Wo àwọn Ààrẹ orílẹ́-èdè mẹ́fà tí wọ́n kò yọjú síbi ìpàdè àjọ àgbáyé UNGA tó n lọ lọ́wọ́ l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ipade awọn olori orileede Kaakiri agbaye n waye, to si n lọwọ lọwọ bayii.
Pupọ awọn aarẹ orileede kọọkan kaakiri agbaye ni wọn wa nibi ipade agbaye naa ti wọn pe ni UNGA, eyi to n waye niluu New York nilẹ Amẹrika.
Ṣugbọn pẹlu bi ipade naa ṣe kan gbogbo agbaye, sibẹ, awọn aarẹ orileede mẹfa ni wọn kọ lati yọju sibẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ran awọn aṣoju, ti yoo gba ẹnu wọn sọrọ.
Àwọn Ààrẹ mẹ́fà wo?
Igba kọkanlelọgọrin ree ti ipade UNGA yoo maa waye, nibi ti awọn olori orileede yoo ti sọrọ nipa awọn idagbasoke, adojukọ, ati awọn nnkan miran to kan gbogbo araalu.
Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ni Aarẹ ilẹ Naijiria lọwọlọwọ, ẹni ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima n ṣoju fun nibi ipade UNGA naa.
Aarẹ Tinubu wa ni isinmi ọlọsẹ mẹta, eyi to bẹrẹ lọgbọn ọjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.
Xi Jinping
Xi Jinping ni Aarẹ to n ṣakoso orileede China ti ko yọju sibi ipade awọn aarẹ agbaye to n lọ lọwọ nilẹ Amẹrika.
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Xi yoo wa nilẹ Amẹrika, sibẹ, ko nii yọju sibi ipade ọhun, ilu Washinton D.C ni yoo ti lọ ba Trump ṣepade.
Lara awọn nnkan to jẹ Xi logun lasiko yii ni ti ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu Aarẹ Donald Trump tilẹ Amẹrika.
Igbakeji aarẹ, Han Zheng ni yoo ṣoju Xi Jinping nilẹ Amẹrika.
Vladimir Putin
Aarẹ orileede Russia ni Vladimir Putin, ẹni to ti wa nibẹ lati ọdun 2012.
Sergey Lavrov to jẹ minisita fọrọ ilẹ okeere ni yoo ṣoju ọga rẹ, Vladimir Putin nibi ipade naa.
Giorgia Meloni
Giorgia Meloni ni aarẹ orileede Italy, toun naa ko yọju sibi ipade awọn olori orileede lagbaye to n lọ lọwọ nilẹ Amẹrika.
Minisita fọrọ ilẹ okeere, Antonio Tajani ni yoo ṣoju aarẹ ilẹ Italy nibi ipade naa.
Claudia Sheinbaum
Aarẹ orileede Mexico ni Claudia Sheinbaum ti yoo minisita fọrọ ilẹ okeere yoo ṣoju rẹ nibi ipade UNGA to n lọ lọwọ.
Friedrich Merz
Bakan naa ni Aarẹ Friedrich Merz ti orileede Germany ko si nibi ipade UNGA to n lọwọ.
Ohun to yatọ ni pe igbimọ ni Aarẹ Friedrich Merz ran lọ lati ṣoju rẹ nibi ipade naa.



























