You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọsẹ́ gbẹ̀mí ọ̀gá rẹ̀ ní Kwara, ó tún ń bèrè ₦2m lọ́wọ́ ẹbí olóògbé
Ọwọ ṣinku ofin ajọ alaabo NSCDC ti ipinlẹ Kwara ti tẹ ọdọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Soliu Olarewaju Mujeeb, ti wọn fura si pe o lọwọ ninu ijinigbe ati iṣekupa ọga rẹ, Olarewaju Olusegun Afolabi ni ilu Ilorin.
Olarewaju Olusegun Afolabi to yan iṣẹ titun ina ṣe laayo lo jẹ ẹni ọgọta ọdun ki wọn to da ẹmi rẹ logbodo.
Ọga agba ajọ NSCDC, Abbas Nda Mohammed lo fi ọrọ naa lede lọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, osu Kẹfa, ọdun 2026 ti a wa yii ni olu ileesẹ ajọ naa lẹyin iwadii lori bi oloogbe ọhun ṣe dede dawati.
Gẹgẹ bi ọga agba naa ṣe sọ, "oloogbe ọhun ni wọn fi towa leti pe o jade kuro nile lọjọ keje, oṣu yii lati bẹ isẹ ina kan wo ṣugbọn ti ko pada wọle, eleyi to sọ ẹbi rẹ sinu wahala.
"Wọn fi ọrọ naa to ẹka to n tọpinpin ẹrọ ibanisọrọ NSCDC ni ọjọ kọkanla oṣu yii nigba ti gbogbo igbiyanju wọn lati ri ja si pabo.
"Lẹyin naa ni awọn ẹbi oloogbe naa bẹrẹ si n gba ipe lati ori foonu oloogbe ọhun, ti wọn si n bere fun millionu meji naira."
NSCDC sọ mọlẹbi oloogbe naa pada te N120,000 ranṣẹ gẹgẹ bi ẹni to n pe wọn ṣe dari wọn.
Ọwọ́ NSCDC tẹ afurasí apànìyàn
NSCDC sọ siwaju si pe lẹyin iwadii ọpọlọ ati itọpinpin imọ kọmputa to fi mọ ayẹwo lori bi wọn ṣe san owo naa, ọwọ tẹ afurasi ọhun.
Wọn ni nibi ifọrọwanilẹnuwo ni afurasi ti jẹwọ pe oun mọ oloogbe naa, oun si ni oun gbẹmi rẹ.
Afurasi sọ pe oun ti ba ṣisẹ ina ri gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ, ṣugbọn ija lode ti orin di owe laarin awọn mejeji.
Àlàyé lórí bí Soliu ṣe ṣekúpa ọ̀gá rẹ̀
Ọga agba NSCDC naa sọ pe, ṣe ni afurasi ọun tan ọga rẹ lọ sile akọku kan to wa ni agbegbe Kangile, Kulende ni Ilorin wi pe, ko wa bẹ isẹ ina kan wo.
Ibẹ ni afurasi naa ti kọlu u, to si paa, lẹyin naa ni o gba foonu rẹ ti o si pada lo foonu naa lati bere owo lọwọ ẹbi oloogbe.
Ninu iwadii NSCDC ni afurasi ti mu wọn lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ri iboji kekere kan ti wọn furasi pe ibẹ ni o sin oku oloogbe si.
Abbas wa sọ pe iwadii n tẹsiwaju lẹyin naa ni awọn yoo wa afurasi naa sọwọ si ẹka to ba yẹ lati tẹ iwadii awọn siwaju.
O wa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara pe ajọ NSCDC ko ni yẹsẹ ninu didaabo bo ẹmi ati dukia wọn.