You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bàbá àti ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta, afurasí ajínigbé tó ń fi màálù dídà bojú kó sí gbaga Amotekun l'Ondo
Ọwọ palaba baba ẹni ọdun merindinlọgọta ati awọn ọmọkunrin rẹ mẹta afurasi tí wọn n ṣiṣẹ ajinigbe segi lẹyin ti wọn ko si gbaga awọn ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn afurasi mẹrẹẹrin naa ji ọkunrin kan gbe lọ ni ilu Oba-Akoko nijọba ibilẹ guusu iwọ-oorun ipinlẹ Ondo.
Orukọ awọn afurasi naa ni Illiasu, baba ẹni ọdun mẹtadinlọigọta, awọn ọmọ rẹ ni Usman, ọmọ ọdun metalelọgbọn; Wahab, ọmọ ọdun metadinlọgbọn; ati Yakubu, ọmọ ọdun mejidinlogun.
Bakan naa ni Amotekun tun fi panpẹ ofin mu awọn afurasi miran lori ẹsun idigunjale ati ẹgbẹ okunkun.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ajọ Amọtẹkun ni Alagbaka niluu Akure, ọga agba ajọ naa, Akogun Adetunji Adeleye, salaye pe awọn eeyan mẹrin naa n ṣiṣẹ ajinigbe nigba ti wọn n fi maluu dida boju.
Adeleye sọ pe ọjọ mẹrin gbako ni wọn fi wa awọn ajinigbe yií ni kete ti awọn ẹbi ẹni ti wọn jigbe fi ọrọ naa to wọn leti.
Ọga agba ajọ naa sọ pe wọn jì okunrin naa gbe ni agbegbe Oba-Akoko lasiko to n lọ irin ajo.
O ni awọn ẹbi okunrin yii ti san owo ti awọn ajinigbe naa beere fun, sugbọn wọn kọ lati tu okunrin naa silẹ.
Adeleye ni idi eyi ni awọn ẹbi ẹni to wọn jigbe naa fi tọ Amọtẹkun lọ, latari bí awọn ajinigbe ṣe kọ lati mu ileri wọn ṣe lẹyin owo ti wọn ti gba.
Ní kete ti ọrọ naa de ọdọ awọn Amotekun lawọn ẹṣọ ajọ naa wọ inu igbo pẹlu iranlọwọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ.
Eyi lo mu kí wọn mọ pe idile to yan ijinigbe laayo lo ṣiṣẹ laabi naa.
''Ida marundinlọgọrin owo tawọn ajinigbe gba lọwọ ẹbi ẹni ti wọn ji gbe ni Amotekun ri gba pada''
Ọga agba Amotekun fikun ọrọ rẹ pe awọn ajinigbe naa kọ oju ibọn sawọn ẹṣọ Amotekun, ti awọn naa si da a pada, sugbọn lẹyin o rẹyin Amotekun bori awọn ajinigbe naa.
Lẹyin ti wọn fi panpẹ ofin mu awọn afunrasi naa ni wọn ri ọkunrin tí wọn jigbe doola, sugbọn awọn ajinigbe yii ti fi ada ṣa ara okunrin naa yanayana.
O ṣalaye pe ni kete ti wọn tu okunrin naa silẹ lawọn gbe e lọ ile iwosan fun itọju to peye.
Adeleye sọ ọ di mimọ pe ida marundinlọgọrin owo ti awọn ajinigbe naa gba ni Amotekun gba pada lọwọ wọn.
Awọn nnkan miran ti wọn gba lọwọ awọn afurasi naa ni oogun oloro, ọti lile, siga, ibọn, ada àti awọn ohun miran ti wọn n lo fun iṣẹ laabi ti wọn n sẹ.
Adeleye sọ pe ẹni to jẹ ọga awọn ajinigbe naa jẹ ọkan lara awọn ogbontarigi ajinigbe ti wọn ti n wa lati ọdun 2024, sugbọn o na papa bora nigba naa.
Amọ, bayii ọwọ ofin ti tẹ afurasi naa ti wọn yoo si gbe lọ Ileẹjọ laipẹ.
''Ọkọ mi lo bajẹ si ẹba ọna marosẹ Ọba-Akoko lasiko ti wọn jí mi gbe''
Lasiko to n sọrọ nípa iriri rẹ lọwọ awọn ajinigbe naa, Ọgbẹni Oyebade Samuel salaye pe nigba ti ọkọ oun bajẹ sì opopona marose Oba-Akoko ni awọn ajinigbe naa ji oun gbe.
O sọ pe awọn Fulani mẹrin ọhun jade lati inu igbo pẹlu ibọn, ada ati igi, ti wọn si kọkọ lu oun ni alubami, ki wọn to wọ oun lọ inu igbo.
Ogbeni Oyebade sọ di mimọ pe awọn ajinigbe naa kọkọ bere fun ogoji milionu naira, kí wọn to ni adehun lati gba 1.6 millionu naira, eyi ti awọn ẹbi oun san.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn ajinigbe yii kọ lati tu oun silẹ lẹyin ti wọn gba owo tan.
Oyebade ni lẹyin eyi ni awọn ẹbi oun fi iṣẹlẹ naa to Amọtẹkun leti, ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun si wọ inu igbo ti gbe oun si lọ lati doola oun.
Ogbeni Oyebade wa gboriyin fun Amọtẹkun fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, bakan naa lo kepe ijọba lati tubọ gbaruku ti ajọ naa, ki wọn le maa se isẹ wọn daadaa.