Ìdí rèé tí a fi ń ra màálù kan ní ₦2.5m báyìí, àwọn alápatà sàlàyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ alapata nipinlẹ Eko ti ke gbajare wi pe owo gọbọi lawọn fi n ra maalu bayii ni ipinlẹ naa.
Adari ẹgbẹ ọhun, Alhaji Bamidele Kazeem, to ba ileeṣẹ iroyin NAN sọrọ ṣalaye wi pe owo maalu ti lọ soke debi wi pe maalu tawọn n ra ni N1.7m tẹlẹ ti di N2.5m bayii nipnlẹ Eko.
Alhaji Kazeem ko ṣai ṣalaye idi abajọ ti owo ti wọn n ta maalu fi lọ soke lasiko yii.
Lara awọn nnkan ti Ọgbẹni Kazeem sọ pe o faa ti maalu fi gbowo lori ni eto aabo to mẹhẹ papaa julọ lẹkun ariwa orilẹede Naijiria ti wọn ti n ko ọpọ ẹran maalu wa silu Eko.
Alhaji Kazeem tun sọ pe owo ọkọ to n gbe maalu de ipinlẹ Eko naa wa lara ohun to jẹ ko wọn gan an bayii.
Adari ẹgbẹ awọn alapata ipinlẹ Eko tun sọ pe ai tii máa sin maalu ninu ọgba yatọ si dida wọn kiri naa jẹ ki maalu gbowo lori.
''Maalu ti a ra ni N1.7m lọdun to lọ ti di N2.3m si N2.4m bayii.
Koda, a ti ri maalu ti ko din ni N2.5m ni ipinlẹ Eko lasiko yii,'' Alhaji Kazeem lo sọ bẹẹ.
Alaga awọn alapata naa sọ pe ọwọngogo maalu yii ko jẹ ki owo ẹran tita ṣe daadaa mọ.
Bakan naa ni o sọ pe bi maalu ṣe wọn bayii ti jẹ ko nira fawọn onibaara lati le maa ra ẹran maalu jẹ.
''Maalu ti wọn ju ọkọ lọ bayii''
Alaga awọn alapata nipinlẹ Eko ṣalaye siwaju sii pe ''ọkọ ayọkẹlẹ mi ti mo ra ni N2.1m lọdun 2020 ko to owo ti a fi n ra maalu kan mọ bayii.
Eyi n ṣafihan bi maalu ṣe wọn to bayii, o nira lati ri maalu N1m lọja lasiko yii.
Iyalẹnu ni yoo jẹ fun ẹnikẹni to ba ri maalu ti wọn n ta ni miliọnu kan naira bayii.''
Ọgbẹni Kazeem sọ pe ọwọngogo epo bẹntiroolu ati disu tawọn ọkọ to n ko maalu wa si ipinlẹ Eko n lo naa wa lara nnkan to jẹ ki maalu wọn.
O ni ọpọ oniṣowo ẹran maalu ni ko lanfaani lati ko ẹran wa si ilu Eko mọ latari owo ọkọ to wọn.
Alhaji Kazeem sọ pe awọn maalu tawọn n ra nilẹ Yoruba ko to iye ti wọn maa n gbe wa lati apa Ariwa Naijiria.
O wa rọ ijọba ipinlẹ Eko lati tete bẹrẹ eto ọsin maalu ninu ọgba eyi ti ijọba ti ṣeleri wi pe yoo gberasọ ni Gbodu niluu Epe.
Alaga awọn alapata ni rira ẹran lati ilu Epe ko ni jẹ ki owo ọkọ pọ lati maa gbe awọn ẹran naa wọ ilu Eko.



























