Èèyà mẹ́ta farapa níbi tí ọlọ́pàá ti yìnbọn pa awakọ̀ lásìkò àyẹ̀wò

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ṣi lawọn n ṣe iwadii lọwọ lori bi wọn ṣe sọ pe ọlọpaa yinbọn pa awakọ kan ni idubo ayẹwo oju popona, sibẹ idajọ ododo ni awọn eeyan n beere fun bayii.
Ikorita Agip-Ada George to wa niluu Port-Harcourt ni iṣẹlẹ ọhun ti waye l'Ọjọbọ, ọsẹ yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Asiko ti wọn lawọn ọlọpaa da awakọ naa duro lati yẹ ẹ wo, ṣugbọn ti ko duro, ni wọn sọ pe ọkan lara awọn ọlọpaa naa yinbọn fun un, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji ori irin.
Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi ibọn ti ọlọpaa naa yin ṣe ba a lati ẹyin, lo ti juwọ silẹ, ti ọkọ rẹ si ya lọ ba awọn to duro lẹgbẹ opopona.
Awọn ti ko din ni mẹta la gbọ pe wọn farapa, lasiko ti ọkọ naa ya lọ ba wọn.
Loju ẹsẹ ni awọn to wa nitosi ti figbe ta, ti wọn si sare sunmọ awakọ ọhun lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti aṣọ ko bọmọyẹ mọ.
Ọlọpaa naa ni wọn lo tun bẹrẹ sii yinbọn soke lakọ-lakọ lati le raaye na papa bora, lẹyin to pa awakọ ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Anthony tan.
Awọn eeyan to wa nitosi ni iroyin fi to wa leti pe wọn sare sunmọ awọn ọlọpaa naa, ti wọn ko si jẹ ki wọn raaye salọ.
Àwọn tó wà níbẹ̀ ni kò jẹ́ kí ọlọ́pàá náà sálọ
Ọkan lara awọn to wa nibẹ, ẹni ti ko fẹ darukọ ara rẹ, sọ pe "Nnkan bi agogo marun-un irọlẹ ni awọn ọlọpaa ti wọn wa nitosi ikorita Agip/Ada George da ọkunrin awakọ kan duro, ṣugbọn ti ko duro.
"NItori ko duro ni wọn ṣe sare tẹle lẹyin. Ọkan lara awọn ọlọpaa naa fa ibọn rẹ yọ lojiji, to si bẹrẹ sii yin in. Igba mẹta lo yin ibọn naa.
"Lati ẹyin ni ibọn tib a awakọ ọhun, to si wọ aya rẹ lọ. Loju ẹsẹ nibẹ lo si sọ ijanu rẹ nu, to si lọ kọlu aw]ọn mẹta nibi ti wọn wa."
Ẹni naa sọ pe ariwo ikunlẹ abiyamọ ni awọn eeyan to wa nitosi bẹrẹ sii pa, ti wọn si n sare lọ sibi iṣẹlẹ naa.
"Awọn eeyan gbe awakọ naa jade kuro ninu ọkọ rẹ, lati gbe e lọ sile iwosan to wa nitosi, ibẹ si lo ku si," o ṣalaye.
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe "Lẹyin to yinbọ naa, ọlọpaa yii tun bẹrẹ sii yinbọn soke lati le na papa bora, ṣugbọn awọn ọdọ to wa nibẹ, ni wọn lọ koju rẹ, ti wọn si gba ibọn ọwọ rẹ, ko to di pe wọn bẹrẹ sii lu."
Bakan naa lo ṣalaye pe asiko ti wọn n lu ọlọpaa naa, ni awọn ọlọpaa akẹgbẹ rẹ de, ti wọn si gba a silẹ lọwọ wọn.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Blessing Agaba sọ pe oun naa ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, ati pe oun yoo gbe atẹjade sita "ni kete ti oun ba ti gbọ ẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣẹlẹ".
"Mo ṣi n duro lati gbọ ẹkunrẹrẹ lati ẹnu ọga ọlọpaa agbegbe naa." Agaba ṣalaye.


























