Alága ìjọba ìbílẹ̀ Owo tí wọ́n já síhòhò l'Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Oluwaseun Ogunmola
Ọrọ di bo o lọ o yago lọna lọjọ Aje, ogunjọ oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii niluu Owo, ipinlẹ Ondo, nigba tawọn janduku yabo ọfiisi Alaga ijọba ibilẹ Owo, Tope Omolayo, ti wọn si ja a si ihooho lẹyin to pada si ọfisi lẹyin oṣu mẹfa to ti wa nile.
Ṣaaju ni awọn asofin ijọba ibilẹ naa ti ni ki Tope Omolayo lọ rọ ọ kun nile foṣu mẹfa gbako, latari aawọ to ni pẹlu Ọlọwọ tilu ọwọ; Ọba Ajibade Ogunoye.
Awọn ti ọrọ ijanisihoho naa soju wọn salaye, pe alaga yii pada sẹnu isẹ laarọ ọjọ Aje, ogunjọ oṣu kẹrin, awọn janduku si yabo ayika ofisi ijọba ibilẹ naa, ti wọn ya aṣọ mọ alaga ijọba ibilẹ náà lọrun nigba ti wọn wọle tan.
Wọn salaye pe awọn janduku naa wọle sinu ọgba, wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke, eyi to mu kawọn to wa ni ayika sa asala fun ẹmi wọn.
Lasiko ti eyi n lọ lọwọ ni wọn kọlu Omolayo, ti wọn si ja a sihoho pẹlu aṣọ funfun to wọ.
Awọn alatilẹyin Ọlọ́wọ̀ lo kọlu mi- Alaga
Nigba to n salaye ohun to ṣẹlẹ si i atawon to fura si, Tope Omolayo ti i se Alaga ijoba ibilẹ Owo sọ pe awọn to ṣe ikọlu soun naa jẹ awọn alatilẹyin Ọlọwọ tilu Ọwọ, Ọba Ajibade Ogunoye ati aburo Kọmiṣanna fun eto iṣuna nipinlẹ Ondo.
Nigba ti Omolayo n darukọ awon to ni wọn ja oun sihojo naa, o darukọ ẹnikan to pe ni Kunle Odide ati awọn miran to pe ni Eko, Gentle, Festus, Akeem, Goldberg ati Last Angle.
Alaga naa ṣalaye pe awọn to lu oun sọ pe Ọlọwọ ti pàṣẹ pe oun gbọdọ fi ilu silẹ, o ni ohun to jẹ ki wọn tun pada waa fiya jẹ oun bayii niyẹn.
Kí ni Afin Ọlọwọ sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
BBC News Yoruba gbiyanju lati ba akọwe eto iroyin ni afin Ọlọwọ sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan ori ade naa, sugbọn gbogbo igbiyanju naa lo ja si pabo.
Titi di asiko ti a gbe iroyin yii jáde, awọn igbimọ oloye ilu naa ko ti i fesi si ọrọ naa.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Ni osu kẹwaa ọdun 2025 ni awọn asofin ìjọba ibilẹ Ọwọ ni ki Tope Omolayo lọ rọ ọ kun nile fun oṣu mẹfa gbako, lori ẹsun pe o wọ ori ade ilu naa; Ọba Ajibade Ogunoye, nilẹ.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin atẹjisẹ ohùn (voice note) to tẹ awọn eeyan lọwọ, eyi to kun fun ọrọ arifin ati itabuku ti Alaga naa sọ si Ọlọwọ. Eyi lo mu awọn olugbe ilu naa binu gidigidi si alaga Omolayo nigba yẹn.
Leyin iṣẹlẹ yii ni awọn oloye ilu naa se ipade, ti wọn si ni Omolayo ko gbọdọ fi ẹsẹ tẹ ilu naa mọ , bo tilẹ jẹ o ti tọrọ aforiji lọwọ ori Kabiyesi Ogunoye.
Ṣugbọn Oloye Ademola Obanonyen, ẹni to gba ẹnu awọn oloye naa sọrọ nigba naa sọ pe wiwa nipo Omolayo jẹ ohun ti gbogbo ilu Owo ko fara mọ rara, idi niyẹn to fi gbọdọ fi ilu silẹ.
Oṣu mẹfa ti Omolayo ti kuro lọfisi lo gbiyanju lati pada wọle lọjọ Aje, ṣugbon to ba iya pade.
Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Jimoh Abayomi, fidi ikọlu si Alaga ijọba ibilẹ Ọwọ naa mulẹ.
Lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ, o salaye pe Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ naa; Adebowale Lawal, ti pasẹ fun awọn ọlọpaa lati lọ sibudo iṣẹlẹ naa ni kete ti wọn gbọ ohun tó ṣẹlẹ̀.
O salaye pe alaafia ti jọba ní agbegbe naa, ti gbogbo awọn osisẹ ìjọba ibilẹ naa si n se isẹ wọn lai si ibẹru.
Alukoro naa sọ pe wọn ti bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ yii, ti wọn yoo si ri i daju pe wọn fi awọn to ṣe ikọlu náà jofin.


























