You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló pa Oriyomi pọ̀ pẹ̀lú Surii Ilupeju, afurasí adigunjalè tí ọlọ́pàá ń wá? Ohun tí a mọ̀ rèé
Ilumọọka agbohunsafẹfẹ ati oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, ti sọ pe oun ko ni nnkankan ṣe pẹlu Babatunde Surajudeed (Surii Ilupeju), afurasi adigunjale tawọn ọlọpaa n wa.
Oriyomi ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe awọn ti wọn loun ni ajọṣepọ pẹlu Surajudeed fẹ ṣakoba fun ipolongo ibo oun ni.
Gbajugbaja akọroyin naa to ni ileeṣẹ igbohinsafẹfẹ Agidigbo FM niluu Ibadan sọ pe awọn eeyan kan lo fẹ ba orukọ oun jẹ papaa julọ pẹlu boun ṣe fẹ dije fun ipo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027 lo jẹ ki wọn maa sọ kiri pe oun ni ajọṣepọ pẹlu Surii Ilupeju.
Oriyọmi sọ pe ''mo ti ri iroyin kan lori ayelujara eyi tawọn eeyan kan fi n sọ pe mo ni ajọṣepọ pẹlu afurasi ọdaran kan, Surajudeen Adio Babatunde tawọn eeyan mọ si Surii Ilupeju.
Mo n fi asiko yii sọ pe mi o mọ Surii Ilupeju, mi o si ni ajọsepọ kankan pẹlu rẹ.
Bakan naa mi o ṣagbatẹru fun ẹnikẹni lati huwa ọdaran, bẹẹ si ni emi naa ko lọwọ ninu iwa ọdaran kankan.
Titi gbogbo asiko ti mo fi ṣiṣẹ ijọba gẹgẹ bi akọroyin to fi di akoko yii ti mo jẹ oludije fun ipo gomina lẹgbẹ Accord, ori otitọ ati ododo ni mo maa n duro le lori.''
Ọrọ yii jẹyọ lẹyin tawọn ọlọpaa yabo ile Ilupeju lagbegbe Olodo n'Ibadan lọjọ kejila oṣu Kẹfa yii lori ẹsun iwa ọdaran.
Afurasi adigunjale marun un lawọn ọlọpaa mu ninu ile naa, bẹẹ ni wọn si tun ri oniruuru nnkan ija oloro to fi mọ ogun gba lọwọ awọn afurasi ọhun.
Ọrukọ awọn afurasi ti wọn mu ọhun ni Ahmed Nafiu, Olukunmi Olaniyi, Femi Odeyinde, Jelili Akinade, ati Muhideen Adio.
Eyi gan an lo jẹ ki Oriyomi fesi sọrọ to n lọ lori itakun ayelujara.
Mo ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori iwadii ti wọn n ṣe, ti wọn ba nilo mi - Oriyomi
Ọpọ lo n sọ lori itakun ayelujara wi pe iṣọmọgbe Oriyomi Hamzat ni Ilupeju jẹ.
Amọ, Oriyomi ṣalaye pe nitori pe ẹnikan pade oun ri ko tumọ si pe oun mọ nnkankan nipa ohun ti ẹni naa ba ṣe.
''Gbigba eeyan siṣẹ, tabi ki eeyan jẹ ibatan ko tumọ si pe eeyan n gbimọ pọ pẹlu iru eeyan bẹẹ lati huwa ọdaran; bakan naa ni ko tumọ si pe eeyan mọ nnkan to n lọ ninu igbesi aye iru eeyan bẹẹ,'' Oriyomi ṣalaye.
Ilumọọka agbohusafẹfẹ naa rọ araalu wi pe ki wọn jẹ kawọn ẹṣọ eleto aabo ṣiṣẹ iwadii wọn lai koba awọn eeyan ti ko mọwọ mẹsẹ.
Oriyomi tun sọ pe oun ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori iwadii ti wọn n ṣe ti wọn ba nilo oun.
O ni lọpọ igba loun ti ran iṣẹ iwadii ọlọpaa lọwọ sẹyin.
Gbajugbaja akọroyin naa sọ pe ẹni to n gbe iroyin ofege kiri nipa oun fẹ ba orukọ oun jẹ ni nitori oṣelu.
O wa rọ araalu wi pe ki wọn kọ eti ikun sawọn to n gbe iroyin ti kii ṣe ootọ nipa oun kiri.
Oriyomi ni ko si iru ibanilorukọjẹ tabi ijẹrii eke to le da oun duro lati ma wa ilọsiwaju ati igbayegbadun awọn eeyan ipinlẹ Oyo.