Ńjẹ́ o mọ̀ pé àdó olóró ti bú rí nítòsí ààrẹ lásìkò àyàjọ́ òmìnira ní Nàìjíríà? Ohun mánigbàgbé márun tó wáyé rí lọ́jọ́ àyájọ́ òmìnira

Aworan Ahmadu Bello, Ọbafẹmi Awolọwọati Nnamdi Azikwe
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Alẹ ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan, ọdun 1960 mọjumọ ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, jẹ ọjọ manigbagbe ti orileede Naijiria ko nii gbagbẹ ninu itan.

Bo tilẹ jẹ pe itan ti wa nilẹ tẹlẹ, ṣugbọn itan ti ayajọ ọjọ ominira yii ṣara ọtọ.

Wọn ṣe inu gbọngan Tafawa Balewa ti wọn ti ṣayẹyẹ naa lẹṣọọ.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni korajọ sinu gbọngan yii, to fi mọ awọn aṣọju ijọba, akẹkọọ, oniṣowo, obinrin ati ọkunrin, oniruuru ijo, orin ati ere idaraya ibilẹ ni awọn eeyan ṣafihan rẹ.

Ọmọọbabinrin Alexandra ti Kent lo ṣoju Ọbabinrin Elizabeth keji nibi ayẹyẹ ọhun, o si ti de si Naijiria lati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsa, ọdun naa.

Nibi ayẹyẹ igbominira

Awọn agbaagba alakoso Naijiria, to fi mọ Olootu ijọba, Tafawa Balewa, ati gomina to fẹẹ gbe ipo silẹ, Ọgagun Sir James Robertson ni wọn wa nibẹ lọjọ naa.

Laaarọ ọjọ kinni, ọṣu Kẹwaa, ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Naijiria lo wa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe bi awọn kan ṣe n sọ pe ero to wa nibẹ to ẹgbẹrun mẹwaa, bẹẹ lawọn miran n sọ pe ẹgbẹrun lọna ogun ni awọn to wa nibẹ.

Nigba ti eto naa bẹrẹ, Sir James lo bọ siwaju lati fun Tafawa Balewa ni aga to fi jokoo, wọn gbe asia ilẹ Geesi wa silẹ, lati gbe asia Naijiria lọ soke, eyi to jẹ alawọ ewe ati funfun.

Fun igba akọkọ ninu itan, asia orileede Naijiria lọ soke, to si ṣafihan wi pe wọn ṣẹṣẹ bi ọmọ tuntun.

Olootu ijọba tuntun, Tafawa Balewa sọrọ ti itan rẹ ko le parẹ, to si bẹrẹ pẹlu wi pe: "Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, jẹ ọjọ ti gbogbo ọmọ Naijiria ti n reti lati ọdun meji sẹyin.

"Ọjọ nla ti a n reti pada de, ilẹ Naijiria si ti wa di ominira, ati orileede to da duro.

"Ọrọ ti mo ba sọ ko le sọ bi inu mi ṣe dun to, ati iwuri jijẹ ọmọ Naijiria to ni anfaani lati gba awọn iwe ofin lati ọwọ Ọbabinrin, eyi to ṣe afihan idanimọ ominira Naijiria.

"Anfaani nla leyi jẹ, eyi ti yoo maa mọ riri rẹ titi lai. O tun fun mi ni okun ati igboya bi mo ṣe n ni afojusun lati lo gbogbo aye mi lati fi ṣiṣẹ isin sin orileede wa," Tafawa Balewa sọ bẹẹ.

Ṣugbọn ṣa, ni afikun ajọyọ ayẹyẹ ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1960, oniruuru itan lo tun ti waye latigba naa titi di asiko yii, eyi ti a fi n ṣajọyọ ọdun kẹrindinlaadọrin ti orileede naa gba ominira.

1963: Naijiria di Ripọbiliiki

Aṣoju Ọbabinrin elizabeth keji ati Tafawa Balewa

Bẹẹni, ayipada ọtun nla ree latigba ti ominira ti waye lọdun 1960.

Lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1963, ilẹ Naijiria di Ripọbiliiki, leyi to ṣe ayipada si iwe ofin to jẹ pe Ọbabinrin Elizabeth ni olori ilu, nigba ti Nnamdi Azikiwe di ipo gomina agba mu.

Ọjọ naa ni iwe ofin ọdun 1963 fẹsẹ mulẹ. Igbesẹ naa lo si fi opin si ki Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi maa jẹ olori Naijiria, to fi faaye gba Naijiria lati bẹrẹ sii yan Aarẹ, nigba ti Tafawa jẹ Olootu agba.

Eyi lo si jẹ ki Nnamdi Azikiwe di aarẹ akọkọ ti orileede Naijiria ni, nigba ti iwe ofin wa bo ṣe wa.

Kii ṣe pe wọn n ṣayẹyẹ ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, lasan, ṣugbọn wọn tun fi n ṣe iranti ọjọ ti wọn gba iṣakoso kuro lọwọ Ọbabinrin Elizabeth keji.

Labẹ iṣakoso tuntun yii, Tafawa Balewa lo ṣi n tẹsiwaju gẹgẹ olori orileede pẹlu gbogbo agbara, nigba ti Azikwe jẹ olori gbogbo ipinlẹ.

Tafawa Balewa, Nnamdi Azikwe ati Obafemi Awolowo, wọn n rẹrin

1979: Ripọbiliiki keji

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Lonii, a tun n foju ri Ripọbiliiki keji. Pẹlu ayẹyẹ ibura to waye laaarọ oni, mo n gun ori ipo yii gẹgẹ bi Aarẹ akọkọ pẹlu gbogbo agbara. Mo n lo anfaani asiko yii lati fi dupẹ lọwọ gbogbo yin fun suuru ati atilẹyin ninu gbogbo asiko iṣipopada yii."

Eyi ni awọn ọrọ ti Alaaji Shehu Shagari sọ lọjọ ti wọn bura fun un gẹgẹ bi Aarẹ ilẹ Naijiria lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1979.

Eyi waye lẹyin iṣakoso ọdun mẹrinla ti awọn ologun ti n ṣe ijọba.

Alaaji Tanko Yakasai, ẹni to ti le ọgọrun ọdun, agba oloṣelu Naijiria tẹlẹ, sọ pe awọn oloṣelu lati ẹkun Guusu atu Ariwa Naijiria yoo parapọ ninu igbesẹ ati eto to gbe iṣakoso Alaaji Shehu Shagari wọle.

O sọ pe, "Eto idibo akọkọ ree ti ọpọ ọmọ Naijiria lero wi pe ko ni ojusaaju ninu."

"Ko si iwa ipa, ṣugbọn awọn to parapọ ko ipa to jọju ninu eto idibo naa," Tanko Yakasai fidi rẹ mulẹ.

Ọmọwe Sulaiman Shehu Malami, olukọ kan nile ẹkọ gbogboniṣe ti Kaduna, naa tun sọ pe titi aye ni wọn yoo maa fi ranti ijọba Shagari pẹlu awọn agbekalẹ to dara.

1996: Abacha da ipinlẹ mẹfa silẹ

Ọgagun Sni Abacha atawọn ọgagun ni igbimọ iṣejọba ologun nigba naa lorilẹede Naijiria.

Lasiko ti wọn n ṣayẹyẹ ọdun kẹrindinlogoji ominira Naijiria, Ọgagun ani Abacha kede idasilẹ awọn ipinlẹ tuntun mẹfa, to si jẹ ki ipinlẹ to di Naijiria mu lọ soke lati ọgbọn si mẹrindinlogoji.

O ṣalaye peipinnu naa lo waye lẹyin ti igbimọ lati ṣe idasilẹ awọn ipinlẹ tuntun gbe abajade wọn sita, ati pe awọn ipinlẹ naa ni awọn ohun amuyẹ bii ijọba ibilẹ ati aala.

Abacha jẹ ko di mimọ pe ipinnu naa lo ṣoju ṣaara lati yọ ipinlẹ mẹfa lara ẹkun idibo mẹfa orileede naa. O sọ pe awọn nnkan bii ero, ilẹ ati awọn ohun miran to ṣe pataki ni wọn ṣe agbeyẹwo wọn, ko to di pe wọn gbe igbesẹ yii.

Awọn ipinlẹ ti wọn da silẹ naa lo ṣi wa titi di oni.

Awọn ipinlẹ naa ni:

Bayelsa ti wọn yọ lati ara ipinlẹ Rivers

Ebonyi ti wọn yọ lati ara ipinlẹ Abia ati Enugu

Ekiti ti wọn yọ lati ara ipinlẹ Ondo

Gombe ti wọn yọ lati ara ipinlẹ Bauchi

Nasarawa ti wọn yọ lati ara ipinlẹ Plaeau

Zamfara ti wọn yọ lati ara ipinlẹ Sokoto

Alaaji Buba Galadima, to jẹ agba oloṣelu Naijiria sọ pe, "anfaani to wa ninu awọn ipinlẹ tuntun ti wọn da silẹ naa ni lati jẹ ki ijọba sunmọ araalu, ati lati jẹ ki awọn eeyan sọrọ nipa awọn ohun ti wọn n doju kọ."

Ado Oloro ilu Abuja

Gbagede Eagle Square to wa niluu Abuja ni ayẹyẹ aadọta ọdun ominira waye, nibi ti awọn adari ilẹ Naijiria bii Aarẹ Goodluck Jonathan atawọn alẹnulọrọ miran ti peju.

Ṣugbọn ṣa, lasiko ayẹyẹ naa, ọpọ awọn ọkọ to wa nitosi gbagede naa ni wọn ju ado oloro si. Lẹyin ado oloro naa, ni ado oloro miran tun dun nitosi gbagede ayẹyẹ ọhun.

Iroyin to kọkọ jade sita ni pe eeyan mẹjọ lo ti ku, ṣugbọn ti iye awọn ku tun le si i ni mejila, nigba ti ọpọ awọn eeyan farapa yannayanna.

Ikọlu naa lo ko orileede naa sinu ọfọ, eyi to yẹ ko jẹ ọjọ ajọyọ lati fi ṣayẹyẹ ominira aadọta ọdun.