Ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa Olufẹmi Adesuyi olùdíje sípò gómìnà fẹ́gbẹ́ òṣèlú ZLP ní ìpínlẹ̀ Osun

Adesuyi lo de fila egbe oselu ZLP, to si n wo ookan

Oríṣun àwòrán, Adesuyi John Olufemi/Facebook

Àkọlé àwòrán, olufemi Adesuyi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Osun lopin ọsẹ yii, ti gbogbo araalu, paapaa awọn oludije kọọkan si ti wa ni imurasilẹ.

Adijẹ mẹrinla lati inu ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ni wọn jade lati du ipo aga kan ṣoṣo to fẹẹ ṣi silẹ laipẹ yii.

Lara awọn to n dije du ipo naa ni Onimọ-ẹrọ Olufemi John Adesuyi, ẹni to jade labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party.

Ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 1976 ni wọn bi Olufẹmi Adesuyi, to si kẹkọọ gboye nipa imọ-ẹrọ, eyi ti oloyinbo n pe ni 'Computer Science ati Engineering' nile-ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo to wa niluu Ile-Ife, ipinlẹ Osun.

Adesuyi ṣiṣẹ gẹgẹ bi oludari ẹka eto nile ẹkọ giga Living Spring College of Technology and Innovation to wa niluu Osogbo, ipinlẹ Osun bakan naa.

Yatọ si eyi, Adesuyi tun fi ara rẹ jin fun iṣẹ Ọlọrun, pẹlu bo ṣe jẹ onigbagbọ pọmbele to mọ ohun to n ṣe.

Òṣèlú

Ọdun 2015 ni Adesuyi darapọ mọ oṣelu lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan rẹ, ṣugbọn to jade lati du ipo aṣoju-ṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party, iyẹn lọdun 2019.

Adesuyi du ipo aṣoju-ṣofin lẹkun idibo Aarin Gbungbun Ife, Ariwa Ife, Guusu Ife ati Ila Oorun Ife lọdun 2019, to si pada fidi rẹmi pẹlu ibo mẹrindinlọgọrun-un ti awọn ololufẹ rẹ di fun un, leyi to jẹ ko ṣe ipo kẹwaa lori tabili.

Iyẹn nikan tun kọ, Adesuyi tẹsiwaju lati kopa ninu eto idibo gomina ipinlẹ Osun labẹ asian ẹgbẹ oṣelu kan naa lọdun 2022, to si ni ibo 364.

Ninu gbogbo awọn mẹẹdogun to du ipo lọdun naa, Adesuyi lo wa ni isalẹ tabili.

Ifẹ ati igbagbọ ti Adesuyi ni lati dari akoso ijọba nipinlẹ Osun, lo fa a, to tun fi jade lati du ipo gomina naa lọdun 2026 ti a wa yii.

Ìlérí

Oniruuru ileri ni Adesuyi ti ṣe fun gbogbo awọn ara ati olugbe ipinlẹ Osun, iyẹn bi wọn ba fi ibo wọn gbe e wọle lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

Lara awọn ileri naa ni ipese iṣẹ f'awọn ọdọ, atunṣe ati atunto lẹka eto ilera, idagbasoke eto ẹkọ, opopona to ja geere, to fi mọ igbayegbadun araalu ati awọn oṣiṣẹ ijọba.