Wo bí fífi ọmọdé lọ́kọ, ìṣẹ́ àti àìsí àbò tó péye ṣe ń ṣèdíwọ́ fún àti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang/BBC
Bo ṣe n gun jeero ninu odo lo n ka 'ABC' ti wọn kọ ọ nile ẹkọ ko too di pe awọn bandiiti ṣigun le oun atawọn akẹkọọ mi-in ti wọn ko si le lọ sile ẹkọ mọ.
Hadiza, ọmọ obinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun la n sọrọ nipa rẹ. O n ka ohun to n ka naa lati ran ara rẹ leti ohun to padanu nipa ai ri ile ẹkọ lọ mọ.
"Nigba mi-in, mo maa n kọ nnkan si ilẹẹlẹ ki n le fi mọ boya mo ṣi mọ iwe e kọ."
Hadiza lo sọ bẹẹ.
Awọn agbebọn kan lo yabo abule awọn ọmọdebinrin yii ni nnkan bii ọdun meji sẹyin, ti wọn si jẹ ibẹ run.
"Wọn le awọn maaluu wa lọ, wọn si ji ọmọdebinrin kan gbe. Niṣe la sa lọ, ẹsẹ lasan la fi rin lai wọ bata titi ta a fi di ibi ta a wa bayii."
Hadiza lo ṣalaye bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang/BBC
Latigba ikọlu naa lo ti n gbe ni agọ awọn eeyan ti ko nile lori mọ ni Goronyo, ipinlẹ Sokoto, eyi to jẹ kilomita diẹ si ile awọn obi rẹ to ti kuro.
Hadiza lọ sile ẹkọ fun igba diẹ nibi, amọ ko pẹ to fi pade ọdọmọkunrin kan ti wọn jọ n sọrọ ifẹ, bẹẹ lo si ṣe fẹ ọkunrin naa lẹni ọdun mẹtala pere.
Bẹẹ ni ile ẹkọ lilọ si dopin fun un.
"Aṣa wa nibi ni pe ti ọmọbinrin ba ti lọkọ, ile ẹkọ lilọ ti dopin fun un."
Hadiza lo sọ bẹẹ.
Ni bayii, ọdọ awọn ẹbi ọkọ rẹ lo n gbe to si n mojuto ile bii iyawo.
Ofin Naijiria ko faaye gba ki eeyan ṣe igbeyawo bi ko ba ti I pe ẹni ọdun mejidinlogun loootọ, amọ gbogbo igba kọ ni ijọba n ri eyi ro.
BBC ṣeto igbẹkọ Dars Hausa
Bi ọrọ Hadiza ṣe ri yii lo ri fun ọpọ awọn ọmọde lorilẹede Naijiria yii naa lawọn apa ibi kan.
Ọkan ṣoṣo ninu miliọnu mẹẹẹdogun (19 million) ọmọ Naijiria ti ko ri ile ẹkọ lọ ni Hadiza, gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ UNESCO ti wọn ṣe ni 2024 ṣe sọ.
Eyi si jẹ ida kan ninu mẹrin awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn wa leyi to yẹ ki wọn ṣi wa ni yara ikawe bii akẹkọọ.
Lati ṣẹgun eyi lo jẹ ki BBC World Service gbe Dars Hausa, kalẹ.
Eyi ni ilana ẹkọ kan to n fi ede Hausa ti wọn n sọ ni Ariwa Naijiria, orilẹede Niger ati Cameroon to mule tiwa, ati lawọn apa ibo mi-in ni Iwọ-Oorun Afica, kọ wọn.
Ilana ẹkọ yii mu ede oyinbo mọ ọn pẹlu, bẹẹ lo ni iṣiro ninu pẹlu ẹkọ nipa imọ Sayẹnsi, o si wa fawọn akẹkọọ kaakiri Iwọ-Oorun Africa.
Yoo maa lo ẹka ayelujara, amohumaworan agbelewo ati redio.
Redio naa pẹlu nitori ọpọ eeyan lapa Ariwa lo jẹ pe redio ni ọna kan ti wọn n gba mọ ohun to n lọ laye, o si fẹrẹ ma si idile ti ko ni in ni Naijiria, gẹgẹ bi ajọ alaanu Save the Children ṣe fidi ẹ mulẹ.
Ki ni itumọ Dars?

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang/BBC
Dars tumọ si ẹ̀kọ́ ninu ede Pashto ati Dari, ede meji yii ni wọn fi kọkọ gbe ile ẹkọ yii kalẹ ni 2023, fun awọn ọmọ orilẹede Afghanistan ti wọn ko ri ile ẹkọ lọ mọ.
Lẹyin eyi ni abala keji waye pẹlu ede Arabic loṣu Keji ọdun 2025.
Awọn ile ẹkọ ti BBC gbe kalẹ yii ṣe pataki, nitori yato si Hadiza, awọn ọmọ mi-in tun wa tawọn naa n koju iṣoro ai ri ile ẹkọ lọ mọ latari wahala bandiiti, ajingbe ati agbebọn.
Iru ọmọ bẹẹ tun ni Rukayya, ọmọ ọdun mejila toun naa n gbe nibudo awon alainile lori ni Goronyo.
"O maa n dun mi ti mo ba ri awọn ọmọde miran ti wọn n kẹkọọ ti wọn si n lọ sile ẹkọ, ti emi o si le lọ."
Rukayya lo sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bii akọbi, Rukayya yoo lọ soko igi lati ṣẹgi ti yoo ta, yoo si tun tọrọ baara kawọn aburo rẹ le jẹun.
"To ba jẹ pe baba mi wa laye ni, mi o ni I maa tọrọ baara jẹun."
O fi kun un pe awọn eeyan kan maa n fi oun ṣe yẹyẹ, amọ ko sọgbọn mi-in toun le da, bẹẹ ni ko sọna mi-in ju koun ṣẹgi ta, ṣagbe jẹun lọ.
Baba Rukayya ko ku iku aisan, awọn bandiiti lo yinbọn pa a niṣoju ọmọ rẹ ni nnkan bii ọdun kan sẹyin, eyi lo mu awọn ẹbi rẹ sa kuro nile, ti wọn di ero agọ awọn ogunlende.
Dandan ni ẹkọ alakọọbẹrẹ ati ti girama fawọn ọmọde lorilẹede Naijiria, ọfẹ si lo yẹ ko jẹ

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang/BBC
Labẹ akoso bo ṣe yẹ ko ri, dandan ni lilọ sile ẹkọ fawọn ọmọde lorilẹee Naijiria.
Ọdun mẹsan-an lo yẹ ki wọn fi kọ ẹkọ ọhun, ọdun mẹfa nile ẹkọ alakọọbẹrẹ, mẹfa nile ẹkọ girama, ọfẹ si lo yẹ ko jẹ.
Ojuṣẹ ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ lo si yẹ ki inawo ile ẹkọ naa jẹ.
Amọ ọpọ ile ẹkọ ni ko ni tiṣa to, bẹẹ ni awọn ẹbi ti ko lowo lati fi ran awọn ọmọ wọn lọ sile ẹkọ aldaani naa pọ.
Wọn ko lowo lati ra iwe, owo aṣọ ile iwe ati owo ọkọ tawọn ọmọ yoo maa wọ lọ bi ile iwe naa ba jinna sile.
Awọn ti wọn lawọn n lọ sile ẹkọ nilana Almajiri l'Oke-Ọya ko kọ ẹkọ meji nibẹ ju ẹkọ ẹsin Islam lọ.
Ko si ẹkọ nipa ede Gẹẹsi tabi Iṣiro ninu ọrọ wọn, awọn wọnyi gẹgẹbi ajọ UNICEF ṣe to wọn, ko si nile ẹkọ kankan naa ni.

























