'Inú ìbànújẹ́ ni mo fi dàgbà nítorí èmi nìkan ni ọwọ́ mi rí báyìí nínú ẹbí mi'
Akẹkọọjade ni ile ẹkọ Federal College of Animal Health and Production Technology ni Oluwapelumi Mutiu, ẹni to ni ipenija ara.
Mutiu sọ fun BBC News Yoruba pe ipenija nla lo jẹ fun oun nigba ti oun n dagba nitori oun maa n ri ara oun bi ẹni to da yatọ ninu ẹbi nitori oun nikan ti o jẹ ọmọ keji ninu ọmọ meji tawọn obi oun bi ni o ni ipenija naa.
O sọ pe bi wọn ṣe bi oun niyẹn ti oun kii si fẹ ba awọn eeyan ṣere nigba ti oun w ani kekere.
O fi kun nigba ti oun bẹrẹ si ni dagba ni oun gba ipenija ara ti oun ni gẹgẹ bi agọ ara oun.
Bakan naa lo sọ pe lara ipenija ti oun n koju bayii ko ju bi awọn eeyan kii ṣe fẹ fun niṣẹ nitori ipenija ti oun ni.
"Ko si nnkan ti eeyan ti gbogbo ara rẹ pe ti mi o le ṣe amọ awọn eeyan kii fẹ fun mi niṣẹ, wọn maa n sọ pe mi o le ṣe e nitori ipenija ti mo ni."
Mutiu tun sọ pe oun ko ni ko aarẹ ọkan lori iṣẹ to wu oun lati ṣe gangan nigba ti oun dagba iyẹn imọ nipa ipoogun ti awọn oloyinbo n pe ni "pharmacy".
O ni oun n gbiyanju lati ṣakojọ oun gbogbo to yẹ lati fi ṣe iṣẹ naa.








