Ilé ẹjọ́ gba onídùúró Blessing CEO pẹ̀lu ₦20m lórí ẹ̀sùn jìbìtì ₦69.15m

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ile ẹjọ to n ri si awọn ẹsun àrà ọ̀tọ̀ nipinlẹ Eko ti fi aaye beeli silẹ fun gbajumọ sọrọsọrọ ori ayelujara, Blessing Okoro tawọn eeyan mọ si Blessing CEO.
Ọjọbọ ni kootu to fikalẹ s'Ikeja, nipinlẹ Eko, gba oniduuro Blessing pẹlu miliọnu lọna ogun naira (₦20m).
Tẹ o ba gbagbe, ẹsun meji ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu jibiti lilu ni sọrọsọrọ ori ayelujara naa n jẹjọ rẹ, eyi ti kootu pe ni ₦69.15 ni wọn ti fi aaye beeli silẹ fun un wayii.
Adajọ Rahman Oshodi to n gbọ ẹjọ naa, fi aaye beeli ọhun silẹ lẹyin to ti Blessing ti wa ni ahamọ ajọ EFCC fun igba kan.
Ohun to ṣẹlẹ
EFCC fẹsun onikoko meji kan Blessing CEO lọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa ọdun 2026, awọn ẹsun naa da lori ole jija ati fifi ẹtan gba owo.
Gẹgẹ bi EFCC ṣe wi, olujẹjọ fi ẹtan gba ₦69,150,000 lọwọ Hope Chiropractic Health Clinic Limited, loṣu Kẹta ọdun 2025.
Wọn ni o sọ fun wọn pe oun yoo gbe ile kan fun wọn lati maa lo ni agbegbe Lekki niluu Eko ni.
Eyi ko pada ri bẹẹ, lọrọ ba di ẹjọ.
Blessing lasiko ijẹjọ rẹ jẹwọ iwa naa, o si ni oun jẹbi.
Ohun ti kootu wi
Lasiko igbẹjọ yii, Adajọ Oshodi beere iwe irinna Blessing, agbẹjọro rẹ si dahun pe o ti sọnu, awọn si ti fi iwe to yẹ gbe eyi lẹsẹ.
Adajọ pada kede pe oun fi aaye beeli silẹ fun Blessing CEO pẹlu ogun miliọnu naira, oniduuro meji ti wọn duro ire ti wọn si ni owo yii nipamọ wọn.
Kootu paṣẹ pe oniduuro kọọkan gbọdọ mu iwe akọsilẹ owo wọn ni banki fun ọdun mẹta wa, tabi ki wọn mu ẹri wa pe wọn ni owo ti ko din ni ₦20 million ninu akanti wọn.
O ni ki ẹka to n ri si gbigba beeli nipinlẹ Eko gba gbogbo akọsilẹ to yẹ nipa Blessing atawọn oniduuro rẹ silẹ.
Bakan naa ni Adajọ Oshodi paṣẹ pe ki ẹka to n ri si iwọlejade arinrinajo (Immigration) lọ mọ pe olujẹjọ yii ko le jade irinajo lasiko yii, titi ti wọn yoo fi yanju ẹjọ rẹ.
O sun igbẹjọ si ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa odun 2026.
Ta a ni Blessing CEO

Oríṣun àwòrán, Bleesing CEO Instagram
Ọmọ ipinlẹ Ebonyi, lapa Ila Oorun Naijiria ni Blessing Nkiruka Okoro. Ijọba ibilẹ Onitsha ni wọn ti bi i.
Orukọ to sọ ọ di gbajumọ ni Blessing CEO.
Onkọwe ni, sọrọsọrọ ori ayelujara ni, bẹẹ lo si tun maa n sọrọ lori igbeyawo ati ibaraẹnidọrẹẹ ati ibalopọ.
O bi awọn ọmọkunrin meji.
Ẹni ọdun mejidinlogun, (18) ni Blessing nigba to fẹ ọkọ rẹ akọkọ ni 2010, ọkunrin naa lo bi awọn ọmọ rẹ meji fun.
Igbeyawo naa tuka nigba ti Blessing pe ẹni ọdun mọkanlolgun (21)
Ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) ni bayii.
Oṣu Kẹrin ọdun 2019 ni Blessing CEO ṣafihan awọn foto ile nla to ni oun kọ si Enugu, amọ ko pẹ ti Onye Eze, ẹni to ni ile ọhun fi jade pe irọ ni Blessing n pa, oun kọ lo ni ile naa, o si fi ọlọpaa mu un..
Lẹyin eyi ni Blessing ṣe fidio to fi tọrọ aforiji pe irọ loun n pa.
Nipa ajọṣe pẹlu ọkunrin, ọkunrin kan, Ikechukwu Darlington Ogbonna tawọn eeyan mọ si IVD ni wọn ni Blessing n ba dọrẹẹ, ti ọrọ naa si di ariwo nigba ti iyawo Ogbonna to n jẹ Bimbo ni oun ko ni I gba ki Blessing ni nnkan lati ṣe pẹlu ọkọ oun.
Oṣu Kẹwaaa ọdun 2022 ni Bimbo ku lojiji, ko pẹ sigba naa ni iroyin gbe e pe Blessing ati IVD ti n fẹra wọn.
Ko si pẹ sigba naa ti IVD fi ni ki Blessing jẹ kawọn gbe ifẹ awọn lọ si ipele to han saye.
Ọrọ nipa jẹjẹrẹ to ti wa ni ipele kẹrin to ni oun ni nibẹrẹ ọdun yii lo tubọ mu ẹnu kun Blessing CEO ju, eyi to pada ja si irọ lẹyin ti awọn ẹlẹyinju aanu ti da owo to to miliọnu mẹtala naira fun un.


























