ.
Awon dokita tabi osisẹ ile iwosan gbọdọ sọra gidigidi, ki wọn si lo ibọwo tabi iboju ti wọn ba n toju ẹni to n se aisan.



























